Wo àwọn òṣèré tíátà Yoruba méje tó jáde láyé lọ́dún 2026

Awọn oṣere to ti jade laye
    • Author, Olumide Owaduge
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Leyin iku gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Taiwo Hassan Ogogo, ọpọ ọmọ Naijiria lo ba agboole tiata kẹdun ni Naijiria.

Amọ ṣa, kii ṣe Ogogo nikan ni oṣere tiata Yoruba to ti papoda ninu ọdun yii.

Lapapọ, iye awọn oṣere tiata Yoruba ti wọn ti jade laye ti le ni meje bayii.

Lara nnkan to gbẹmi awọn oṣere naa ni aisan, ijamba ọkọ, ati bẹẹ lọ.

Iwọnyii ni awọn oṣere tiata to ti jade laye ninu ọdun 2026 yii.

Ajara Lasisi – Oṣu Keji ọdun 2026

Aunty Ajara nigba aye rẹ

Oríṣun àwòrán, Aunty Ajara

Ajara Lasisi, ti ọpọ eeyan mọ si Aunty Ajara lo jade laye lọjọ Karun un, oṣu Keji, ọdun 2026.

A gbọ pe Aunty Ajara ku lẹyin to ti kọkọ ba aisan kan finra, iroyin iku rẹ si da ibanujẹ sọkan awọn oṣere tiata nitori ifẹ ti ọpọ eeyan ni si.

Fesogboye Oyewole – Oṣu Karun un ọdun 2026

Agbaọjẹ ni Fesogboye Oyewole nidi iṣẹ tiata Yoruba ni Naijiria ṣaaju iku rẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2026 yii.

Titi di asiko yii, awọn mọlẹbi rẹ ko kede ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Amọ ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ lo ṣe elede lẹyin rẹ lẹyin to dagbere faye.

Okiki Adeshina 'Janmole' – Oṣu Kẹfa ọdun 2026

Ijamba ọkọ lo mu ẹmi Okiki Adeshina 'Janmole' lọ laito ọjọ.

Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Mr Latin lo kede iku Okiki Adeshina 'Janmole' lasiko to sọ pe ọgbẹ to ni lasiko ijamba to wa ninu rẹ lo gbẹmi rẹ.

Janmole wa lara awọn oṣere to ṣẹṣẹ n goke agba ki ọlọjọ to de.

Kola Oyewo – Oṣu Kẹfa, ọdun 2026

Odu ni Kola Oyewo, kii ṣe aimọ fun oloko lagbo tiata ni Naijiria ati loke okun.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii Kola Oyewo dagbere faye.

Nigba aye rẹ, Oyewo jẹ ọkan gboogi lara awọn agba oṣere ti awọn eeyan n bu ọla fu julọ.

Yatọ si pe o jẹ oṣere, o tun ti fi akoko igba kan ri jẹ olukọ ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Ile Ife, OAU.

Bo tilẹ jẹ pe mọlẹbi rẹ ko sọ ni pato ohun to gbẹmi rẹ, a mọ pe o n ba aisan finra ṣaaju ki ọlọjọ to de.

Taiwo Adeshina 'Elegbeje Ado' – Oṣu Kẹfa, ọdun 2026

Elegbeje Ado nigba aye rẹ

Oríṣun àwòrán, Elegbeje Ado

Taiwo Adeshina 'Elegbeje Ado' jade laye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu, Kẹfa, ọdun 2026 yii lẹyin aisan ranpẹ.

Oṣere tiata to maa n bẹ awọn arugbo wo, Kunle Afod lo fi ikede iku rẹ lede.

A gbọ pe lẹyin aisan ranpẹ ni Elegbe Ado jade laye.

Elegbeje ado gbajumọ fun ipa Babalawo ati jagunjagun to maa n ṣe ninu tiata, amọ ṣaaju iku rẹ lo ya si agbo oṣere ọmọlẹyin Kristi lẹyin to gba iṣẹ iranṣẹ.

Temitope Osoba - Oṣu Kẹjọ, ọdun 2026

Temitope Osoba

Oríṣun àwòrán, osobatemitope/instagram

Ọjọ karun un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni Tope Osoba jade laye lẹyin to ti kọkọ ba aisan jẹjẹrẹ ọmu finra.

Ẹni ogoji ọdun pere Temitope ṣaaju iku rẹ.

Oniruru ariyanjiyan lo jẹyọ lẹyin iku Temitope, bi awọn kan ṣe n fẹsun kan ololufẹ rẹ, wolii ijọ alaṣọ funfun, Itunu Onadeko lawọn mii n sọ pe ọkunrin naa ko mọ nipa iku rẹ.

Taiwo Hassan 'Ogogo' – Oṣu Kejọ ọdun 2026

Ogogo wọ agbada sti file

Oríṣun àwòrán, Facebook/Taiwo Hassan

Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni Ogogo ko to jade laye.

Ọsẹ kan ṣaaju iku rẹ lawọn mọlẹbi rẹ ke gbajare sita lori ayejujara pe o ti wa ni ipele kẹrin aisan jẹjẹrẹ, ti wọn si bẹbẹ fun iranlọwọ lati tọju rẹ.

Amọ ko pẹ si asiko naa ti Ogogo fi aye silẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.

Ilu rẹ, Ilaro, ni wọn si oku rẹ si lọjọ Aje to tẹle ni ilana ẹsin Musulumi.

Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ ninu iṣe tiata ni wọn peju eto isinku ọhun.