Ìjọba àpapọ̀ ké gbàjarè lẹ́yìn tí àrùn tó ń gbẹ̀mí màlúù kọlu ìpínlẹ̀ 17

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti ke gbajare pe arun bovine pleuropneumonia (CBPP) to maa n kọlu awọn maluu ti tan de ipinlẹ mẹtadinlogun ni Naijiria.

Nigba to n sọrọ nibi ipade kan ti wọn ti n jiroro lori bi wọn yoo ṣe fopin si arun naa nilu Abuja, minisita fun ohun ọsin, Idi Mukhtar Maiha, ni arun naa le ṣakoba fun ẹka ohun ọsin ni Naijiria amọ wọn le rẹyin rẹ ti ijọba ba tete ṣe ohun to yẹ nipa rẹ.

O fi kun pe lati igba ti arun naa ti wa lode lo ti n ṣakoba fun ọrọ aje ohun ọsin ati pe ti ijọba ko ba tete kapa rẹ, o le pa odidi agbo maluu kan run.

Minisita ọhun ke si gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati bẹrẹ ṣiṣe ohun to yẹ bii fifun awọn ohun ọsin wọn ni abẹrẹ ajẹsara lọna ati kapa arun ọhun.

Nigba to n ba awọn ọmọ igbimọ to n ri si kikapa arun naa sọrọ, Maiha rọ wọn ki wọn ṣe alakalẹ ọna lati fopin si arun naa nitori o le ṣakoba fun ẹka ohun ọsin kaakiri Naijiria.

Arun bovine pleuropneumonia jẹ arun to maa n ṣakọba fun eemi maluu ati ẹfọn.

Awọ onimọ ni kokoro Mycoplasma mycoides lo n ṣokunfa arun ọhun to maa n mu ki ẹranko ni aisan iba, eyii to maa n ge ẹmi wọn kuru ni ida aadọta.

Arun naa maa n tan kalẹ ti wọn ba mi ohun to wa lara ẹranko mii to ba ni arun naa simu, o si jẹ arun to n gbẹmi ọpọ maluu ati ẹfọn nilẹ Afrika.

Lara awọn ọna ti wọn fi n dena rẹ ni fifun awọn ẹranko ni abẹrẹ ajẹsara ki wọn tilẹ to ni irara.

Ọna mii lati gbogun ti arun ọhun ni yiya awọn ẹranko to ni arun ọhun sọtọ kuro lara awọn ti ko tii ni ati didena rinrin kiri awọn ẹranko to ti ni.