Ìjíròrò láàárín Amẹ́ríkà àti Iran láti fòpin sí ogun forí sánpọ́n

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti Iran ti kọ̀ láti fẹnukò láti fòpin sí ogun lẹ́yìn tí àwọn méjéèjì kọ̀ láti fẹnukò lórí àwọn ìbéèrè wọn.

Ní ọjọ́rú ni orílẹ̀ èdè méjéèjì fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n fi jíròrò lórí àwọn nǹkan tó ń fa ogun náà àti bí wọ́n ṣe le parí rẹ̀.

Ìlú Islamabad, olú ìlú orílẹ̀ èdè Pakistan ni wọ́n fẹnukò pé kí ìjíròrò náà ti wáyé lẹ́yìn ìgbésẹ̀ ààrẹ Pakistan àti ààrẹ China dá sí ìkọlù tó ń wáyé náà.

Àwọn nǹkan tí Amẹ́ríkà ń bèèrè kò tọ̀nà lábẹ́ òfin - Iran

Àmọ́ lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní iléeṣẹ́ ìròyìn Iran fi ìkéde síta pé Iran àti Amẹ́ríkà kò ríbi fẹnukò lórí ìgbésẹ̀ àlááfíà nítorí àwọn nǹkan tó lágbára tí Amẹ́ríkà ń bèèrè fún.

Wọ́n ní àwọn ti so ìjíròrò náà rọ̀ fún ìgbà kan ná nítorí gbogbo akitiyan àwọn láti jẹ́ kí ìjíròrò náà lọ déédéé kó sì so èso rere ló já sí pàbó látàrí àwọn nǹkan tí kò wúlò tí Amẹ́ríkà ń bèèrè fún.

Bákan náà ni agbẹnusọ iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè Iran, Esmaeil Baqaei nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìjíròrò náà sọ pé àṣeyọrí ìjíròrò náà wà lọ́wọ́ Amẹ́ríkà.

Ó ní òun kò lérò pé ẹnikẹ́ni máa gbàgbọ́ pé àwọn máa fẹnukò kíákíá àti pé ó ṣòrò kí àwọn fẹnukò lẹ́yìn ìpàdé kan ṣoṣo.

Baqaei sọ pé Amẹ́ríkà nílò láti dènà bíbéèrè fún àwọn ohun tó lágbára àtàwọn ohun tí kò bá òfin mu, kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àti ìfẹ́ Iran.

Lára àwọn ohun tó ní àwọn jíròrò lé lórí ni Strait of Hormuz, ètò ṣíṣe àdó olóró "nuclear weapon" àti fífi òpin sí gbígbé ogun ti Iran pátápátá.

Ó fẹ̀sùn kàn pé ibi tí kò ti sí ìfọkàntán ni ìjíròrò náà ti wáyé, tó sì ní àwọn kò lè fẹnukò lẹ́ẹ̀kan náà lórí àwọn ìbéèrè kóówá àwón.

Kí ni Amẹ́ríkà sọ?

Ẹ̀wẹ̀, Amẹ́ríkà sọ pé àwọn nǹkan tí kò lágbára ni àwọn ń bèèrè lọ́wọ́ Iran, tí wọ́n sì mú ọgbọ́n dání.

Igbákejì Ààrẹ Amẹ́ríkà, JD Vance ní Trump rán òun láti ṣojú rẹ̀, tó sì ní kí òun ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn fẹnukò lórí àlááfíà.

Vance ní gbogbo nǹkan tí àwọn le ṣe ni àwọn ṣe ṣùgbọ́n tí àwọn kò rí ẹnu rẹ̀ fi gun ibìkan.

Ó ní òun àtàwọn ikọ̀ òun kò ríbi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Iran kò ní tẹ̀síwájú láti máa ṣe àdó olóró "nuclear weapon" tàbí láti wá nǹkan tí wọ́n fi le ṣe é kíákíá.

Ó sọ pé ohun tó jẹ Ààrẹ Amẹ́ríkà lógún jùlọ nìyẹn, tó sì fi àìdunnú rẹ̀ hàn pé wọn kò fénukò lórí rẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Vance kò mẹ́nuba Strait of Hormuz, ọ̀nà ojú omi tí wọ́n ń gbé epo rọ̀bì gbà tí Amẹ́ríkà ń fẹ́ kí Iran ṣí, èyí tí ìgbàgbọ́ sì wà pé ó jẹ́ kókó ìdí tí ìjíròrò náà fi ń wáyé.

Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè Pakistan sọ pé ó pọn dandan kí àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì dáwọ́ ogun dúró ná gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fẹnukò lé lórí tẹ́lẹ̀ títí ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n dá fi máa pé.

Kò ì tíì sí àrídájú bóyá ìjíròrò míì máa wáyé láàárín àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì tí ọ̀sẹ̀ méjì náà máa fi pé.