You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Nàìjíríà kéde orúkọ àwọn afurasí tó ń ran ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́
Ko din ni orukọ eeyan mejidinlogoji (48), ati ẹgbẹ mejila ti ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti fi sita bayii gẹgẹ bi awọn ti wọn fura si pe wọn n ran awọn agbebọn lọwọ ni lorilẹede yii.
Iwe orukọ ti wọn fi lede lọjọ Ẹti, ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii, wulẹ sọ diẹ nipa awọn ti wọn fẹsun kan naa ni.
Igbimọ 'Nigeria Sanctions Committee' (NSC) to gbe awọn orukọ naa jade ko sọ ọmọ orilẹede ti wọn jẹ, bẹẹ ni ko ṣalaye bi ipa ti wọn ti ko ninu igbesunmọmi ṣe pọ to.
Bakan naa ni wọn ko ṣalaye kikun nipa iru ẹgbẹ gan-an ti wọn wa, wọn ko si fi fọto wọn lede lati fi oju wọn han, tabi sọ boya ọkunrin tabi obinrin ni wọn.
Iwe orukọ ti wọn fi lede yii, jade bi igbẹjọ awọn afurasi ẹẹdẹgbẹta (500) ṣe fẹ bẹrẹ lọsẹ yii.
Eeyan to din ni aadọrin (386) ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn jẹbi igbesunmọmi ninu igbẹjọ .
Awọn wo ni wọn darukọ?
Iwe ti Nigeria Sanctions Committee (NSC) fi lede naa ko fi alaye pupọ han.
Ọkan lara awọn afurasi naa ni olori ogun (Quaid), fun ẹgbẹ Islamic State of West Africa Province (ISWAP) Okene.
Oun ni afurasi ti wọn lo ṣọṣẹ nibi ikọlu ile ijọsin St. Francis Catholic Church, Owo, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti pa ọpọ eeyan lọjọ karun-un oṣu Kẹfa ọdun 2022.
Afurasi yii naa ni wọn lo tun mọ nipa bawọn agbebọn ṣe yabo ọgba ẹwọn Kuje, l'Abuja, lọjọ karun-un, oṣu Keje ọdun 2022.
Afurasi miran ni wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Ansarul Muslimina Fi Biladissudam (ANSARU).
Ẹgbẹ yii ni wọn lo rọ mọ Al-Qaeda for di Islamic Maghreb (AQIM).
NSC ṣalaye pe afurasi yii ti gba ẹkọ ija pupọ, o si ṣiṣẹ labẹ Muktar Belmokhtar tawọn eeyan mọ si One Eyed.
"Koko iṣẹ rẹ ni ko maa ṣeto ibaraẹnisọrọ labẹnu fawọn agbesunmọmi, o si tun jẹ ọga ninu ado oloro ṣiṣe.
Oun tun ni aṣọna fun olori ẹgbẹ ANSARU, Mohammed Usman (Khalid Al-Bamawi).
Bakan naa lo tun jẹ iranṣẹ ati atọna fun AQIM Katibat, ninu aṣalẹ̀ Algeria ati Mali".
Bẹẹ ni igbimọ NSC wi.
Afurasi ISWAP
Afurasi mi-in ti wọn tun tọka si jẹ olori ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP.
NSC ṣalaye pe ọkan lara awọn olori ẹgbẹ naa ni Guusu-Iwọ oorun ni.
Oun ni wọn lo n wa owo fun wọn nilana ori ayelujara ti a mọ si Crypto currency.
Lara awọn afurasi yii jẹ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram bi wọn ṣe wi, wọn ṣe ikọlu, wọn n gba owo itusilẹ, wọn si tun n kọ ẹkọ igbesunmọmi.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ẹka to n ri si ọrọ aabo nilẹ America, gba awọn ọmọ ilu wọn niyanju lati ma ṣe wa si Naijiria lasiko yii, nitori ijinigbe, igbesunmọmi ati aisi aabo gbilẹ nibẹ kankan.