Tinubu yóò ṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Ogun lónìí, yóò ṣí pápákọ̀ òfurufú Gateway níbẹ̀ àtàwọn àkànṣe iṣẹ́ míì

Gomina Dapo Abiodun wọ agbada pẹlu fila ati Aarẹ Bola Tinubu toun naa wọ agbada kaabọ ni papakọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, Ogun State Government/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lonii ni Aarẹ orilẹede Naijiria, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu yoo bẹrẹ abẹwo rẹ si ipinlẹ Ogun.

Aarẹ Tinubu atawọn ti yoo kọwọ rin pẹlu rẹ yoo balẹ si papakọ ofurufu Gateway to wa niluu Ilisan-Remo lati ṣi awọn akanṣe iṣẹ ti Gomina Dapo Abiodun ṣe.

Eyi ni yoo jẹ igba keji ti Tinubu yoo ṣe abẹwo si ipinlẹ Ogun latigba to ti de ori iṣakoso gẹgẹ bi aarẹ ilẹ Naijiria.

Aarẹ Tinubu yoo ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe iṣẹ ti Gomina Abiodun ti ṣe kaakiri ipinlẹ naa, lara rẹ ni papakọ ofurufu Gateway ati awọn ọkọ baluu tuntun meji ti ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ ko wọle fun okowo irinajo kaakiri agbaye.

Ninu atẹjade ti oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin, Ọnarebu Kayode Akinmade, fi sita ni o ti jẹ ko di mimọ pe abẹwo aarẹ n ṣafihan pataki idokoowo ni oniruuru ẹka ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun.

Akinmade sọ pe ifilọlẹ papakọ ofurufu naa to wa niluu Ilisan-Remo yoo ko ipa to pọ ninu eto ọrọ aje, pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn ẹru yoo maa gba ibẹ wọle si Naijiria.

Siwaju sii lo sọ pe ninu ọgba papakọ ofurufu ọhun, Aarẹ Tinubu yoo tun ṣiṣọ loju ọkọ baluu Gateway Air meji ti ijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ ko wọle lati bẹrẹ iṣẹ irin ajo soke okun naa, nipa ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ ValueJet.

Bakan naa ni Aarẹ yoo tun ṣe ifilọlẹ ọkọ alupupu igbalode ẹgbẹrun kan to n lo ina, ọkọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo ọgọrun un ati awọn katakata lati ṣe igbelarugẹ fun iṣẹ agbẹ ati ipese ounjẹ ti yoo ran awọn agbẹ lọwọ.

Awọn ohun miran ti aarẹ yoo tun ṣe ifilọlẹ wọn ni opopona Ilisan si Iperu Remo, eyi to wọ papakọ ofurufu naa.

Tinubu yoo tun ṣe abẹwo si abule ileeṣẹ aṣọbode, Nigeria Customs Service Village and commission lati ṣe ifilọlẹ ile tuntun ti wọn ṣẹṣẹ kọ, eyi ti wọn pe ni "Forward Operating Base (FOB)".

Aarẹ Tinubu ko tun ni ṣai ṣe ifilọlẹ opopona Ibadan atijọ to so ilu Saapade ati Ilishan papọ, eyi ti wọn yoo yi orukọ pada si Bola Ahmed Tinubu Expressway.

Lati kadi irin ajo naa nilẹ, Akinmade tun fi kun ọrọ rẹ wi pe Aarẹ Tinubu yoo ṣe abẹwo si opopona marosẹ Sagamu si Benin to n lọ lọwọ.