Kí ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ Ilẹ riri tó pa ọ̀pọ̀ eeyan to le ni ọgọ́rùn-ún

Agbegbe iwakusa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ṣe lọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna nigba ti ilẹ deedee bẹrẹ sii mi, to si gbe eeyan ti ko din ni ọgọrun min.

Ilu kan ti wọn n pe ni Zamboï lorileede Central African Republic to paala pẹlu Cameroon ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Agbegbe ti wọn ti n wa kusa ni iṣẹlẹ aburu ọhun ti waye, nigba ti wọn sọ pe ojiji ni ilẹ bẹrẹ sii ri mọ awọn eeyan lẹsẹ.

Fọnran kan to n kaakiri ori ayelujara ṣafihan bi ilẹ naa ṣe n ri lọ si isalẹ nibi ti awọn eeyan ti n ṣiṣẹ, ti ọpọ awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn.

Adamou Abdon, to jẹ ologun ni Garoua-Boulaï, ilu to paala pẹlu ilẹ Cameroon sọ fun BBC nipa bi iṣẹlẹ ọhun ṣẹ lọjọ Iṣẹgun.

Loju ẹsẹ ni eto iranwọ lati doola ẹmi awọn eeyan ti bẹrẹ, ṣugbọn ti ọpọ ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ohun to ruju ni bi iṣẹlẹ ọhun ṣe ba awọn eeyan lojiji, nitori ti ko sẹni to le sọ nnkan to fa ilẹ riri naa.

Abdon sọ pe awọn oku mẹtadinlaadọfa ni wọn gbe jade labẹ ilẹ riri naa, lasiko ti wọn n doola ẹmi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn awakusa to wa nibẹ lasiko naa, Cedric Mbango, sọ fawọn akọroyin pe "ilẹ naa ri lojiji, to si ri awọn eeyan mọlẹ.

"Bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii, awọn eeyan ṣi wa labẹ ilẹ ti wọn ko tii ri wọn yọ jade."

Mẹta ninu awọn to kagbako iṣẹlẹ buburu naa ni wọn jẹ ọmọ ilẹ Cameroon, gomina ẹkun Ila-Oorun Cameroon sọ fawọn akọroyin bẹẹ.

Grégoire Mvongo sọ pe pupọ ninu awọn oku naa ni wọn tig be pada lọ sile wọn lati sin, nigba ti igbesẹ n lọ lati rii pe wọn ṣe itọju awọn to farapa ni Zamboï.

Awọn akọroyin sọ pe pupọ ninu awọn to farapa, ti ori si ko yọ ni wọn ko lọ sile iwosan ni Baboua, ilu kan ni CAR to jinna diẹ si agbegbe iwakusa.

A gbọ pe awọn alakoso ati alẹnulọrọ tọrọ naa kan ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa ilẹ riri ojiji ọhun.

Iroyin AFP sọ pe iwakusa Artisanal, ọkan lara awọn ilana ti wọn fi n wa kusa lo n ṣokunfa ilẹ riri lawọn agbegbe kan lẹkun naa.

Wọn ni agbegbe ti wọn ti n ṣiṣẹ ko bojumu, ati pe ọpọ awọn awakusa ni wọn n ṣiṣẹ ninu ewu ilera ati ewu agbegbe.

Bakan naa ni wọn sọ pe iṣẹlẹ ọhun kii ṣe nnkan tuntun nitori pe awọn ilẹ ti wọn ti n wa kusa, ni wọn kii da iyẹpẹ bo pada nigba ti wọn ba ṣiṣẹ tan nibẹ, ati pe ọjọ to n rọ tun maa n ba ilẹ jẹ.