Wo àwọn ohun tó yẹ láti ṣe bí o bá jí ní òwúrọ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọ̀kan lára ètò ìlera tí ó máa ń fa àríyànjiyàn ni ohun tó yé kí èèyàn ṣe nígbà tí èèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jí pàápàá ní òwúrọ̀.

Onírúurú ìròyìn ni a ti máa ń gbọ́ nípa bí ẹ̀rù ṣe máa ń ba àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ dìde lórí ibùsùn lẹ́yìn tí wọ́n bá jí, tí èyí sì máa ń fa ìṣòro míì fún wọn.

Dókítà Khadija Mormoni, Onímọ̀ ètò ìlera ní ilé ìwòsàn olùkọ́ni Kaduna State Teaching Hospital ní Barau Dikko sọ pé ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ tí èèyàn bá jí ni kí èèyàn kọ́kọ́ sinmi.

Dókítà Khadija sọ pé ohun tí èèyàn nílò láti kọ́kọ́ ṣe ni kí èèyàn fara balẹ̀ sórí ibùsùn láti sinmi fún ìgbà díẹ̀.

"Èèyàn le lo àsìkò yìí láti ronú nípa ohun tí èèyàn fẹ́ ṣe lọ́jọ́ náà, gbàdúrà tàbí ṣèrántí ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun míì."

Ó ṣàlàyé pé àsìkò tí èèyàn fi ń sinmi yìí ṣe pàtàkì gan nítorí ó máa ń jẹ́ kí èèyàn ní ìrònújinlẹ̀, jí ọpọlọ èèyàn sílẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ òòjọ́ ọjọ́ náà, tí yóò sì jẹ́ ohun gbogbo lọ létòlétò.

Dókítà náà ní ohun kejì tó ṣe pàtàkì ni kí èèyàn mu omi tó lọ́wọ́rọ́ díẹ̀, tí èèyàn sì lè fi omi òrombó díẹ̀ sí.

"Ó dára kí èèyàn mu omit ó lọ́wọ́rọ́, èèyàn le fi òrombó díẹ̀ si tàbí kí èèyàn mu omi náà lásán.

"Omi náà máa fọ àwọn ẹ̀yà ara inú èèyàn mọ́. Ó máa ṣe ìrànwọ́ láti fọ àwọn oúnjẹ tí èèyàn ti jẹ láti àná nù, kí èèyàn tó máa jẹ tuntun mọ́ ọn."

Ó ṣàlàyé pé tí oúnjẹ tí èèyàn bá jẹ láti àná kò bá kúrò ní ara tí èèyàn fi ń jẹ oúnjẹ míì mọ, ó le fa kí inú èèyàn le ju bó ṣe yẹ lọ, tó sì lè máa fa kí inú èèyàn tóbi.

Dókità náà fi kun pé ó dára kí èèyàn ṣe eré ìdárayá díẹ̀, kí gbogbo Egungun ara le tò, kí èèyàn tó máa bá iṣẹ́ míì lọ lẹ́yìn tí èèyàn bá jí.

Lẹ́yìn àwọn èyí ni dókítà ní ó sàn láti wẹ̀, kí èèyàn sì jẹun aṣaraláoore.

Kí ni àwọn nǹkan tó yẹ láti jìnà sí tí èèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jí?

Lórí àwọn nǹkan tó yẹ láti jìnà sí tí èèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jí, Dókítà Khadija ní kò yẹ láti kọ́kọ́ fóònù tí èèyàn bá kọ́kọ́ jí nítorí iná tó máa ń tàn lójú fóònù máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báa èèyàn ni.

Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wádìí lórí ohun tó máa ń fa kí òyì ojú máa kọ́ èèyàn, kí èèyàn dá kú tàbí kí orí máa fọ èèyàn tí wọ́n bá dìde lórí ìbùsùn ní kété tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jí, ó ní èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ kìí ṣàn púpọ̀ lára nígbà tí èèyàn bá ń sùn.

"Iye ẹ̀jẹ̀ tó máa ń ṣàn lọ sínú ọpọlọ máa ń dínkù. Ọpọlọ ló máa ń ṣàkóso àwọn ẹ̀yà ara yòókù, tó sì jẹ́ pé tí ẹ̀jẹ̀ kò bá ti ṣàn bó ṣe yẹ, àwọn ẹ̀yà ara yòókù náà kò ní ṣiṣẹ́ dáadáa.

"Òhun ló máa ń fa òyì ojú fún ẹlòmíì, kí èèyàn ṣubú, dákú, tó sì lè ṣokùnfà ikú èèyàn nígbà míì."

Dókítà Khadija fi kun pé ohun dára ni kí èèyàn fún ara rẹ̀ láàyè, kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn sí gbogbo ibi tó yẹ láti inú ọkàn lẹ́yìn tí èèyàn bá jí nípa kí èèyàn sinmi dáadáa lórí ìbùsùn kí ó tó dìde.

Ó ní àwọn nǹkan tó máa ń fa kí ẹ̀jẹ̀ má ṣàn bó ṣe yẹ ni ọjọ́ orí, àìsàn ọkàn, oòrùn àsùnjù, oyún níní, àti lílo àwọn oògun kan fún ìgbà pípẹ́.

Àmọ́ ó wòye pé ẹni tí kò bá ní ọ̀kan nínú àwọn àìlera tí a kà sókè yìí, tó sì máa ń ní òyì ojú nígbà tí ó bá dìde lórí ìbùsùn kódà lẹ́yìn tó bá fara balẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kó tó dìde, ẹni náà nílò láti lọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú tó péye.

Ó fi kun pé, fún àwọn àgbàlagbà àti àwọn aláboyún, ó ní ó sàn tí wọ́n bá fẹ́ dìde lórí ìbùsùn lẹ́yìn tí wọ́n bá sinmi díẹ̀ tán láti yí sí ẹ̀gbẹ́, kí wọ́n fi ẹ̀gbẹ́ dìde díẹ̀díẹ̀ láti jòkòó, kí wọ́n tó dìde pátápátá, kí wọ́n sì na ara wọn.