You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ìdí rèé tí gómìnà kan fi le yọ ọba nípò lábẹ́ òfin
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹrin ni ìròyìn gbòde pé gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ń gbèrò láti yọ Olubadan ilẹ̀ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja nípò.
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí fún ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose ló fẹ̀sùn kan bẹ́ẹ̀ nínú àtẹ̀jáde tó fi sójú òpó X rẹ̀.
Ó fẹ̀sùn kàn pé Gómìnà Makinde ti pètè pèrò, tó sì ti ń ka àwọn ẹ̀sùn kan láti fi yọ Olubadan nípò nítorí kò kópa níbi ayẹyẹ gbígba adé àwọn ọba mẹ́ta tó wáyé ní ìlú Ibadan lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Ìròyìn náà fa awuyewuye lórí ayélujára tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti ààfin Olubadan sì ti sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ pé àhesọ lásán, irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ẹ̀sùn náà.
"Àwọn gómìnà ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti gba adé lórí ọba tí ìgbésẹ̀ tàbí ìwà rẹ̀ bá jọ mọ́ ìwà àṣemáṣe"
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oyè àjẹrọ̀run ni oyè ọba jíjẹ nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́, tó jẹ́ pé ikú ló máa ń gba aṣọ lára eégún wọn ṣùgbọ́n nǹkan ti yípadà lóde òní.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn gómìnà ti gba adé lórí àwọn ọba fún ìdí kan tàbí òmíràn tí wọ́n sì fi ẹlòmíràn rọ́pò wọn lójú ayé wọn.
Èyí ló mu wa kàn sí onímọ̀ òfin láti mọ̀ nípa ohun tó le ṣokùnfà kí ìjọba fi àṣẹ gba adé lórí ọba àti ọrùn ilẹ̀kẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí amòfin Abdulfatah Adabaale ṣe ṣàlàyé, lábẹ́ òfin tó de àwọn ọba ní Nàìjíríà, gómìnà ìpínlẹ̀ kan le yọ àwọn ọba tó wà lábẹ́ àkóso ìpínlẹ̀ rẹ̀ nípò tó bá kẹ́fín pé ọba bẹ́ẹ̀.
Adabaale ṣàlàyé pé lábẹ́ òfin tó dé ọ̀rọ̀ oyè ní Nàìjíríà, ohun tó le mú kí ìjọba yọ ọba nípò ni ìwà àṣemáṣe èyí tí wọ́n máa ń pè ní "misconduct".
Ó ní àwọn gómìnà ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti gba adé lórí ọba tí wọ́n bá ri pé ìgbésẹ̀ tàbí ìwà ọba bẹ́ẹ̀ jọ mọ́ ìwà àṣemáṣe tó lòdì sí nǹkan tí wọ́n gbàgbọ́ nínú.
Ó sọ pé òfin kò là á mọ́lẹ̀ pé nǹkan báyìí ni dandan ló jẹ́ àṣemáṣe tí ìjọba le yọ ọba nípò lé lórí .
'Gómìnà le yọ ọba nípò tí ọba bẹ́ẹ̀ bá ń lọ́wọ́ nínú àìsí ààbò tàbí ṣe agbódegbà fáwọn agbéṣùmọ̀mí ní agbègbè rẹ̀'
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé lára àwọn ohun tó máa ń fa kí ìjọba yọ ọba nípò ni tí ọba bá wu ìwà àrínfín sí gómìnà tàbí àwọn aláṣẹ, tó sì hàn pé ìwà àrínfín ni ọba náà hù.
Ohun mìíràn tí Adabaale sọ pé ó le fa kí gómìnà yọ ọba nípò ni tí wọ́n bá rí i pé ọba bẹ́ẹ̀ ń lọ́wọ́ nínú àìsí ààbò tàbí pé ọba náà ń ṣe agbódegbà fáwọn agbéṣùmọ̀mí ní agbègbè rẹ̀.
Adabaale ní lẹ́yìn tí wọ́n bá yọ ọba tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípò tán, ó ṣeéṣe kí ọba bẹ́ẹ̀ tún fojú ba ilé ẹjọ́, kó sì kojú ìjìyà tó bá tọ́ síi.
Ó tún ṣàlàyé pé tí wọ́n bá ṣàwárí rẹ̀ pé ìyànsípò ọba ní èrú nínú, tó sì hàn pé ẹni tó wà lórí ipò kò tọ́ nípò ọba, ìjọba le gba adé lórí ọba bẹ́ẹ̀, kí wọ́n gbé fún ẹlòmíràn tí wọ́n bá sọ pé ó tọ́ sí.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, amòfin náà sọ pé gbogbo àwọn ìwà yìí ni ó wà lábẹ́ ìwà àṣemáṣe èyí tí wọ́n fi le yan ọba nípò.
Makinde, Olubadan fèsì lórí ẹ̀sùn Fayose pé ìjọba Oyo fẹ́ rọ Olubadan Ladoja lóyè
Gomina tẹ́lẹ̀ ni ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayoṣe, ke sita nirọlẹ ọjọ Aiku ana, pe Gomina Makinde n pete ati yọ Olubadan Rashidi Ladoja kuro nipo ọba.
Oju opo ayelujara X rẹ ni Fayose ti ke gbajare naa sita lánàá.
Fayose ni oun ri i gbọ nibi to ti dájú ṣáká, pe Gomina Seyi Makinde n pete ati yọ Olubadan kuro nipo ọba ninu ọsẹ yii.
Fayose kọ ọ sibẹ pe ẹsun ti Makinde fẹ fi kan Olubadan Ladoja ni pe ọba naa ko yọju sibi ti Gomina ti fi awọn oloye Ibadan mẹta jọba lọsẹ to lọ.
"Ń wo maa wo Ṣigidi Seyi Makinde to fẹ ṣere ẹtẹ niran"
O ni awon ẹsun miran tun ti wa nilẹ ti Makinde fẹ ni ki Olubadan dahun si, ti yoo si gbabẹ yọ ọ danu bii jìgá kuro lori àpèèrè ọba.
Gomina Ekiti tẹlẹ naa sọ pe oun yoo maa wo Ṣigidi Seyi Makinde to fẹ ṣere ẹtẹ niran.
Bi Fayose ṣe sọrọ naa ni oriṣiiriṣii ero ti n jade nipa rẹ lori ayelujara.
Ọpọ eeyan lo fi oju adarugudu silẹ wo o, wọn ni ohun ti ko ri bẹẹ ni Fayose n gbe kiri.
Gomina Makinde fèsì
Ko pẹ rara ti Gomina Seyi Makinde ti Fayose fẹsun kan fi dahun, ọjọ ti Ayodele sọrọ naa ni ijọba ipinlẹ Oyo da esi rẹ pada fun un.
Kọmiṣanna eto Iroyin ati Ọgbọn inu nipinlẹ Oyo, Ọmọọba Dotun Oyelade, ṣalaye pe ijọba ko gbiyanju rẹ, sọ ọ tabi gbe igbesẹ iyọnipo lori Ladoja ri.
Oyelade sọ pe:
" Ni bayii, awọn eeyan Naijiria naa mọ ẹni, ati iru ohun ti wọn le gbagbọ, paapaa nigba ti ikede ba ti ibi kan pato wa.
"Ijọba ipinlẹ Oyo ko gbiyanju rẹ, ba ẹnikẹni sọ ọ tabi gbe igbesẹ lori iru nnkan bẹẹ ri.
"O gbọdọ ni idi otitọ kan ti ijọba fi n gbe igbesẹ kọọkan ti wọn ba n gbe, niṣe lo si yẹ ki eyi to n ti ọdọ agbẹnusọ alatako ẹgbẹ wa ti ofin ko mọ wa yii tete bọ si ààtàn to ti wa."
Bẹẹ ni Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Oyo naa wi lori ibosi Fayose.
O ni oṣelu to ba ti kun fun akitiyan bii eyi lo maa n bi irọ ati agbelẹrọ, to si maa n sọ ijọba awaarawa di awẹ́wa.
Ahesọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni, yoo buru jai bi ko ba jẹ ahesọ - Olubadan
Nigba to n fesi si ọrọ to ti gbilẹ lori ayelujara naa, Akọwe iroyin fun Ọba Ladoja; Adeola Oloko, ṣapejuwe ohun ti Fayose sọ naa bii ahesọ ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ rara.
Oloko ṣalaye lọjọ Aiku naa, pe ko si ija kankan laaarin Gomina Makinde ati Olubadan Ladoja, to le fa ohun ti Fayose sọ yii.
"Yoo ti lọ buru ju bi ki i ba ṣe ahesọ.
"Emi o ri idi kankan ti aigbọra ẹni ye yoo fi wa laaarin Gomina Makinde ati Olubadan ilẹ Ibadan."
Bẹẹ ni Oluranlọwọ Olubadan lori ikede naa wi.
Bi awọn igun mejeeji ti ọrọ yii kan ti ṣe sọrọ ni ọpọ eeyan ti n sọ pe Ayo Fayose ki yoo le wi nnkan kan mọ bayii.
Wọn ni ero rẹ ko ni i ṣẹ mọ pẹlu.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to lọ ni Gomina Makinde sọ awọn agba oye Ibadan mẹta di ọba alaye nipinlẹ Oyo, bo tilẹ jẹ pe awọn to sọ di ọba naa ko yọju sibi ayẹyẹ naa rara.
Awọn ọba naa sọ pe awon 'busy' nigba naa ni
Olubadan Ladoja to yẹ ko wa nibẹ pẹlu ko yọju sibi ayẹyẹ to waye ni Gbọngan Mapo niluu Ibadan naa.
Eyi to fa a ti iroyin fi jade nigba naa, pe aarin Olubadan Ladoja ati Gomina Seyi Makinde ti daru.
Ṣugbọn awon mejeeji sọrọ nigba naa pe ko sija kankan laaarin awọn.
Lẹyin rẹ ni Ayo Fayose jade bayii, pe Makinde fẹ yọ Olubadan Ladoja nipo nitori ọba naa ko yọju sibi ayẹyẹ igbade oloye mẹta.