You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ múra o! Òjò ńlá tó le fa àgbárá òjò ń bọ̀ ní ìpínlẹ̀ mẹ́wàá - NiMet
Ajọ to n ri si bi oju ọjọ ṣe ri ni Naijiria iyẹn Nigerian Meteorological Agency ti ṣekilọ pe ojo nla maa rọ to si ṣeeṣe ko fa ẹkunwọ omi ati agbara ni awọn ipinlẹ mẹwaa kan.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ naa fi lede ni ọjọru, ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹrin, wọn ni ojo naa maa rọ laaarin ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹrin si ọjọ Kejila, oṣu Kẹrin ọdun 2026.
Ninu atẹjade ti ajọ naa fi sita lọjọru ni wọn ti tun sọ pe iji yoo waye lawọn ipinlẹ kan nigba ti oorun yoo si jade lawọn ibomiran.
Wọn sọ pe awọn ilu kan ni awọn ipinlẹ Ebonyi, Anambra, Ogun, Taraba, Cross River, Benue, Imo, Delta, Rivers, ati Abia ni o ṣeeṣe ki omiyale agbara ya ṣọọbu ti ṣọṣẹ.
Ajọ naa ni o ṣee ṣe ki ara san lọsan an lasiko ti ojo ba n rọ tabi lalẹ lawọn ipinlẹ naa.
Laarin gbungbun ẹkun ariwa Naijiria, ajọ Nimet ni kurukuru yoo wa loju ọrun, o si ṣee ṣe ki ara san ki iji lile si fẹ nipinlẹ Plateau, Abuja, Niger, Nasarawa, Kwara, Kogi ati nipinlẹ Benue lọsan an tabi lọwọ alẹ.
Nimet ni kawọn eeyan to wa lẹkun guusu Naijiria maa reti ojo tori o ṣee ṣe ki ara san laarọ lawọn apa ibikan nipinlẹ Cross River ati Akwa Ibom.
Ajọ naa sọ pe kawọn eeyan to n gbe lawọn ipinlẹ to wa lẹkun guusu yoku naa mura silẹ fun ara ati iji lile lọwọ alẹ.
Ajọ Nimet tun fi kun pe oorun yoo jade lọpọ agbegbe ni ẹkun ariwa Naijiria, amọ, o ṣee ṣe ki ara san lasiko ti ojo ba n rọ ni ọsan tabi lalẹ.
Wọn tun ni oorun yoo jade lẹkun aarin gbungbun apa ariwa, ṣugbọn awọn eeyan ipinlẹ Kogi, Nasarawa, Plateau, Benue ati Abuja gbọdọ mura silẹ fun iji lile ati ara.