Wo bí o ṣe le darapọ̀ mọ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Ìrù Ẹkùn tí Sunday Igboho dá sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, bí Tinubu ṣe fòǹtẹ̀ lù ú

Sunday Igboho ati awọn ẹsọ Iru Ekun ti wọn wọ asọ ologun

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu ẹṣọ eleto aabo Iru Ẹkun toun da silẹ.

Igboho sọ ninu fidio kan to fi lede lori itakun ayelujara wi pe lẹyin toun gbe ẹṣọ eleto aabo Iru Ẹkun de iwaju Tinubu ni aarẹ tẹwọ gba a.

Oloye Igboho wa kepe gbogbo ọmọ Yoruba to jẹ Akinkanju lati darapọ mọ ẹṣọ Iru Ẹkun lati le jọ ṣiṣẹ pọ wa ojutuu si iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan to n pọ si i lawọn ipinlẹ Yoruba bayii.

Oloye Sunday Igboho wọ aṣọ buba buluu

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram

"Wọn fẹ da ijọba Tinubu laamu, ki awọn eeyan le maa sọ pe ilu o fararọ, to fi de ilẹ Yoruba gan an ti aarẹ ti wa"

''A ko gbọdọ faye gbawọn janduku agbebọn ti wọn ti bẹrẹ sii ṣọṣẹ lawọn ipinlẹ wa bayii.

Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan ti wọn ṣe gan an niyi lasiko ti Aarẹ Goodluck Jonathan wa lori oye.

Nigba yẹn ni wọn lọ ko awọn Boko Haram jade lati maa da ijọba Jonathan laamu.

Nnkan ti wọn si fẹ ṣe lasiko yii ni pe wọn fẹ da ijọba Tinubu laamu, ki awọn eeyan le maa sọ pe ilu o fararọ to fi de ilẹ Yoruba gan an ti aarẹ ti wa.

Awa la o nii gba fun wọn lati da ijọba Tinubu ru, tori ọmọ ẹni ko ni ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹkẹ si idi ọmọ ẹlomiran,'' Igboho lo sọ bẹẹ.

Owo Baba Dami ni ilẹ Yoruba ko gbọdọ faye gba awọn oloṣelu ti wọn ko awọn janduku agbebọn sabẹ.

Ajigbara fun idasilẹ Yoruba Nation sọ pe agbesunmọmi ni ẹnikẹni to ba n pa eeyan to si tun n ji eeyan gbe pawo.

Igboho ni o ṣee ṣe ko ma jẹ pe awọn Fulani nikan lo n ṣiṣẹ laabi yii.

Oloye Adeyemo sọ pe ọdaran ni ẹnikẹni ti oun atawọn ẹṣọ Iru Ẹkun ba le ba ninu igbo ọba nilẹ Yoruba.

Sunday Igboho ni ko si nnkan kan to le mu ki eeyan maa gbe ninu igbo, o ni igboro lo yẹ ki gbogbo eeyan maa gbe gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.

Ẹnikẹni to ba fẹ darapọ mọ Iru Ẹkun ko ni lati sanwo fọọmu kankan - Igboho

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Owo Baba Dami ni awọn oloṣelu kan lo wa nidii awọn janduku to n ji awọn eeyan gbe pawo ni Naijiria.

O wa rọ gbogbo awọn ọmọ Yoruba wi pe ki wọn ma jẹ kawọn janduku agbebọn ba ilẹ Yoruba jẹ.

''Ko si giri kankan, ọrọ to wa nilẹ yii kii ṣe ọrọ ija ẹsin tori onigbagbọ lemi naa.

Iyawo mi keji ti lọ si Mecca tori musulumi ni, o si maa n kirun ninu ile.

Mi o dẹ binu si i nitori pe emi gan an maa n lọ si ṣọọṣi, awọn oniṣẹṣe si lawọn obi mi.

Ki ni a wa fẹ maa bara wa ja fun? Kii ṣe ọrọ ẹsin, ẹ jẹ ka gbe ọrọ ẹsin si ẹgbẹ kan.

Ẹ jẹ ka doju kọ awọn janduku ti wọn n ji awọn ọmọ wa gbe lọ.

Ẹnikẹni to ba fẹ darapọ mọ Iru Ẹkun ko ni lati sanwo fọọmu kankan.

A maa fi nọmba foonu awọn alakoso Iru Ẹkun ni ipinlẹ kọọkan lede fun ẹnikẹni to ba fẹ darapọ mọ wa lati pe.

Ijọba naa maa ṣe atilẹyin fun wa ti a ba ti n ba iṣẹ lọ, tori ọmọ to ba ṣi apa ni baba maa n gbe.

Awa ni a ni nnkan wa, ọmọ oniluu ti ko ni fẹ ki ilu rẹ tu ni wa, ẹ jẹ ka jọ fọwọ sowọ pọ,'' Oloye Adeyemo ṣalaye.

Igboho ni awọn oloṣelu to wa nidii ọrọ awọn janduku ajinigbe yii fẹ ba ijọba Tinubu jẹ ni.

Owo Baba Dami ni ilẹ Yoruba ko ni gba kawọn oloṣelu kan ba ijọba Aarẹ Tinubu jẹ.