Àlàyé lórí bí ìbejì ọmọ ìyá kan náà ṣe kú láàárín ọjọ́ méjì síra wọn, ohun gangan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn

Oríṣun àwòrán, Adam Syte/Faceboo
Awọn ibeji obinrin kan ti jade laye laarin ọjọ meji sira wọn, ọpọ eeyan lo si ti n fi erongba wọn lede lori iku wọn bayii latari ipo ti awọn atawọn obi wọn wa ni ẹka eto ilera Naijiria.
Dokita Hadiyah Usman ati Aidah Usman, ti awọn mejeji jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn lo n ba aisan foniku-fọladide, sickle cell, finra lati kekere.
Naijiria wa lara awọn orilẹede ti aisan naa n ba finra julọ lagbaye.
Ọpọ awọn eeyan lo ti bẹrẹ si n ba mọlẹbi awọn ibeji naa kẹdun lori ayelujara, paapaa bi awọn mejeji ṣe jẹ onimọ iṣẹgun, ti wọn tun ku laarin ọjọ meji lera wọn.
Bi awọn ibeji naa ṣe jade laye

Oríṣun àwòrán, Hadiza Usman/Facebook
Gẹgẹ bii ohun ti awọn mọlẹbi wọn sọ, Hadiyah ṣaisan kan to lagbara nitori sickle cell to wa lara rẹ, wọn si gbe lọ sile iwosan ijọba apapọ Federal Medical Centre to wa ni Nguru, ipinlẹ Yobe.
Nigba ti yoo di ọjọ Ẹti to kọja lo jade laye.
Asiko to n gba itọju lọwọ naa ni ibeji rẹ Aidah n gba itọju nile ẹkọṣe iṣẹgun University of Maiduguri Teaching Hospital lori irufẹ ailera kan naa.
Lẹyin ti Aidah gbadun tan ti wọn si ni ko maa lọ sile, o lọ si Nguru lati lọ daro iku ibeji rẹ.
Ọjọ Aiku to jẹ ọjọ meji lẹyin iku ibeji rẹ loun naa dagbere faye.
Awọn oloogbe mejeji ni ọmọ Ọjọgbọn Hadiza Abdullahi Usman, to jẹ ọga agba ile iwosan ijọba apapọ, FMC ni Nguru, ti baba wọn si jẹ Ọjọgbọn Usman Abdullahi, oniṣegun ati olukọ ile ẹkọ giga.
Iroyin lati ọdọ mọlẹbi awọn ibeji naa fi han pe lọpọ igba lawọn mejeji maa n ṣaisan sọwọ kan bo tilẹ jẹ pe wọn ko gbe ni agbegbe kan naa.
Aisan wo ni Sickle Cell?

Aisan sickle cell ma n waye laarin awọn ọmọ ti ẹjẹ awọn obi wọn ba jẹ AS ati AS tabi SS ati AS.
Yatọ si pe aisan naa maa n da awọn to ba ni laamu, o tun maa n ṣakoba fun awọn obi ati mọlẹbi wọn pẹlu.
Iwadii fi han pe ọmọ ti iye wọn to 300,000 ni wọn n bi lọdun lagbaye ti idaji wọn si n wa lati Naijria, ninu awọn 150,000 ti wọn n bi ni Naijiria yii, nnkan bii 100,000 ninu wọn lo n ku lọdọdun.
Awọn onimọ nipa eto ilera gbagbọ pe ai kii ṣe ayẹwo ṣaaju igbeyawo tabi ibalopọ lo jẹ ki ọpọ ṣi maa bi awọn ọmọ to ni sickle cell laye ode oni.
























