You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni ọ̀gágun Braimah táwọn agbésùnmọ̀mí ṣekúpa pẹ̀láwọn ọmọogun míràn ní Borno, Tinubu kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí àwọn tó ṣubú lójú ìjà?
Awọn agbesunmọmi ṣekupa Ọgagun Oseni Omoh Braimah atawọn ọmogun mii ni Benisheikh ni ijọba ibilẹ Kaga nipinlẹ Borno lanaa Ọjọbọ.
Ọgagun Braimah ni olori ikọ ọmogun 29 Task Force Brigade ni Benisheikh.
Ohun ti a gbọ ni pe lojiji lawọn agbesunmọmi naa ya wọ ibudo awọn ọmogun naa ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.
Ọkan lara awọn olori agbegbe naa, Zanna Lawan Ajimi, sọ fun BBC pe Ọgagun Braimah wa lara awọn ọmogun tawọn agbesunmọmi ṣekupa lasiko ikọlu naa.
''Ọgagun Braimah ba iṣẹlẹ naa lọ, a gbọ gbe awọn ọmogun naa gbiyanju agbara wọn lati da a pada fawọn agbesunmọmi naa.
Araalu ikan naa ku lasiko ikọlu ọhun, nigba ti ẹlomiran farapa.
Benisheikh ati Ngamdu lawọn agbesunmọmi naa ti ṣoṣẹ, awujọ mejeeji wa labẹ ijọba ibilẹ Kaga.
Awọn ọmogun naa pa ọpọ awọn agbesunmọmi papaa julọ ni Ngamdu,'' Ajimi lo sọ bẹẹ.
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun, Ọgagun agba Michael Onoja sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ni nnkan bi ago mejila aabọ Ọjọbọ ni ikọlu ọhun ṣẹlẹ ni Benisheikh.
O ni awọn ọmogun ṣekupa awọn agbesunmọmi lasiko ti wọn ṣekọlu si ibudo awọn ọmogun nipinlẹ Borno l'Ọjọru.
Ọgagun Onoja ni awọn agbesunmọmi naa fẹ fipa ya wọ ibudo ọmogun di 29 Task Force Brigad, amọ, awọn ọmogun koju wọn ti wọn si da ibọn bolẹ.
Onoja ni awọn agbesumọmi naa pẹyin da nigba tawọn ọmogun kọju ija si wọn.
Ọgagun Onoja sọ pe oloogbe Braimah lo lewaju awọn ọmogun naa.
O ni o ṣeni laanu wi pe awọn ọmogun kan ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ileeṣẹ ologun ko darukọ awọn ọmogun to ṣubu loju ija ninu ikọlu naa.
Ko tii si ẹgbẹ agbesunmọmi to ti sọ pe awọn lawọn wa nidi ikọlu ọhun.
Ta ni Ọgagun Braimah tawọn agbesumọmi pa ni Borno?
Ọgagun Oseni Braimah kẹkọọ gboye ninu ẹkọ itan nile ẹkọ giga ologun NDA loṣu Kẹsan an ọdun 2000.
Braimah tun gboye fasiti keji ninu ẹkọ idari eto aabo ati ogun nile ẹkọ giga fasiti NDU ni Islamabad.
Bakan naa ni o tun gboye ninu ẹkọ ọgbọn inu ati ibaṣepọ laarin awọn orilẹede agbaye laarin 2004 si 2006 ni fasiti ipinlẹ Benue.
Laarin ọdun 2016 si 2017, Ọgagun Braimah tun gboye fasiti keji ninu ẹkọ nipa eto aabo lati ile ẹkọ King's College niluu London.
Ọgagun Braimah ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ iṣọkan agbaye UN laarin ọdun 2011 si 2012.
Oun ni igbakeji ọga ologun ni olu ileeṣẹ ọmogun Guard Brigade laarin oṣu Kinni si oṣu Kejila ọdun 2014.
Ọgagun Braimah ni adari ikọ ọmogun 7 Guard Battalion laarin oṣu Kejila ọdun 2014 si oṣu Kẹwaa ọdun 2015.
Oloogbe Braimah tun ni oludari ọmogun nile ẹkọ ologun ni Jaji, niluu Kaduna laarin ọdun 2015 si 2018.
Braimah di ọga ikọ omogun Operation Hadin Kai ni ẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria lọdun 2019, o si di ipo naa mu titi di ọdun 2021.
O tun jẹ oludamọran lori eto aabo fun olu ileeṣẹ orilẹede Naijiria ni Islamabad laarin oṣu Karun un ọdun 2021 si oṣu Kẹjọ ọdun 2024.
Titi di akoko iku rẹ Ọgagun Braimah ni ọga ikọ ọmogun 29 Task Force Brigade ni Benisheikh.
Awọn Ọgagun tawọn agbesunmọmi ti ṣekupa ni Naijiria laipẹ yii
Ọgagun Braimah ti jẹ ki iye awọn ọgagun tawọn agbesunmọmi ṣekupa ni Naijiria pọ si bayii.
Iwadii fi han wi pe lasiko ikọlu si ibudo awọn ologun lawọn agbesunmọmi yii ṣekupa awọn ọgagun naa.
Iroyin kan jade loṣu Kẹta to kọja eyi to sọ pe ọgagun mẹta lawọn agbesunmọmi Boko haram ati ISWAP sẹkupa laarin ọjọ meje nipinlẹ Borno.
Awọn ọgagun naa ni Maj. U.I. Mairiga to n dari ibudo ologun Mayenti, Ọgagun Lt-Col Umar Faruq to n dari ikọ ọmogun Kukawa ati 101 Brigade ati Ọgagun Lt-Col S.I. Iliyasu to ṣiṣẹ ni Konduga.
Boko Haram Ọgagun pa ọgagun Maj Mariga lọjọ kinni oṣu Kẹta ni Mayenti nijọba ibilẹ Bama.
Awọn agbesunmọmi tun ṣekupa awọn sọja ni Ngoshe nijọba ibilẹ Gwoza lọjọ kẹta oṣu Kẹta nibi ti wọn ti pa ọga agba ologun kan bakan naa.
Ni ọjọ kẹfa oṣu Kẹta ni awọn agbesunmọmi Boko Haram sẹkupa ọga ikọ ọmogun 222 Battalion ni Konduga, Ọga Lt-Col Iliyasu.
Lọjọ kẹsan an oṣu Kẹta lawọn agbesunmọmi tun ya wọ ibudo awọn ologun ni ijọba ibilẹ Kukawa ninu eyi ti wọn ti ṣekupa ọgagun Lt-Col Faruq.
Laipẹ yii ni awọn agbesunmọmi tun ṣekupa ọgagun agba mii nipinlẹ Borno.
Iyalẹnu lo jẹ nigba ti fọnran kan jade eyi to ṣatifihan bawọn agbesunmọmi ṣe mu Ọgagun Brig-Gen Musa Uba.
Oloogbe Uba lo n ṣakoso ikọ ọmogun Damboa ni Wajirko nibi tawọn agbesunmọmi ti ṣekupa a.
Tinubu kẹdun pẹlu ẹbi awọn ọmogun to ku ninu ikọlu to waye ni Borno
Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti kẹdun pẹlu ẹbi awọn ọmogun to ku lasiko ti awọn agbesunmọmi ṣe ikọlu si ibudo wọn nipinlẹ Borno.
Tinubu fi ẹdun ọkan rẹ han ninu atẹjade kan ti oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita lori iku awọn ọmogun naa.
Aarẹ lu awọn ọmogun to ṣubu loju ija naa lọgọ ẹnu fun iwa akinkanju ti wọn hu eyi ti ko jẹ kawọn agbesunmọmi le awọn olugbe agbegbe Benisheikh kuro ni ibugbe wọn.
Nigba to n kẹdun pẹlu ileeṣẹ ologun lori iku ọmogun 29 Task Force Brigade, Operation HADIN KAI, aarẹ rọ awọn adari ileeṣẹ ọmogun wi pe ki wọn ma jẹ ki iṣẹlẹ naa da omi tutu si wọn lọkan lori igbiyanju wọn lati ṣẹgun awọn agbesunmọmi.
''Iroyin t imo n gbọ fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmogun n gbena woju awọn agbesunmọmi, wọn si n ṣẹgun wọn.
Mo kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn sọja wa ti Ọgagun Oseni Omoh Braimah dari wọn ti wọn fi ara wọn ṣe etutu fun orilẹede wa nipinlẹ Borno.
Ijọba ko ni gbagbe ifarajin yin laelae. Nnkan ti ẹ ṣe ko ni jẹ lasan an.
Mo wa n rọ gbogbo ọmogun wi pe ki wọn ma kaarẹ, ẹ tẹsiwaju lati maa gbogun ti awọn agbesunmọmi to n da omi alaafia ru ni Naijiria.
Ijọba yoo maa ṣatẹyin fun yin ni gbogbo igba lẹnu iṣẹ ti ẹ n ṣe fun orilẹede wa.
A tubọ maa pese awọn nnkan ti ẹ ba nilo, a ko si tun ni fi ọrọ igbayegbadun yin lẹnu iṣẹ ṣere rara,'' Tinubu lo sọ bẹẹ.
Aarẹ wa rọ awọn ọmọ Naijiria atawọn oniroyin lati maa ṣatilẹyin fawọn ọmogun Naijiria bi wọn ti n doju ija kọ awọn agbesunmọmi.