Gbajúgbajà olórin ilẹ̀ Amẹrika, Dolly Parton ti jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dolly Parton
Gbajugbaja olorin ifẹ nnni, Dolly Parton ti jade laye lẹni ọgọrin ọdun.
Awọn mọlẹbi rẹ lo kede iku rẹ loju opo ayelujara lọjọ Iṣẹgun.
Gẹge bii atẹjade ti wọn fi lede, ilu Nashville, ni Tennessee, lorilẹede Amẹrika lo dakẹ si.
Psrton, to jẹ ọmọ atapata dide lo wa lati Tennessee titi to fi di ilumọọka agbaye, irawọ rẹ si kan fun ododo ogọta ọdun gbako.
Iye awo orin ti obinri naa ta le ni ọgọrun miliọnu kaakiri agbaye, eyii to mu ki wọn fun ni inahijẹ "Queen of Country."
Lara awọn orin Parton to milẹ titi kaakiri agbaye julọ ni "Jolene", "9 to 5", "Coat of Many Colours" ati "I Will Always Love You".
Iye orin ti obinrin naa kọ le ni ẹgbẹrun mẹta, o si gba ami ẹyẹ Grammy mọkanla nigba aye rẹ.
Yatọ si orin kikọ, o tun jẹ oṣere lẹyin to kopa ninu awọn fiimu bii 9 to 5, The Best Little Whorehouse in Texas, Steel Magnolias ati Joyful Noise.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kinni, ọdun 1946 ni wọn bi ni Little Pigeon River, Tennessee.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati igba to ti wa lọmọ ọdun mẹtala pere lo ti n kọ orin niwaju awọn eeyan.
Parton kọrin lori ẹrọ amohunmaworan ati redio ko to kọ orin ni Grand Ole Opry ni Nashville.
Akọja ewe orin rẹ lo pe ni "Puppy Love" ki awọn orin mii to gbajumọ kaakiri agbaye to tẹle.
Lẹyin to pari ile ẹkọ girama lọdun 1964 lo lọ ilu Nashville nibi to ti mu iṣẹ orin kikọ loju paali.
Ọdun 1967 lo gbe awo orin rẹ akọkọ jade, orukọ awo orin naa lo pe ni Hello, I'm Dolly, ko to darapọ mọ The Porter Wagoner Show lori ẹrọ amohunmaworan.
Lọdun 1973, o fi ẹgbẹ naa silẹ lati da duro.
Lẹyin naa lo kọ orin "I Will Always Love You" eyii to da lori ipinya rẹ pẹlu ẹgbẹ ọhun..
























