Ṣé ọmọ Naijiria láṣẹ lábẹ́ òfin láti ya fídíò ọlọ́pàá lẹ́nu iṣẹ́?

Oríṣun àwòrán, Newton Isokpehi
Ọlọpaa kan, ASP Newton Isokpehi, ti dero atimọle bayii lẹyin to dunkoko pe oun yo yinbọn pa araalu kankan to ba ya fidio oun lẹnu iṣẹ.
Ṣaaju ni Isokpehi ti kọkọ sọ ninu fidio kan to fa ori ayelujara ya pe oun yoo yinbo pa gbogbo awọn to ba wa ninu ọkọ ti ẹnikẹni ba ti ya oun ni fọto tabi fidio.
Ọrọ naa bi ọpọ araalu ninu to bẹẹ titi to di fi de akata awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn to mu u sinun ahamọ.
Ki ni Newton Isokpehi sọ ni pato?
Ninu fidio to ṣe niwaju ile kan ni afurasi naa ti sọ awọn ọrọ kobakungbe naa.
O ni "Ti mo ba wa lẹnu iṣẹ ti mo si wa pẹlu ibọn lọwọ mi, ti ẹnikẹni ba ya fidio mi, Allah n gbọ, ọga ọlọpaa to ni ẹ le maa ya fidio wa ni yoo lọ sin oku ẹni naa.
"Ti wọn ba bi ẹnikẹni daa, ko ya fidio mi lẹnu iṣẹ… mo maa yinbọ pa ẹni naa ni to fi mọ gbogbo awọn to ba wa ninu bọọsi ti ẹni naa ba wa ni.
"Ojojumọ ni awa ọlọpaa n jiya, (ijọba) ko ṣe nnkankan fun wa, wọn ko ra aṣọ fun wa."
Ọlọpaa naa to ni oun ti lo ọdun mẹrindinlọgbọn lẹnu iṣẹ sọ pe oun ko jere kankan nitori ọpalamba iya loun n jẹ lẹnu iṣẹ naa.
Lẹyin naa lo ṣi apa rẹ to si sọ pe ọta ibọn tib a oun ri, sibẹsibẹ iya n jẹ ọlọpaa.
O fi kun pe "Ẹ wo oju mi daadaa, ẹni ti wọn ba bi daa ko gbe kamẹra lati ya mi lẹnu iṣẹ, wọn maa fi iku ṣe ifa jẹ ni."
Ileeṣẹ ọlọpaa bu ẹnu atẹ lu ọknrin naa, bẹrẹ iwadii

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force
Ẹwẹ, ni kete ti fidio ọhun bẹrẹ si n fa ori ayelujara ya ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fi atẹjade kan lede nibi ti wọn ti bu ẹnu atẹ lu ohun ti ọkunrin naa sọ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni Naijiria, DCP Anthony Okon Placid fi lede, o ni ọga agba ileeṣẹ ọhun, IGP Olatunji Rilwan Disu, ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii lori rẹ ko le jiya to tọ labẹ ofin.
Bakan naa, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Anambra afurasi naa ti n ṣiṣẹ, Ikioye Orutugu ti bu ẹnu atẹ lu u o si ti ni ki wọn fi si ahamọ.
IGP Olatunji Rilwan Disu sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni faye gba idunkoko mọ araalu lati ọwọ ọlọpaa kankan, ọlọpaa to ba si ṣe bẹẹ yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Se araalu lẹtọ labẹ ofin lati ya fidio ọlọpaa lẹnu iṣẹ?
Wayi o, ibere ti ọpọ ọmọ Naijiria n bere bayii ni pe ṣe awọn lẹ ya lati ya fidio ọlọpaa lẹnu iṣẹ.
Ninu atẹjade ọọfisi ọga ọlọpaa Naijiria, IGP Olatunji Rilwan Disu, o ni araalu laṣẹ lati ṣe bẹẹ.
Atẹjade ọhun sọ pe "Ọga agba ọlọpaa, IGP Olatunji Rilwan Disu ti maa n sọ tipẹtipẹ pe araalu lẹtọọ lati ya fidio ọlọpaa lẹnu iṣẹ wọn lọna to ba ofin mu, niwọn igba ti irufẹ fidio bẹẹ ko ba di iṣẹ ọlọpaa lọwọ tabi ko ṣakoba fun eto aabo irufẹ ọlọpaa bẹẹ tabi ko da iṣẹ ti wọn n ṣe duro."
Lati kin ọrọ yii lẹyin, agbẹjọro kan, Confidence Aribibia sọ pe "Kii ṣe ẹṣẹ labẹ ofin lati ya fidio ọlọpaa lẹnu iṣẹ rẹ.
"Oṣiṣẹ ilu ni ọlọpaa, iṣẹ ilu lo si n ṣe, fun idi eyii, agbara ofin ko din ku nitori pe eeyan kan yọ kamẹra jade lati ya ọlọpaa naa.
"Bẹẹ ni ọlọpaa ko lẹtọ lati gba foonu araalu tabi ko sọ fun araalu pe ko yọ fidio naa kuro loru foonu rẹ nitori pe o n ya oun lẹnu iṣẹ."

























