You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ pé mo ní àìsàn jẹjẹrẹ inú ìfun, mo rò pé gbogbo ayé mi ti parẹ́ - Tobiloba ẹni ọdún 22
Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ pé mo ní àìsàn jẹjẹrẹ inú ìfun, mo rò pé gbogbo ayé mi ti parẹ́ - Tobiloba ẹni ọdún 22
Ẹni ọdun mejilelogun ni ọdọbinrin Oluwasina Tobilọba ṣugbọn ohun toju rẹ ti ri kọja ọjọ ori rẹ lọ.
Oluwasina Tobilọba ti moribọ lọwọ aisan jẹjẹrẹ inu ifun lẹyin ti iwadi awọn dokita fihan an ni ọdun diẹ sẹyin pe o laisan naa lara.
Gẹgẹbi ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Tobilọba ṣalaye pe oun ro pe ile aye oun ti dorikodo ni nigba ti wọn kọkọ sọ ọ di mimọ fun oun pe oun ti lugbadi aisan naa.
"Ọmọ ọdun mejidinlogun ni mi nigba ti aisan naa kọkọ bẹrẹ si nii farahan lọ."