Mọ̀ nípa ààfààní tó wà nínú níní ìbálòpọ̀ déédé àtàwọn àìsàn tí ìbálòpọ̀ ń dènà wọn

Mọ̀ nípa ààfààní tó wà nínú níní ìbálòpọ̀ déédé àtàwọn àìsàn tí ìbálòpọ̀ ń dènà wọn

Oluwa to wa da ni takọtabo mọ idi to fi ṣe bẹẹ, ibalopọ takotabo ko si kere ninu iṣẹ ti Adaniwaye tori rẹ da awa eeyan.

Eyi naa lo fi jẹ pe yatọ si pe o wa fun igbadun ara ẹni ati ki eeyan le di ọlọmọ laye, ibalọpọ tun ni awọn anfaani to pọ rẹpẹtẹ.

Lara anfaani ibalopọ bi iwadii ṣe fidi ẹ mulẹ loju opo ayelujara Web MD ni pe nini ibalopọ deede lẹ jẹ ki ẹmi eeyan gun.

Akọkọ ni pe lasiko ibalopọ, ara maa n gbe omoonu (hormone) ta a mọ si Prolactin jade, eyi to maa n ṣe iranlọwọ fun eeyan lati sun, to si le mu adinku ba ẹjẹ riru ati ifunpa giga to ba fẹ da eeyan laamu.

Ọkunrin ba n damira ni ọpọ igba, o le mu adinku ba ewu ati ni aisan jẹjẹrẹ inu koropọn ti a mọ si Prostate cancer.

Nnkan miran ni pe ibalopọ loorekoore le ṣe iranlọwọ fun ọkan rẹ, nipa pe yoo ran ọkan rẹ lọwọ lati ti ẹjẹ jade daadaa kaakiri ara rẹ, eyi to le dena nini aisan ọkan lọjọ iwaju.

Iwadii tun fidi ẹ mulẹ pe ti ọkunrin ba n damira ni ọpọ igba, o le mu adinku ba ewu ati ni aisan jẹjẹrẹ inu koropọn ti a mọ si Prostate cancer.

Lasiko ibalopọ, ara maa n gbe awọn eroja kan ti a mọ si antibody-immunoglobulin, to maa n da aabo bo ara lọwọ awọn aisan oriṣiiriṣii jade.

Ara si tun maa n ṣe agbejade oomonu ti oloyinbo n pe ni endophines, to maa n mu adinku ba ori fifọ ati ara riro.

Ìkìlọ̀ nípa ìbálòpọ̀ gbogbo ìgbà

Looootọ ni pe ibalopọ wulo o si wuyi fun awa eeyan, ikilọ to wa nibẹ ni pe eeyan gbọdọ ti to ẹni ọdun mejidinlogun, (18) ko to yẹ ko dabaa lati ni ibalopọ.

Ibalopọ ko si fun ọmọde rara.

Bakan naa ni eeyan ko gbọdọ ni ibalopọ ipa, o ko si gbọdọ ṣe e nilana to le mu ọ lufin.

Ti ẹ ba si fẹ ni ibalopọ pẹlu ẹni ti ki i ṣe ololufẹ yin ti ẹ gbe silẹ ti ẹ si jẹrii, ẹ ri i daju pe ẹ lo rọba idaboobo.

Bi ohunkohun ba ru yin loju lori ibalopọ, ẹ kan si awọn oṣiṣẹ eto ilera.