Mo lè má sí láyé láti kópa nínú ètò ìdìbò ọdún 2027 – Obi

Aworan Pter Obi to fi owo mu igo loju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Peter Obi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Oludije sipo aarẹ ilẹ Naijiria, Peter Obi ti sọ pe o ṣee ṣe ki oun ma si laye mọ ṣaaju eto idibo apapọ ọdun 2027, pẹlu bo ṣe sọ pe awọn kan n dunkooko mọ ẹmi oun.

Peter Obi lo sọrọ ninu ifọrọwerọ to ṣe laipẹ yii lori ikanni ayelujara, nibi to ti ṣalaye nipa awọn adojukọ rẹ lori ipinnu lati du ipo aarẹ.

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra sọ pe ọpọ awọn ẹtọ oun ni ijọba ilẹ Naijiria fi n dunkooko mọ oun, ati pe gbogbo awọn to duro gẹgẹ bi alatako ijọba ni wọn n dojukọ idunkooko loriṣiriṣi.

Oludije naa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe oun ko lẹbọ lẹru ṣaaju, lasiko ati lẹyin toun wa ni ipo gomina ipinlẹ Anambra, to si loun yoo wa gbogbo ọna lati jẹ ki ifẹ, alaafia ati iṣọkan jọba nilẹ Naijiria, iyẹn boun ba ni anfaani lati wa ni ipo aarẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Obi sọ pe "Mo maa duro lori awọn ọrọ mi. Laaarin ọdun mẹrin, mo gbọdọ ti ṣe ninu awọn ileri mi. Koda bi nko ba tiẹ ni pada du ipo naa lẹẹkeji, mo maa mu ileri mi ṣe. Nigba ti mo n lọ si Anambra, mo sọ awọn ohun ti mo fẹẹ ṣe, mo si fi n daa yin loju pe mo mu wọn ṣẹ.

"Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, mo le ma jẹ ọmọ oye fun ipo aarẹ nikan, mo tiẹ tun le ma si nile aye mọ. Mo n sọ eyi fun un yin nipa aridaju. Gbogbo ohun ti mo n ṣe lati gbe ile aye ni ijọba yii n dunkooko mọ.

"O ṣee ṣe, to jẹ pe bi wọn ba ri anfaani naa, mo le ma si laye mọ. Eleyii kii ṣe ifẹsunkan, ojoojumọ ni wọn n dunkooko mọ mi, nitori pe mo n ṣe awọn nnkan ti mo lero wi pe o dara.

"Wọn ko nii wa lati sọ pe awọn lawọn n ṣe nnkan bayii, ṣugbọn ẹ maa rii firifiri wi pe awọn ni wọn wa nidi rẹ ninu awọn irin ajo. Gbogbo awọn to duro gẹgẹ bii alatako ni wọn n dunkooko mọ."

Wọn ti ṣe ikọlu ojukoju si mi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oludije naa tun fi kun ọrọ rẹ pe "Emi gẹgẹ bi ẹnikan, wọn n ṣe ikọlu si mi. Gbogbo awọn nnkan to yẹ ki n lẹtọọ si gẹgẹ bi iru eeyan ti mo jẹ ni wọn fi n doju kọ mi, niṣe ni mo tun n lakaka lati rii lojoojumọ. Mo ni adojukọ kekere kan laipẹ yii ni papakọ ofurufu. Awọn alakoso papakọ ofurufu wa lati tilẹkun ọkọ ayọkẹlẹ mi. Mo sọ fun wọn pe emi ma nii, ṣugbọn wọn sọ fun mi pe ko si eyi to kan awọn nipa iru eeyan ti mo jẹ.

"A ti pin orileede yii pẹlu ibinu sira ẹni. Idi ree ti mo fi n sọ pe mo fẹẹ mu iṣọkan pada wa, nibi ti iyapa wa. Mo fẹẹ mu ifẹ ati itara ifẹ ara ẹni pada wa fun wa. Wọn tilẹkun ọkọ mi mọ mi, ti awọn ọkọ miran si wa nibẹ. Mo wa n ri awọn ti mo ti mọ tẹlẹ, ti wọn ko nii ki mi. Wọn a maa bẹru wi pe ki nnkan ma ṣẹlẹ si wọn.

"Awọn kan tun wa fun mi ni iwe ipe sibi ayẹyẹ ọjọ ibi wọn, ṣugbọn wọn maa tun bẹ mi wi pe nko gbọdọ wa sibẹ. A ko le maa gbe bayii lọ. Awọn eeyan a tun maa ṣe ikilọ fun mi pe ki n ṣọra mi.

"Mo ti sọ fun iyawo mi ati awọn ọmọ mi, wi pe ohunkohun ti yoo ba a ṣẹlẹ si mi, amuwa Ọlọrun ni, ki wọn gba kamu," Obi sọ bẹẹ.

Ojú àánú ni Peter Obi n wá - Ìjọba àpapọ̀

Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu

Ijọba apapọ ilẹ Naijiria ti wa sọ pe ki ẹni kẹni ma ṣe gba awọn ọrọ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu National Democratic Congress, NDC, Peter Obi gbọ, nitori pe oju aanu awọn araalu lo n wa.

Oludamọnran pataki si aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi soju opo ayelujara 'X' rẹ, to si ṣalaye pe awawi lasan ni Obi n sọ.

Atẹjade ọhun ti Onanuga fi sita l'Ọjọru, ọsẹ yii lo ti sọ pe agbelẹrọ lasan ni awọn ẹsun ti Obi sọ sita, ati pe ọkan lara awọn abala iwe irọ ati iroyin ẹlẹjẹ to kọ, lo sọ naa.

Onanuga sọ pe "Awọn ọrọ ti Obi sọ yii, agbelẹrọ lasan ni, oju iwe kan ninu iwe irọ ati iroyin ẹlẹjẹ to gbe kalẹ ni".

O ni gomina naa n wa ọna lati ṣi oju awọn eeyan kuro ninu awọn iṣoro to n dojukọ ẹgbẹ oṣelu NDC to ti fẹẹ du ipo ni igbesẹ ọhun jẹ.

"Ọrọ wi pe oun le ma si laye mọ fun eto idibo ọdun 2027, ati pe idunkooko fun awọn eeyan lati ma ṣe pe e si ode ariya mọ, ko si ohun meji rẹ ju ọrọ agbelẹrọ lọ, abala kan ninu iwe irọ ati iroyin ẹlẹjẹ to kọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Awọn ẹsun yii ko lẹsẹ nilẹ, bẹẹ ni ko fidi mulẹ, ati pe agbekalẹ lati wa oju aanu lasan ni, bẹẹ si lo tun jẹ ọna agbekalẹ lati fi tan awọn araalu, ati awọn iṣoro to n doju kọ ẹgbẹ oṣelu NDC to ṣẹṣẹ darapọ mọ.

"O ṣe pataki lati mọ pe Peter Obi nifẹ si awọn ele nile ifowopamọ Fidelity. Banki naa si n ṣe aṣeyọri nitori bi eto ọrọ aje orileede yii ṣe n ni idagbasoke, labẹ agbekalẹ atunto.

"Ijọba ko doju kọ ile ifowopamọ naa. Kaka ki ijọba maa dọdẹ rẹ kaakiri, awọn ọrọ agbelẹrọ ti Ọgbẹni Obi n gbe kaakiri lo n le kiri."

O wa sọ pe Tinubu ko raaye ohun miran gẹgẹ bi ẹsun ti Obi n gbe kaakiri, to kọja afojusun lori atunto.

Ohunkóhun kò gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí Obi o - Atiku

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Abubakar Atiku

Ju gbogbo rẹ lọ, oludije sipo aarẹ ilẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), Atiku Abubakar ti wa ṣe ikilọ pe ohunkohun ko gbọdọ ṣẹlẹ si Peter Obi, ṣaaju ati lẹyin eto idibo apapọ ọdun 2027.

Atiku sọ pe ijọba apapọ ni lati fi aridaju sita pe ko sohun ti yoo ṣẹlẹ si Atiku toun naa n gbero lati jade du ipo aarẹ.

Bakan naa lo tun rọ ijọba apapọ lati tu gomina tẹlẹri nipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai, lati tu silẹ kuro lahaamọ to wa.

O ni ijọba lati wa atunṣe ti yoo fidi rẹ mulẹ pe ko s'ohun to dunkooko mọ awọn alatako, paapaa nigba ti wọn ba n ṣe idunkooko si wọn, to si lo lodi si eto oṣelu awa-ara-wa.

Atiku sọ siwaju ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Phrank Shaibu, eto aabo awọn aṣiwaju alatako jẹ ojuṣe ijọba apapọ.

"Ohunkohun ko gbọdọ ṣẹlẹ si Peter Obi. Ohun to ba de ba imu, o ti de ba gbogbo ara ni. Nigba ti wọn ba n dunkooko mọ olori alatako kan, gbogbo ohun alatako ni wọn ti n dunkooko mọ," Attiku sọ bẹẹ.

"Nigba ti awọn araalu ba n bẹru nitori igbagbọ nipa oṣelu, oṣelu awa-ara-wa funra rẹ ti si olufarapa."