Ìjọba bu ẹnu àtẹ́ lu pípa àwọn ọmọ Nàìjíríà méjì ní South Africa bí ìjọba South Africa ṣe kéde ṣíṣe àtìlẹyìn fáwọn tí okoòwò wọn bá ìwọ́de lọ

Awọn ọmọ Naijiria to ṣẹṣẹ de lati South Africa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu iṣekupani to waye ni orilẹ ede South Africa nibi ti eeyan meji ti padanu emi wọn.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si eto irinna silẹ okeere, Imomotimi Ebienfa fi lede lọjọ Karun-un, oṣu Keje sọ pe awọn eeyan to padanu ẹmi wọn naa ni Emeka Charles Ibegbeu ati Nnaemeka Mathew Andrew Ekepynong.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe fẹsun kan, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa ni awọn ọlọpaa Metro sẹkupa Emeka ni agbegbe Sunnyside, Pretoria.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan pe awọn ọlọpaa kan naa lo tun ṣekupa Nnaemeka Matthew Andrew Ekepynong ni ogunjọ, oṣu Kẹrin.

Ijọba South Africa ko i tii sọ ohunkohun lori ẹsun naa.

Ijọba Naijiria sọ pe iku awọn eeyan naa n kọ wọn lominu ati pe o waye lasiko tawọn ara South Africa n gbogunti awọn ajoji ni orilẹ ede wọn.

Ẹlomiran to tun padanu ẹmi rẹ ni Musa Yanua Joe ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Big Joe.

Atẹjade naa ni iwaju ṣọọbu Big Joe ni won pa a si lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹfa ni Witbank Mpumalanga.

Ijọba Naijiria ni o je ohun to banilọkanjẹ pe ọwọ ko i tii tẹ awọn to huwa ibi naa.

Wọn ni ipaniyan naa farajọ pe awọn kan mọọmọ ṣekọlu sawọn eeyan to n ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai lodi si ofin.

Ijọba Naijiria ni ti ikọlu bayii ba n tẹsiwaju, o tumọ si pe awọn ọlọpaa Tshwane Metro Police naa lọwọ ninu ikọlu naa.

'A n pe fun iwadii lori iku awọ eeyan wa'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijọba Naijiria ni ohun ti ko dara ni ki wọn maa naka aleebu sawọn ajoji lori ohun to yẹ ko jẹ pe ijọba orilẹ ede wọn lo yẹ ko mojuto o.

Nnkan mii ti ijọba Naijiria n binu si ni ọrọ ti agbẹnusọ ijọba orilẹ ede South Africa sọ lori amohunmaworan bo ṣe n bi awọn ọmọ Naijiria to n kuro ni orilẹ ede naa pe nib oni wọn ko awọn oogun oloro ti wọn ko wọle lọna aitọ si.

Ijọba Naijiria ni ọrọ naa ko yẹ lẹnu awọn to wa nipo aṣẹ, ti awọn ko si ni gba iru rẹ laye rara.

Awọn alaṣẹ ni Naijiria n pe fun iwadii to jinlẹ lori awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti ṣekupa ni South Africa.

Wọn ni eyi pọn dandan lati jẹ ki awọn to huwa ọdaran naa foju wina ofin ati pe awọn maa gbe igbesẹ ti ijọba South Africa ko bag be igbesẹ to yẹ.

Bakan naa ni wọn parọwa sawọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa lati maa tẹle ofin, ki wọn jina sawọn agbegbe ti iwọde tako awọn ajoji ti n waye bi ijiroro laaarin orilẹ ede mejeeji ṣe n tẹsiwaju.

Wọn ni awọn maa tẹsiwaju lati ko awọn araalu to ṣi w ani South Africa pada sile lẹyin tawọn to le ni ẹẹgbẹrin ti de si Naijiria bayii.

A maa satilẹyin fawọn ti okoowo wọn ba iwọde lọ - Ijọba South Africa

Ijọba orilẹ ede South Africa ti sọ pe awọn ọlọja ati olokoowo ti iwọde tako awọn ajoji to n waye ni orilẹ ede naa n ṣakoba fun ni awọn maa ṣatilẹyin fun.

Wọn ni ki awọn eeyan naa lọ yọju si ileeṣẹ to n ri si okoowo lati lọ forukọ wọn silẹ.

Atẹjade kan ti orilẹ ede naa fi sori ikanni X wọn lọjọ Aiku ni wọn kede igbesẹ naa.

Ikede yii lo n waye lẹyin ti Minisita kan, Khumbudzo Ntshavheni ti ṣaaju sọ pe awọn ko ni fun ẹni to ba wọ orilẹ ede naa lọna aitọ ni ohun ini wọn ti wọn ba bajẹ pada.

Ntshavheni sọ eyi lẹyin ti ijoba Naijiria sọ pe awọn maa beere fun ẹbun gba mabinu fun awọn eeyan to fi gbogbo ohun ini wọn kalẹ lati sa asala fun ẹmi wọn.

Amọ ijọba orilẹ ede naa ti wa sọ pe awọn ṣetanlati ṣatileyin fawọn to padanu ohun ini wọn.

Ebienfa sọ fun BBC lọjọru to kọja pe ijọba orilẹ ede mejeeji ti n jiroro lori igbesẹ naa.