Arọ́bafin ni Sẹ́nétọ̀ Adeseun ni mo fi ní kó gáfárà fún ipò Mayegun ìlú Ogbomoso – Soun Ghandi Laoye

Arọ́bafin ni Sẹ́nétọ̀ Adeseun ni mo fi ní kó gáfárà fún ipò Mayegun ìlú Ogbomoso – Soun Ghandi Laoye

Lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun 2026 ni Ṣọ̀un ti ilu Ogbomọṣọ, Ọba Ghandi Afọlabi Laoye, Orumọgẹgẹ III ti paṣẹ lọ rọọkun nile fun Sẹnetọ Ayọade Adeṣeun kuro ni oye Mayegun ilu Ogbomọṣọ.

Ọrọ naa lo wu aawọ to n lọ labẹnu laarin Ọba Ghandi ati Sẹnetọ tẹlẹ naa eyi to ti n rugbo labẹnu fun awọn akoko diẹ.

Ninu ifọrọwerọ yii pẹlu BBC News Yoruba, Ṣọun ogbomọṣọ ti Ọgbẹni gbẹnusọ̀rọ fun ṣalaye pe iwa afojudi si aṣiwaju ẹni pẹlu aibọwọ fun oriade kunara awọn idi ti wọn fi ni ko ṣe gaya fun oye Mayegun na.

Ọbalaye naa ni Sẹnetọ Adeṣeun ko fi arinfin rẹ fun Ṣọun bo rara, koda o tun sọrọ alufansa sii ni gbangba.

Ki ni Adesun sọ ṣaaju?

Ṣaaju ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba ni Sẹnetọ Adeṣeun pẹlu ti sọ pe, kiigbọ-kiigba ni Kabiyesi naa ati pe ti inu rẹ nikan lo maa n fẹ lati ṣe. O ni awọn iwa wọnyii ti mu ki ilu naa pin yẹlẹyẹlẹ

Sẹnetọ Adeṣeun ni ireti ọpọ araalu ni pe asiko Ọba Adeoye Ghandi gẹgẹbi ẹni to ti jade kaakiri agbaye yoo mu idagbasoke ba ilu Ogbomọṣọ, amọṣa nisinsinyii, ohun ti awọn ri ni pe 'ọba to maa n gba imọran ara rẹ nikan ni'.

'Eyi ti wọn n ṣe yii pe awọn ni ki n lọ rọọkun naa, ki wọn maṣe wulẹ jẹ ki n lọ rọọkun, emi gan o fẹ ipo yẹn mọ nitori ẹni ti eeyan ba ṣiṣẹ pọ tik ii fi ọrọ lọ eeyan; a kii ṣe ọmọ kekere ninu ohun ti an ṣe yii…'