You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí o ṣe lè wo, tàbí ṣe àtẹ̀jáde ìwé atọ́nà pélébé fún ìdánwò Jamb UTME
Ajọ to n ṣe aayan idanwo aṣewọle si ile ẹkọ giga gbogbo lorilẹede Naijiria JAMB ti kede pe awọn akẹkọọ to fẹ ṣe idanwo aṣewọle sawọn ileẹkọ giga gbogbo lorilẹede Naijiria lọdun yii lee bẹrẹ si ni lọ ṣe atẹjade iwe pelebe afinimọna fun idanwo naa eyi ti wọn pe ni "JAMB Exam slips".
Ninu atẹjade to fi si oju opo ayelujara X rẹ ni Ọjọbọ̀, ajọ JAMB ni awọn akẹkọọ to fẹ ṣe idanwo naa le bẹrẹ si ni kan si oju opo ayelujara ajọ naa lati tẹẹ jade.
Ninu iwe atẹjade pelebe naa ni iroyin nipa ibudo ti akẹkọọ kọọkan yoo ti joko ṣe idanwo, ọjọ ti akẹkọọ̀ kọọkan yoo ṣe idanwo tirẹ pẹlu akoko.
Ṣaaju ni ajọ JAMB ti sọ ninu ikede rẹ kan pe laarin ọjọ kẹrindinlogun si ikarundinlọgbọn oṣu kẹrin ni idanwo naa yoo waye.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi suta lọjọ Abamẹta, ajọ̀ naa rọ awọn akẹkọọ to fẹ ṣe idanwo naa ataraalu lati kọ eti ọ̀gbọin si awọn iroyin kan to n lọ kaakiri pe wọn ti sun idanwo naa siwaju, to si tẹnumọ ọ pe ajọ JAMB ko mọ si ikede iroyin ẹlẹjẹ naa.
Bawo ni o ṣe le wo iwe atọna pelebe fun idanwo Jamb?
Ajọ naa ṣalaye awọn igbesẹ fun wiwo iwe pelebe naa ati titẹẹ jade latori ayelujara.
Awọn igbesẹ naa niwọnyi ni ṣisẹ n tẹle:
- Akọkọ: Lọ si oju opo Jamb ni www.jamb.gov.ng
- Tẹ oju abala ti wọn kọ '2026 UTME Slip Printing' si
- Fi nọmba iforukọsilẹ rẹ, iyẹn 'Registration number'rẹ sibẹ