Ìdí rèé tí Iyabo Obasanjo ṣe gba kámú bí gbogbo ẹgbẹ́ APC l‘Ogun ṣe fa Yayi kalẹ̀ bíi olùdíje gómìnà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun ti kede pe Sẹnetọ Solomon Olamilekan Adeola (Yayi) ni oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ni 2027.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Abiodun fa Yayi kalẹ, lasiko ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun.

Ninu fidio kan ti Gomina Abiodun ti kede Yayi lo ti ni ẹgbẹ ti pinnu lori ẹni ti yoo ṣoju APC nipo gomina ni 2027.

"Lakọọkọ naa, a ti pinnu lori ẹni to yẹ ko gbe aisa ipinlẹ wa."

Bi Abiodun ṣe kede bẹẹ ni Yayi naa dide duro, ti ọpọ alatilẹyin si n ki i ku oriire tilu tifọn.

Ẹ o ranti pe Senetọ Iyabo Obasanjo-Bello naa ti jade pe oun fẹ dupo gomina Ogun ni 2027, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC kan naa, ki Gomina Dapo Abiodun too fa Yayi kalẹ bayii bii aayo ẹgbẹ bayii.

Iyabo Obasanjo juwọ silẹ fun Yayi, o loun ko dupo gomina Ogun mọ ni 2027

"Bi ipade awọn ẹgbẹ APC ogun ṣe waye lọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu Kẹrin 2026 yii, wọn kede Seneto Solomon Olamilekan Adeola (Yayi) bii oludije ti ẹgbẹ fẹnu ko si lati dupo gomina ninu ẹgbẹ wa ni 2027.

"Mo ki i ku oriire, mo si gbadura pe yoo ṣe aṣeyọri. Mo tun dupẹ lọwọ awọn agba ẹgbẹ wa pẹlu, ti wọn jẹ ko ṣee ṣe lati kopa ninu igbesẹ iyansipo naa.

"Latari igbesẹ yii, mo ti pinnu lati so erongba mi lati dupo gomina rọ.

''Si gbogbo ẹyin alatilẹyin mi kaakiri ipinlẹ Ogun, mo dupẹ gidi lọwọ yin fun aduroti yin ti ko yingin ni gbogbo asiko irinajo yii.

"A jọ maa tẹsiwaju pẹlu suuru, agbara ati ireti ni."

Eyi ni ọrọ ti Seneto Iyabo Obasanjo sọ nigba to n kede pe oun ko ni i tẹsiwaju ninu idije sipo gomina Ogun mọ ni 2027.

Ta a ni Solomon Olamilekan Adeola (Yayi)?

Wọn bi Solomon Olamilekan Adeola sileewosan Lagos Island Maternity, ipinlẹ Eko, lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ ọdun 1969.

Baba rẹ ni Ayinde Adeola Ogunleye, iya rẹ si ni Abeni Olasunbo Ogunleye.

Yayi ṣe igba kekere rẹ ni Alimosho, nibi to ti bẹrẹ ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ni State Primary School, Alimosho, l'Ekoo.

O lọ sile ẹkọ girama Community Grammar School, Akowonjo, ipinlẹ Eko.

Lẹyin naa lo lọ sile ẹkọ gbogboniṣe ilu Owo, l'Ondo, eyi to ti di Rufus Giwa Polytechnic bayii. Nibẹ lo ti gba oye ninu imọ iṣiro owo.

Oluṣiro agba ti a mọ si Chartered accountant ni Yayi, o si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ Association of Accounting Technicians.

Awuyewuye jẹyọ nipa ọmọ ilu ti Yayi jẹ nigba kan lori ipinnu rẹ lati di gomina Ogun, awọn alatako rẹ sọ pe ọmọ Eko ni, amọ awọn alatilẹyin oloṣelu naa sọ pe ibajẹ lasan leyi, wọn ni ọmọ Yewa, nipinlẹ Ogun ni Olamilekan Yayi.

Itan aye rẹ nidi oṣelu

Ọjọ aboki ti pẹ ninu eegungun ni ọrọ Solomon Adeola tawọn eeyan mọ si Yayi, ninu oṣelu.

Lati ilu Eko de ipinlẹ Ogun to pada si bayii.

Ṣaaju lo ti ṣe Sẹnetọ Iwọ-Oorun nipinlẹ Eko, lati ọdun 2015 titi de 2023.

Lati ọdun 2023 lo ti n ṣe Sẹnetọ fun Iwọ-Oorun Ogun.

Yayi ṣe alaga igbimọ to n ri si owo ilu nile igbimọ aṣoju nigba kan ri.