Àlàyé lórí ohun tó fa rògbòdìyàn inú ẹgbẹ́ ADC, èyí tó jẹ́ kí INEC yẹ àga máwọn adarí ẹgbẹ́ náà nídìí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Wahala to n sẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC tun bẹyin yọ lẹyin ti igun mii to n ṣatilẹyin fun oludije sipo aarẹ lọdun 2023, Dumebi Kachikwu, yọju.

Igun yii si kọ ẹyin si igun aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja tẹlẹ, David Mark ati igun Nafiu Gombe.

Igun tuntun yii sọ fawọn akọroyin niluu Abuja wi pe awọn faramọ igbesẹ ajọ eleto idibo INEC lori bi o ti yẹ aga mawọn olori ẹgbẹ ADC ti Mark ko sodi nidii latari idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Kingsley Temitope to jẹ alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Kogi ni igun tuntun yii yan gẹgẹ bi adele alaga apapọ ẹgbẹ naa.

Bakan naa ni wọn lawọn o faramọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ti Nafiu Bala Gombe ko sodi.

Igun tuntun yii ti ọpọ alaga ipinlẹ wa nibẹ fẹsun kan alaga apapọ ẹgbẹ naa tẹlẹ, Ralph Nwosu, wi pe oun lo fẹ gbe ẹgbẹ awọn fun igun David Mark.

Amọ, Bolaji Abdullahi

Nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ ADC lọwọ yii

Awuyewuye lori igbimọ adari ẹgbẹ oṣelu ADC bẹrẹ loṣu Keje ọdun 2025 nigba tawọn adari ẹgbẹ naa kọwe fipo silẹ ti David Mark si di alaga fidihẹ.

Awọn oloye ẹgbẹ mii naa gba ipo lai si alatako kankan fun wọn.

Ṣugbọn Nafiu Gombe tako igbesẹ naa, o ni ẹgbẹ gbọdọ tẹle iwe ofin ẹgbẹ.

Ọpọlọpọ nnkan lo ti ṣẹlẹ lẹnu ọjọ mẹta yii eyi to jẹ ki rogbodiyan to n lọ ninu ẹgbẹ naa buru sii.

Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Rabiu Kwankwaso, kilọ fun Bala wi pe igbesẹ to n gbe le ṣakoba fun ijọba awarawa orilẹede Naijiria.

Kwankwaso loun ranṣẹ pe Bala wi pe ko jẹ kawọn yanju ọrọ naa, ṣugbọn ko yọju.

Gomina ipinlẹ Kano sọ pe ki ẹnikẹni to ba mọ Bala ba a sọrọ pe ko ma ba ẹgbẹ jẹ.

Kwankwaso to darapọ mọ ADC lati ẹgbẹ oṣelu NNPP lọgbọnjọ oṣu Kẹta ọdun 2026 fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu DCL Hausa.

A o ni gba ki ẹnikẹni ja ẹgbẹ ADC gba mọ wa lọwọ – Nafi'u Bala Gombe

Nafi'u Bala Gombe to jẹ ẹni to wa laarin gbungbun rogbodiyan naa ṣalaye fun BBC Hausa wi pe idi to fi tako igun adari David Mark.

Ede-ai-yede bẹ silẹ ninu ẹgbẹ ADC lẹyin ti ajọ INEC yọ orukọ Mark gẹgẹ bi adari ẹgbẹ lori itakun agbọrọkaye wọn, latari idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Bala Gombe ni oun si ni alaga ẹgbẹ ADC to tọna labẹ ofin, o sọ pe wọn kan n foju kere oun ni nitori ọjọ ori oun.

O ni idi gan an niyi toun fi n ja fun ẹtọ oun.

''Wọn kede ara wọn gẹgẹ bi adari ẹgbẹ lẹyin ti wọn darapọ mọ ẹgbẹ ADC tan nitori ọjọ ori tiwa kere si wọn.

Ọlọrun lo fi mi sipo yii, n ko si le gba ki wọn yan mi jẹ,'' Bala Gombe lo sọ bẹẹ.

Bala Gombe ni ko ba ofin mu ki eeyan to ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu sọ ara rẹ di adari ẹgbẹ lẹsẹ kẹsẹ.

''Wọn ro pe awọn le jẹ gaba lori wa tori wọn lowo, wọn si tun lorukọ.

Idi niyii ti a ko fi ni gba fun wọn.''

Awọn agba ninu ẹgbẹ bii Igbakeji Aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar ati Kwankaso ti kepe Bala Gombe wi pe ko yẹba.

Amọ, o ni oun ko ni gba bo tilẹ awọn agba ẹgbẹ ju oun lọ gan an.