Wọ́n ti sin òkú olùkọ́ táwọn agbébọn pa lásìkò tí wọ́n ṣèkọlú síléẹ̀kọ́ girama Esinele l'Ogbomoso

Oloogbe Joel Adesiyan wọ aṣọ alapa penpe olomi buluu ati posi rẹ funfun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ eeyan lọ peju sibi isinku Joel Adesiyan, ọkan lara awọn olukọ to padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu awọn agbebon to waye ni ile ẹkọ girama to wa ni Ahoro Esinele ati nile ẹkọ Alakọbẹrẹ Yawota labẹ ijọba ibilẹ Oriire niluu Ogbomoso nipinlẹ Oyo lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.

‎Isin ikẹyin naa lọ waye ninu ile ijọsin onitẹbomi Ayegun niluu Ogbomosho.

‎Awọn agbebọn naa yinbọn pa Ọgbẹni Adesiyan ẹni to jẹ olukọni ni ile ẹkọ to wa ni Ẹsinẹlẹ lasiko ikọlu naa.

‎Ninu ọrọ rẹ, aṣoju gomina Ipinlẹ Oyo Michael Ojelabi ẹni ti o jẹ ọga agba fáwọn olukọ ni agbegbe Ogbomoso, kẹdun pẹlu awọn mọlebi oloogbe.

Ojelabi ṣalaye wi pe iku Adesiyan ba ijọba Ipinlẹ Oyo ninu jẹ.

O ni ijọba yoo ko ipa rẹ lati ri wi pe awọn olukọ ati akẹkọọ to wa ni igbekun gba itusilẹ.

‎Oniwaasu ijọ onitẹbomi Ayegun, Ẹniọwọ Paul Olaleye ninu iwaasu rẹ ṣalaye wi pe, gbogbo eeyan ni yoo wọ agbada iku lọjọ kan, o si ka ninu iwe Jobu ori kẹrinla ẹsẹ kẹrinla.

‎Olaleye rọ gbogbo awọn to ṣoju ijọba Ipinlẹ Oyo lati ri wi pe eto oloogbe naa tẹ awọn ẹbi rẹ lọwọ ni kiakia.

‎Oniwaasu naa rọ gbo awọn to wa nibi isin ọhun lati fi Ọlọrun siwaju, ki wọn si ranti atunbotan, nitori pe gbogbo awọn to n huwa ika ni yoo ko ere ika.

‎''Gbogbo ẹtọ oloogbe lawọn ẹbi rẹ yoo ri gba''

‎Ninu ọrọ rẹ, Hassan Ajibola ẹni ti o jẹ alaga fun awọn olukọ nipinlẹ Oyo koro oju si bi ko ti si aabọ to daju fun awọn olukọ papaa julọ awọn to wa ni igberiko.

‎Hassan ninu ọrọ ikẹdun rẹ gbadura wi pe gbogbo awọn agbebon to lọwọ si iku Ọgbeni Adesiyan ni yoo jẹ iya fun iwa ika wọn.

‎Hassan ni "labẹ eto ẹgbẹ awa olukoni a ni eto kan ti an pe ni" End well" mo si nigbagbo wi pe alaisi yii naa jẹ ẹnikan to kopa ninu rẹ.

Gbogbo àwọn ti iru iṣẹlẹ bayii ba sẹlẹ si lo maa n gba owo wọn ni kíákíá".

''Ogo ile wa ti lọ''

Ẹgbon oloogbe naa ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin ṣalaye wi pe ogo idile awọn lo wọ omi.

O ni oloogbe jẹ arole ninu ile baba rẹ ati Iya rẹ.

‎Sangotoye Olaolu ni nigba ti Isẹlẹ naa sẹlẹ ijọba tete gbe igbesẹ bo tile jẹ wi pe ẹpa o boro ma.

Ọgbẹni Olaolu wa ro ijọba lati pese aabọ fun gbogbo ọmọ orile-ede Naijiria.

Olaolu sọ pe "o bani ninu jẹ, o jẹ ikoro ọkan wi pe ko ni ọmọ laye gbogbo awọn ọmọ tẹ ri yẹn o gba wọn tọ ni.

‎Joel ko mọlẹbi mọra, baba to bi Joel ati iya to bi mi ọmọ iya ni wọn, ko si ẹni ti ko fẹran rẹ ninu gbogbo molebi.''

Òní ni ìsìnkú olùkọ́ tí àwọn agbébọn pa lásìkò tí wọ́n kọlú iléẹ̀kọ́ méjì ní ìpínlẹ̀ Oyo

Aworan patako ile ẹkọ girama naa ati olukọ ọhun.

Oni ni eto isinku olukọni ti awọn agbebọn pa lasiko ti wọn kọlu ileẹkọ meji kan ni agbegbe Ahoro-Esinele ati Yawọta ni ọjọ Ẹti ọjọ karundinlogun oṣu karun un.

Awọn agbebọn naa yinbọn pa Ọgbẹni Joel Adesiyan ẹni to jẹ olukọni ni ile ẹkọ girama Community High School Ẹsinẹlẹ lasiko ikọlu naa.

Eto isinku olukọ ti wọn ṣekupa naa yoo waye ni ijọ onitẹbọmi Ayegun Baptist Church ni ilu Ogbomoṣọ

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn agbebọn ti kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko ti i le fi iye wọn mulẹ lọ nibi ikọlu naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti naa, o ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ yii ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ.

Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de bo ṣe wi.

Bi wọn ṣe de ni wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.

Ninu ikọlu naa ni wọn ti yinbọn fun olukọ kan, ẹni ti iroyin sọ pe o ti jade laye, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ.

"Awọn agbebọn ti wọ agbegbe Ahoro-Esinele, nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo. Wọn gbe ọga ile ẹkọ ati awọn akẹkọọ ti a ko mọ iye won lọ"

Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa wi.