Ẹ má ṣe kọ̀ láti gba ọgọ́rùn-ún kan náírà, ìjìyà wà fún ẹni tó bá kọ̀ ọ́ – Báǹkì àpapọ̀ Naijiria kìlọ̀ fùn aráàlú

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Banki apapọ nilẹ Naijiria, CBN ti sọ pe o pọn dandan fun gbogbo araalu, olokoowo ati awọn ile ifowopamọ kaakiri orileede naa lati maa na ọgọrun kan naira.
CBN sọ pe ki gbogbo awọn to n kọ lati maa gba owo ọgọrun kan naira naa dẹkun iwa naa bayii, nitori pe owo ọhun ṣi n jẹ itẹwọgba labẹ aṣẹ, akoso ati ofin ilẹ Naijiria.
Ni afikun oro naa, CBN so pe ijiya wa fun enikeni to ba ko lati gba owo naa bii owo Naijiria
Banki agba naa lo sọrọ yii lẹyin oniruuru iroyin to ti n kaakiri igboro pe awọn araalu kan ti bẹrẹ sii kọ ọgọrun kan naira ọhun.
CBN so pe eyi ku diẹ kaato, nitori pe awuyewuye ti ko lẹsẹ nilẹ ni wọn n gbe kaakiri ilu wi pe owo naa ko nii pẹ ẹ d'ohun igbagbe.
Nigba ti awọn alakoso n fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade ti Arabinrin Hakama Sidi-Ali to jẹ alakoso agba nileeṣẹ agbẹnusọ CBN, o ni ki ẹnikẹni ma ṣe sọ pe oun ko nii gba owo naa mọ rara.
Hakama Sidi pe, "Akiyesi banki agba ilẹ Naijiria ti lọ si oniruuru iroyin bi awọn eeyan ṣe n kọ owo ọgọrun kan naira, nipa iṣiyemeji lori nina owo ọhun."
Sidi-Ali ṣalaye pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n ko ọkan soke lori ọgọrun kan naira ti awọn gbe jade lọdun diẹ sẹyin, lati fi ṣajọyọ idasilẹ ọgọrun ọdun ti wọn ti da ilẹ Naijiria silẹ.
O sọ pe ọgọrun naira tuntun naa ko sọ pe awọn yoo ko eyi to ti wa nita tẹlẹ kuro nilẹ, bi ko ṣe pe wọn yoo maa na gbogbo rẹ papọ ni.
"Fun awọn to n ṣiyemeji, CBN n fi asiko yii sọ fun gbogbo yin wi pe ọgọrun kan naira atijọ, ati ọgọrun kan naira tuntun lo ṣi n jẹ itẹwọgba nilẹ Naijiria, ati pe gbogbo eeyan lo gbọdọ maa gba a ni gbogbo igba kaakiri ilẹ yii.
"Ọgọrun kan naira tuntun ti a fi sọri idasilẹ ọgọrun ọdun ilẹ Naijiria ko rọpo ọgọrun kan naira ti a ti n na ṣaaju, mejeeji lo n jẹ itẹwọgba papọ,"
Ijiya wa fun ẹnikẹni to ba kọ owo yii
Yatọ si eyi, ile ifowopamọ agba naa tun sọ siwaju pe ijiya fun ẹnikẹni to ba gbiyanju lati kọ owo naa, nitori pe o ṣi wa labẹ ofin lati maa na ọgọrun kan naira.
Sidi-Ali ṣekilọ pe, "CBN ṣe ikilọ nla fun ẹnikẹni, okoowo, ileeṣẹ eto iṣuna tabi ajọ to ba kọ ọgọrun kan naira. Iru ikọsilẹ bẹẹ lo tako ofin ati ilana ofin CBN ninu owo ilẹ wa."
Banki agba naa fi kun ọrọ wọn pe awọn yoo bẹrẹ sii fi ọwọ ṣikun ofin mu gbogbo ẹnikẹni, aṣoju, ile itaja tabi ile ifowopamọ to ba kọ lati gba owo ọhun.
"CBN ko nii kọ lati bẹrẹ sii lo ọwọ ofin lori gbogbo ẹnikẹni tabi ileeṣẹ yoowu to ba n tapa si ilana ati ofin gbigba owo yii," atẹjade naa sọ siwaju.



























