Kí ló dé tí ọ̀rẹ́ fi rẹ́já, ta ló fẹ́ yọ ara wọn nípò láàrin Makinde àti Ladoja? Àlàyé rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Bi nnkan ko ba ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ́ ki i deede ṣẹ ni ọrọ ti awọn eeyan n sọ bayii nipinlẹ Oyo, lori ohun ti Ayo Fayose sọ pe Gomina Makinde fẹ yọ Olubadan Ladoja nipo, ti ọrọ si jade bayii pe Ladoja gan-an lo n pete ati le Makinde kuro nile ijọba.

Ọjọ Aiku, ọjọ kejila oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Fayose sọ pe Makinde n pete ati yọ Olubadan kuro nipo, ko pẹ ni gudugbẹ ja lati ẹnu Ọnarebu Gbenga Oyekola to n ṣoju ẹkun Atiba, to si tun jẹ Ako-ijanu nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo.

Ọnarebu Oyekola fi atẹjade kan sita lọjọ Iṣẹgun, nibi to ti sọ pe Olubadan Ladoja ati Florence Ajimobi ti i ṣe iyawo gomina Oyo tẹle, Oloogbe Abiola Ajimobi, ranṣẹ pe Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Oyo, Adebo Ogundoyin.

O ni wọn ṣeleri fun un pe awon yoo fun un ni tikẹẹti ti yoo fi dupo ile igbimọ aṣoju ninu APC, awọn yoo si tun fun un lowo tabua pẹlu.

Ki ni alaye Gbenga Oyekola da le lori gan-an?

Gẹgẹ bi Aṣofin Gbenga Oyekola ṣe ṣalaye ninu atẹjade rẹ naa, o ni awọn ikọ to n ṣiṣẹ fun ki irẹpọ ma si, ti wọn si fẹ lo ile igbimọ aṣọfin Oyo lati da wahala silẹ fun ijọba ati Makinde lo wa nidi ete tuntun yii.

Oyekola ṣalaye pe Adebo Ogundoyin fi to Olubadan leti lati ran oun lọwọ ninu igbesẹ ati di gomina, Olubadan si sọ pe ki Ogundoyin yọju soun.

Ọ ni lasiko ipade Ogundoyin pẹlu Olubadan, awọn gbọ pe Ọba Ladoja gba a nimọran lati ma ṣe dupo gomina.

Dipo bẹẹ, ọba naa sọ fun un pe wọn yoo fun un ni tikẹẹti ile igbimọ aṣoju-ṣofin labẹ asia ẹgbẹ APC, pẹlu owo ti yoo fi ṣeto idibo naa.

O ni sugbọn Ogundoyin sọ pe oun ko fẹ.

Oyekola ṣalaye pe Ogundoyin sọ pe Florence Ajimobi naa tun ranṣẹ pe oun lori ọrọ yii kan naa, o si tun ṣeleri owo tabua foun ṣugbọn oun kọ .

Koko pataki ti Oyekola sọ pe oun tori ẹ ṣe alaye yii ni pe awọn kan ni wọn n ba ijọba Makinde ditẹ, ti wọn ko fẹ ẹ nipo.

O ni oun ko lọwọ siru rẹ ni toun, bẹẹ ni won ko pe oun si ohun to jọ bẹẹ rara.

"Mo yọ ara mi kuro patapata ninu eto yowu tabi igbesẹ to le da alaafia ipinlẹ Oyo ru."

O pari atẹjade rẹ naa pẹlu: ''Ọmọ ọkọ ni mi, emi ki i ṣe ọmọ ale Oyo State."

Alukoro PDP ipinlẹ Oyo, Michael Ogunsina, sọ nnkan kan naa

Bakan naa ni Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo, Michael Ogunsina, sọ pe wọn fi owo nla lọ Adebo Ogundoyin, Abẹbugan ile igbimọ aṣofin Oyo, pẹlu tikẹẹti si ile igbimọ aṣoju ṣofin Oyo lati tako Gomina Seyi Makinde.

Lori eto ileeṣẹ amohumaworan kan, Dominion Television, niluu Ibadan, ni iroyin sọ pe Ogunsina ti sọrọ yii.

O ni awon kan n gbiyanju lati da oju ijọba Makinde delẹ.

Bakan naa lo sọ pe Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Rashidi Adewolu Ladoja, bẹ Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Oyo lati darapọ mọ APC.

Ogunsina pẹlu tun darukọ Iyawo Ajimobi, Florence, pe oun naa lọwọ si bi wọn ṣe fẹ yọ Makinde nipo gomina.

O ni wọn ni ki Ogundoyin fi PDP silẹ, ko darapọ mọ APC to tobi daadaa, wọn si ṣeleri lati fun un ni tikẹẹti asoju Ila Oorun Ido/Ibarapa, ṣugbọn Abẹnugan ile igbimọ aṣofin naa ko gba.

Mo kọyin si iyọnipo, wọn fi owo lọ mi ṣugbọn mi o gba a - Olori ile asofin Oyo

Ẹni ti ọrọ iyọnipo yii kangun si ju, Ọnarebu Adebo Ogundoyin ti i ṣe Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Oyo naa ti sọrọ.

Ninu ọrọ rẹ to ti kari ayelujara, eyi ti Akọwe iroyin rẹ, Oyetunji Oyekunle fi sita ni Ogundoyin ti sọ pe irọ ni pe oun gba owo lọwọ awọn kan ninu APC lati yọ Gomina Seyi Makinde kuro nipo.

Ogundoyin sọ pe ko si ohun to jọ mọ ọrọ owo nibi ipade kankan.

O ni agbelẹrọ ọrọ ti awọn kan to pọ lati fi da ijọba ipinlẹ Oyo ru ni.

O fi kun un pe iṣẹ ọwọ awọn alatako ni gbogbo ahesọ yii, ero wọn si ni ki wọn da ile igbimọ aṣofin Oyo ru.

Mo lọ ṣepade kan l'Eko loootọ, amọ... - Ogundoyin

Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Oyo naa tẹsiwaju pe loooto loun lọ ṣe ipade kan niluu Eko.

O ni ṣugbọn oun kọ jalẹ fun wọn nigba ti wọn bẹrẹ si i sọrọ bii pe wọn fẹ fi owo abẹtẹlẹ lọ awọn aṣofin lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu alatako.

Ogundoyin sọ pe ẹsẹkẹsẹ loun ti kọ ọrọ naa fun wọn, nitori oun ko ni i dalẹ igbagbọ ti awọn eeyan Oyo ati ijọba Makinde ni ninu oun.

Koda, o ni oun sọ fun Gomina Makinde koun too lọ sipade ilu Eko naa, nibi ti oun n fi otitọ inu ba gomina lo de.

O tẹsiwaju pe boun ṣe de naa loun ti fun Gomina labọ ohun to ṣẹlẹ nibẹ, ati boun ṣe kọ lati dalẹ ijọba rẹ.

Ko si iye owo to le ra ile igbimọ aṣofin Oyo ni Ogundoyin wi.

"Mi o ni I lọwọ si eto kankan bo ti wu ko lowo lori to lati da oju ijọba ipinlẹ Oyo delẹ, tabi se akoba fun ijọba ti a fi fun Gomina Seyi Makinde"

Bẹẹ ni Abẹnugan Adebo Ogundoyin wi.

"Olubadan ti mo ṣabẹwo si, mo lọ beere iwure wọn nitori ipo gomina ti mo fẹ lọ fun ni"

Nipa lilọ si ọdọ Olubadan Ladoja, Ogundoyin sọ pe loootọ loun lọ sọdọ ọba naa, ṣugbọn ki i ṣe lati pete iwa oṣelu buburu kan.

Ogundoyin sọ pe abẹwo naa ti to ọsẹ mẹta bayii, ati pe ki nnkan le daa loun ba lọ .

O ni oun lọ sọdọ Olubadan Ladoja lati beere iwure rẹ fun ipo gomina toun fẹ lọ fun ni.

Abẹnugan naa sọ pe lati ọdọ Ọba Rashidi Ladoja loun ti bẹrẹ irinajo oṣelu ni 2017.

O ni Ọba naa lo tọ oun sọna oṣelu, oun si lọ ṣabẹwo si i lasiko yii lati bu ọla fun un, ki i ṣe fun ma jẹ a gbọ kankan.

Ẹ ma fa itẹ Olubadan wọ ẹrẹ̀ - Olubadan Rashidi Ladoja naa ṣalaye tiẹ

Ẹni ti a tiran mọ ko gbọdọ dakẹ ni Yoruba wi, bẹẹ gẹgẹ ni Olubadan Ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja naa ti sọrọ lori rogbodiyan to gbode ọhun.

Olubadan Ladoja to fi atẹjade sita lati ọwọ Akọwe iroyin rẹ,Adeola Oloko, lọjọ Iṣẹgun, ṣalaye pe irọ gbuu ni pe oun fẹ yọ Seyi Makinde kuro nipo gomina.

Ọba Ladoja sọ pe: "Lai deena pa ẹnu, irọ leyi"

'Ko ṣẹṣẹ digba ti eeyan ba jẹ gomina tẹlẹ tabi senẹtọ ko too mọ pe ọba kan ko lagbara lati yọ Alaga ijọba ibilẹ kuro nipo, ka ma ti i sọ pe Gomina ipinlẹ."

Ọba Ladoja ṣalaye pe ahesọ to buru jai ni ẹsun awuruju ti awọn kan n gbe kiri nipa oun yii, o ni ki wọn ma ṣe wọ ori itẹ Olubadan wọnu ẹrẹ̀, itẹ iyi ni.

Emi ko pe ipade kankan lati yọ Gomina Makinde o- Florence Ajimobi

Lati yọ orukọ rẹ kuro ninu ọrọ to gbode yii, Iyawo Oloogbe Abiola Ajimobi; Florence, naa ṣalaye ara rẹ.

Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin obinrin akọkọ nipinlẹ Oyo nigba kan naa fi sita lo ti ṣapejuwe ọrọ naa bii ailẹsẹ nilẹ.

Florence Ajimobi sọ pe irọ ni gbogbo ẹ delẹ, ati pe awọn to gbe e kalẹ mọ ọn mọ ṣe bẹẹ lati ba orukọ oun jẹ ni, ki wọn si ṣi araalu lọna.

Iya ti Aarẹ Tinubu fi ṣe aṣoju ipinlẹ Oyo lorilẹede Austria naa sọ pe:

"Ko si igba kan ti Ambassador Ajimobi pe, lọ tabi kopa ninu iru ipade bẹẹ pẹlu ẹnikẹni tabi ẹgbẹ lati sọrọ lori iyọnipo tabi dida ijọba ipinlẹ Oyo ru."

"Ohun ti PDP n ṣe nipinlẹ Oyo ko kan mi. Awọn oniwakiwa lo n pete yii, wọn fẹ ba orukọ mi jẹ ni"

O sọ pe oun ko lọwọ si ohunkohun to le da alaafia ipinlẹ Oyo ru ri.

Abilekọ Ajimobi wa rọ awọn araalu lati da iroyin naa nu, ki won ma si ṣe gba a gbọ rara.

O ni iru iroyin yii le da wahala oṣelu ti ko yẹ ko ṣẹlẹ silẹ, oun si le ki ọwọ ofin bọ ọ bi awọn to n pin kiri ko baa da a pada.

Sola, Ọmọ Olubadan Ladoja sọ ohun ti Ogundoyin lọ ṣe lọdọ baba rẹ

Bi awuyewuye yii ṣe n lọ lọwọ, Sola Ladoja to jẹ ọkan lara ọmọ Olubadan Ladoja naa ṣalaye ohun to mọ nipa ọrọ yii.

Sola Ladoja sọ pe Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Oyo, Adebo Ogundoyin, ko ba nnkan meji lọ sọdọ baba oun ju pe ki Kabiyesi ran an lọwọ lati di gomina ipinlẹ Oyo lọ.

O ni abẹwo Ogundoyin ko kan yiyọ Makinde rara.

Sola Ladoja sọ pe oun loun jẹ ki abẹwo Ogundoyin si Olubadan waye.

O ni bo si tilẹ jẹ pe ipade wọn jẹ mọ ọrọ osẹlu, o ni wọn wọn ko sọ nnkan kan nipa yiyọ gomina nipo rara.

"Bẹẹ ni, ipade naa jẹ mọ ti oṣelu, sugbọn ko sohun to jọ iyonipo, ko sohun to jọ APC nibẹ, bẹẹ ni ọrọ owo ko ṣẹlẹ nibẹ pẹlu."

Bẹẹ ni Sola Ladoja ṣalaye.

Fayose taku, o ni kawọn to ro pe irọ loun n pa maa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ

Ko kuku si ẹni ti yoo ke mọ onigẹgẹ pe ko gbe tọfun ẹ mi ni ọrọ ti Ayo Fayose n tẹnumọ ni tirẹ.

Bi gbogbo awon ti oro naa kan ṣe n sọ tẹnu wọn ni Fayose naa n sọ pe oun mọ ohun ti oun n sọ.

Loju opo X rẹ to ti bẹrẹ ọrọ iyọnipo Olubadan lo tun pada si, gomina Ekiti tẹle naa si kọ ọ sibẹ pe:

"Ki awọn to ṣi n ṣiyemi lorii pe Gomina Seyi Makinde fẹ yọ Olubadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, loye maa woye ọrọ bo ṣe n lọ.

" Ṣebi ẹ ranti pe wọn ti kọkọ ni ko sija laarin Olubadan ati Makinde lẹyin ti mo sọrọ nipa rẹ.

''Ṣugbọn ni bayii, wọn n fẹsun kan Olubadan pe o n pete ati yọ Gomina Makinde".

Fayose sọ pe ara iṣẹ ọwọ Makinde niyẹn, ko le baa fẹsun kan Olubadan pe o n ṣe ojuṣaaju.

Lọjọ Iṣẹgun ana, Fayose wọ ilu Ibadan, o ṣabẹwo si Olubadan Ladoja nile rẹ to wa ni Bodija.

Ayo Fayose to ko awọn eeyan lẹyin sọ pe oun lọ wo alaafia Ladoja ni.

Ọba Ladoja naa ki i kaabọ ni nnkan bii aago marun-un irọle ku iṣeju mẹwaa to de, o si mu wọ iyẹwu rẹ lọ lati sọrọ.

Ọrọ yii ko ti i pari sibẹ, ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe nnkan kan wa ti araalu ko mọ nipa ohun to n ṣẹlẹ niluu Ibadan yii, amọ o daju pe mẹwaa n ṣẹlẹ labẹnu.

Bo pẹ titi otitọ ọrọ yoo foju han.