Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé níbi ìdìbò abẹ́nú APC sípò Gómìnà l'Oyo

Sẹnẹtọ Sharafa Alli wọ aṣọ funfu, Sẹnẹtọ Abdulfatai Buhari wọ buba olomi buluu, nigba ti Adebayo Adelabu naa wọ aṣọ funfun

Oríṣun àwòrán, Senator Sharafadeen Alli/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Loni Ọjọbọ ni eto idibo abẹnu APC sipo gomina nipinlẹ Oyo waye niluu Ibadan, amọ, awọn kan sọ pe wọn ti di ibo naa tan ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ to dibo nipinlẹ Ọyọ.

Alukoro apapo fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ ni agogo mẹta ọsan ni eto idibo ọhun yoo bẹẹrẹ lasiko tawọn ọmọ ile ẹkọ yoo ti lọ ile.

Ṣugbọn si iyalẹnu wa ọkan lara awọn oludije, Sharafadeen Abiodun Alli ti jade sita ni bi deede aago kan kọja isẹju diẹ lati dibo tiẹ.

Lara awọn ti wọn jọ kọwọrin lati ri Sẹnẹto Yunus Akintunde, Họnarebu Akeem Adeniyi Adeyemi, Họnarebu Olamide Junaid Balikis ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Si iyalẹnu wa ni wọọdu kẹta ti Aṣofin Sharafadeen Abiodun Alli ti kọkọ dibo ni a tun ti ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lọpọ yanturu ti wọn jade lati dibo ni deede agogo mẹta.

Ninu ọrọ tiẹ Adebayo Adelabu to jẹ ọkan lara awọn to n dije sipo Gomina ninu ẹgbẹ oṣelu naa koro oju si bi awọn kan ti ṣe jade dibo saju asiko ti alukoro apapo ẹgbẹ APC fi sile.

Nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ leyin ti o dibo ni wọọdu kesan (Ibadan South-East Local Government Area) o salaye pe gbogbo eto lo lọ deedee ti awọn ọmọ ẹgbẹ to foruko silẹ jẹ 437 nigba ti awọn to si dibo fun ohun sì jẹ 430.

O fi kun pe inu oun ko dun si awọn iroyin ti oun gbo kaakiri pe awọn kan gbiyanju lati ṣe madaru si esi ibo abẹnu naa.

Adelabu sọ pe ni awọn wọọdu mi awọn janduku ko je ki awọn ololufẹ oun dibo nibẹ ti wọn sì kọ esi ibo jade ni bẹẹ ti iru iwa yi ko si da fun ijọba awaarawa.

Oludije naa ṣaalye pe oun ati awọn mẹwaa toku ko faramọ pe ki ẹnikẹni yan enikan le awọn lori to si fi kun pe iwe ejo ko-te-mi-lorun yoo tẹ awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa lọwọ.

Nigba ti o n sọrọ, eni to jẹ ọkan lara awọn alamojuto to ba akoroyin BBC Yoruba sọrọ ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ rẹ sọ pe ohun ti alukoro apapo fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ pa laṣẹ ni awọn tẹle.

O fi kun pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa gbọdọ ṣe atunṣe si gbogbo ọrọ to n ja ran-in ran-in pe Aṣofin Sharafadeen Abiodun Alli ni o jawe Olubori ni tori pe ko bọwọ fun ofin ti ẹgbẹ oṣelu APC gbe kale.