Amẹ́ríkà àti Iran tún ju àdó olóró síra, èèyàn mẹ́rìnlá jáde láye

Oríṣun àwòrán, Instagram
Orilẹ ede Amẹrika ati Iran ti n tẹsiwaju lori ikọlu ti orilẹ ede mejeeji n ṣe si ara wọn bawọn oluwoye ṣe ni adinku ti ba iye ọkọ oju omi to n gba Strait of Hormuz kọja.
Amẹrika ni awọn ṣe ikọlu si ibudo awọn oloogun Iran to jẹ aadọrun-un. Iran sọ pe eeyan mẹrinla ni Amẹrika ti pa lẹnu ikọlu ọjọ meji naa.
Ileeṣẹ iroyin abẹle Iran sọ pe awọn ileeṣẹ ohun amuṣagbara Bushehr wa lara awọn ibi ti ikọlu naa ba.
Amẹrika ko i tii sọ ohunkohun lori ikọlu tuntun naa.
Iran ni awọn n foju sun awọn ohun ini Amẹrika to wa ni Kuwait, Bahrain ati Qatar lati fesi sawọn ikọlu naa.
Iran ṣekọlu sawọn ibudo Amẹrika ni Kuwait, Jordan ati Iraq ni ọjọbọ gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin abẹle ṣe sọ.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Iran bu ẹnu atẹ lu ikọlu tuntun ti Amẹrika ṣe si Iran yii bi wọn ṣe juwe rẹ gẹgẹ bi iwa ọdaran nla, ti wọn si juwe iṣejọba Trump bi eyi to kun fun iwa ibi.
Ileeṣẹ naa ni awọn afara ati oju ọna reluwe ti wọn maa gba lati Tehran lọ si ilu Mashhad nibi tie to isinku olori orilẹ ede naa tẹlẹ ri Ayatollah Ali Khamenei ti n waye ni Amẹrika ti ṣe ikọlu si, ti wọn si ti bajẹ.
Ileeṣẹ eto ilera Amẹrika ni eeyan mẹrinla ni wọn ṣekupa ninu ikọlu tuntun yii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Hossein Kermanpour sọ pe Amẹrika ṣekọlu si ẹkun marun-un ni Iran laaarin ọjọ Kẹjọ ati ọjọ Kẹsan-an, oṣu Keje, nibi ti eeyan mejidinlọgọrin ti farapa, ti awọn mẹtadinlaaadọta ṣi wa nile iwosan.
Awọn orilẹ ede to wa ni ekun Gulf sọ pe Iran naa bẹrẹ si ni ju ado oloro sawọn leyin ikọlu Amẹrika bi ado oloro ṣe balẹ ni Manama, Bahrain, Kuwait, ti Qatar si n ṣekilọ nipa aabo.
Ileeṣẹ Ologun Iran, Islamic Revolutionary Guard Corps (IRGC) fidi rẹ mulẹ pe awọn ju ado oloro si ibudo awọn Ologun Amẹrika to wa ni Kuwait ati Bahrain, ti wọn si ni ipele akọkọ niyẹn si fifesi si ikọlu Amẹrika.
Olori ile aṣofin Iran, Mohammad Bagher Ghalibaf, to tun jẹ ẹni to n ba Amẹrika jiroro lati pana ogun kọ soju opo X rẹ pe Amẹrika ko i kẹkọọ pe idunkoko mọ ni ati yiyẹ adehun ko ni lọ lasan.
"Ẹ jẹ ki n sọ ọ pe bi ẹ ba ṣekọlu si wa, a maa da pada."
O fi kun pe idunkoko Amẹrika kọ lo maa mu awon ṣi Strait of Hormuz bikoṣẹ ipinnu Iran.



























