Wo kókó ìpàdé àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, tó bẹ̀rẹ̀ lónìí láàrin ọ̀pọ̀ awuyewuye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC ní gbogbo ètò ló ti wà ní sẹpẹ́ láti ṣe àpérò ẹgbẹ́ náà níbi tí wọ́n ti máa yan àwọn aláṣẹ tuntun fún ẹgbẹ́ náà.

Ní ìlú Abuja tó jẹ́ olú ìlú Nàìjíríà ni àpérò náà yóò ti wáyé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2026 ní gbọ̀ngán Rainbow Event Center.

Lópin ọ̀sẹ̀ ni igun tí David Mark ń darí rẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú ADC ọ̀hún ṣe àpérò láti yan àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n sì ní àpérò àpapọ̀ yóò wáyé lónìí.

Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ní onírúurú ìpèníjà ni àwọn kojú láti rí ibi tí àpérò náà ti máa wáyé nítorí ìjọba kọ̀ láti fún àwọn láàyè láti lo Eagles Square, Abuja.

A máa ṣe àpérò wa, kódà, bó jẹ́ orí títì láti máa ṣé

Ọ̀kan lára àwọn agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà, Faisal Kabir sọ fún BBC pé àwọn kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìjọba láti jẹ́ kí àwọn lo gbọ̀ngán náà ṣùgbọ́n wọn kò fún àwọn láàyè.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn tún fẹ́ lo pápá ìṣeré Abuja tí wọn kò sì tún fún àwọn ní gbọ̀ngán náà.

Ó ní gbogbo àwọn aládàni tí àwọn kàn sí láti fún wọn ní gbọ̀ngán fún àpérò náà ni ìjọba ń dúnkokò mọ́ wọn pé wọn kò gbọdọ̀ gba àwọn láàyè.

Kabir sọ pé bí àwọn ṣe kojú ìpèníjà nígbà tí àwọn fẹ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà kí àwọn tó rí gbọ̀ngán Shehu Musa Yar'adua nígbà náà.

Ó sọ pé pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tí àwọn ń kojú náà kò ní dí àwọn lọ́wọ́ láti ṣe àpérò náà nítorí kódà kó jẹ́ pé orí títì ni àwọn bá ti máa ṣé.

A kò dènà ADC láti lo gbọ̀ngán Eagles Square, wọn ò kọ̀wé pé àwọn fẹ́ lo gbọ̀ngán náà - Wike

Àmọ́ Mínísítà fún olú ìlú Abuja, Nyesom Wike ti jiyàn ẹ̀sun tí ẹgbẹ́ náà fi kan ìjọba pé wọn kò pèsè gbọ̀ngán Eagles Square fún wọn láti lò.

Wike ní ẹgbẹ́ náà kò kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìjọba láti bèèrè fún gbọ̀ngán, tó sì pè wọ́n níjà pé kí wọ́n fi ìwé tí wọ́n fi bèèrè fún gbọ̀ngán náà léde tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n bèèrè fún-un.

Wike ní kò sí ìgbà kankan tí àwọn dí ẹgbẹ́ òṣèlú kankan láàyè láti lo gbọ̀ngán Eagles Square fún ohunkóhun níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti kọ̀wé ránṣẹ́ pé àwọn nílò rẹ̀.

Ó fi kun pé kò sí ìdádúró kankan tó wáyé fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP nígbà tí wọ́n fẹ́ lo gbọ̀ngán náà lóṣù tó kọjá níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ṣe ohun tó yẹ, tí wọ́n sì san gbogbo owó tó tọ́.

Kí ni kókó àpérò náà dá lé lórí?

Gẹ́gẹ́ bí àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú yòókù, níbi àpérò yìí ni wọ́n ti máa yan àwọn adarí tí yóò máa ṣe àkóso ẹgbẹ́ náà níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.

Ní ọdún tó kọjá ni ẹgbẹ́ náà yan àwọn adarí láti máa ṣàmójútó ẹgbẹ́ náà fún ìgbà kan ná lábẹ́ ìdarí David Mark.

Ibi àpérò yìí ni wọ́n ti máa wá yan adarí yálà nípasẹ̀ fífún àwọn tó wà níbẹ̀ láti máa báṣẹ́ wọn lọ tàbí kí wọ́n yan àwọn mìíràn.

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2026 ni ẹgbẹ́ náà ní àwọn máa ṣe ìbúrawọlé fún gbogbo àwọn adarí tí wọ́n dìbò yàn káàkiri gogbo ìpínlẹ̀ tó wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìgbẹ́jọ́ ADC ń wáyé nílé ẹjọ́ lónìí

Àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ló ń wáyé ní ọjọ́ kan náà tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ń gbọ́ ẹjọ́ lórí làásìgbò tó ń wáyé lórí àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Igun David Mark ló gbé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ sílé ẹjọ́ tó ga jùlọ níbi tí wọ́n ti ń bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ náà da ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù Kẹta ọdún 2023.

Ṣáájú ni igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà tẹ́lẹ̀ rí, Nafiu Bala Gombe ti pe David Mark lẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga pé wọ́n gba àṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC mọ́ àwọn kan lọ́wọ́.

Àmọ́ David Mark lọ sí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn pé kí wọ́n má fi ààyè gba ilé ẹjọ́ gíga láti gbọ́ éjọ́ tí Gombe pè ní ilé ẹjọ́ gíga, pé ilé ẹjọ́ náà kò ní àṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ náà.

Ẹ̀wẹ̀, ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn da ẹjọ́ náà nù, tí wọ́n sì ní kí ilé ẹjọ́ gíga gbọ́ ẹjọ́ náà.

Lẹ́yìn ìdájọ́ náà ni àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC yọ orúkọ David Mark àtàwọn míì kúrò lójú òpó wọn gẹ́gẹ́ bí adarí ADC.

INEC tún ṣèkìlọ̀ fún ADC láti má tẹ̀síwájú pẹ̀lú àpérò tí wọ́n fẹ́ ṣe náà títí ilé ẹjọ́ fi máa dájọ́ wọn.