Àlàyé lórí ìgbà mẹ́wàá tí bààlúù ológun tí já láàárín ọdún márùn-ún ní Naijiria

Ọkọ ofurufu NAF to ja lulẹ lọjọ Aje
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Baaluu ileeṣẹ ologun NAF 931 to jabọ n'Igbokoda, ipinlẹ Ondo lọjọ Aje ọsẹ yii ni ọrọ n lọ nipa rẹ lọwọ, amọ ọpọ ojo lo ti rọ tilẹ ti fi mu ni ijamba ọkọ ofurufu ologun lorilẹede yii, bi a ba wo iru rẹ to ti waye kọja.

O kere tan, ijamba baaluu ologun to waye laaarin ọdun 2021 si 2026 yii to mẹwaa, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe wa fun awọn iṣẹlẹ naa lorilẹede Naijiria.

O si kere tan, eeyan mejidinlaadọrun (68) lo ti ara ijamba ọkọ ofurufu naa di oloogbe, tabi ti wọn ti gba pe wọn ti ku nigba ti ẹnikẹni ko ri wọn mọ lẹyin ti baaluu wọn ja.

Lara awọn baaluu ti ijamba oju ofurufu ti kan ni Naijiria ri jẹ aladani ti wọn fi maa n ja loju ofurufu, agberapa ti a mọ si helicopter, ọkọ ti wọn fi n gbe awọn ologun lati ibi kan simobiran, eyi ti wọn fi n kọ wọn niṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn iṣẹlẹ ọkọ ofurufu ologun Naijiria to ja lulẹ laaarin 2021 si 2026

  • Ọjọ kọkanlelogun oṣu Keji ọdun 2021:

Lọjọ yii ni ọkọ ofurufu NAF Beechcraft King Air 350i, ja lulẹ kete lẹyin to gbera niluu Abuja to si n lọ si Minna, nipinlẹ Niger.

Awọn ologun meje lo wa ninu ọkọ naa, gbogbo wọn ni wọn dagbere faye.

  • Ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta 2021:

Ọkọ ofurufu Alpha Jet kan to wa lori iṣẹ nipinlẹ Borno ṣadeede poora loju ọna rẹ.

Inu igbo Sambisa ni wọn pada ti ri ajaku rẹ nibi to tuka si, wọn ko ri awọn awakọ meji to wa baaluu naa mọ, bẹẹ ni wọn si ṣe gba pe wọn ti ku ni.

  • Ọjọ kọkanlelogun oṣu Karun-un ọdun 2021:
  • Ninu ọdun 2021 yii kan naa, lẹyin oṣu meji ti Alpha Jet ja ni Borno, ọkọ baaluu NAF King Air 350 kan ja lulẹ nitosi papa ofurufu Kaduna.

Eeyan mọkanla lo wa ninu baaluu naa, gbogbo wọn ni wọn ku, titi kan olori awọn ọmọ ogun ori ilẹ igba naa, Lt. Gen. Ibrahim Attahiru.

  • Loṣu Keje ọdun 2021 kan naa, ọkọ ofurufu NAF Alpha Jet kan sọnu lẹyin ti wọn yinbọn mọ ọn nipinlẹ Zamfara.

Amọ ori ko awakọ rẹ, Flight Lieutenant Abayomi Dairo, yọ lọwọ iku, o raye jade ninu iṣẹlẹ naa.

  • 2022: Baaluu NAF Super Mushshak kan ja lulẹ ni Kaduna, awakọ mejeeji to wa nibẹ padanu ẹmi wọn.
  • 2023: Baaluu NAF FT-7NI ja ni Makurdi, ipinlẹ Benue, ori ko awọn awakọ rẹ mejeeji yọ.

Oṣu kan lẹyin eyi, ọkọ baaluu NAF Mi-171 to jẹ agberapa to n ṣiṣẹ idaboobo lọwọ, ja lulẹ ni abule Chukuba to wa nijọba ibilẹ Shiroro, ipinlẹ Niger.

Eeyan mọkanla lo ba ijamba naa lọ.

  • 2023: Oṣu Kejila ọdun 2023 ni baaluu NAF Mi-35P to jẹ agberapa ja lulẹ, kete to gbera nibudo ologun ilu Port Harcourt, ipinlẹ Rivers.

Amọ ori ko awọn eeyan marun-un to wa ninu rẹ yọ, wọn ko ku.

2025: Baaluu Alpha Jet kan koju idaamu loju ofurufu nitosi Kainji, ipinlẹ Niger. Ori ko awọn awakọ rẹ mejeeji yọ, wọn ko ku.

Oṣu Kin-in-ni ọdun 2026:

Ọkọ baaluu NAF CH-4B kan ti ki I ṣe awakọ lo n wa a, ti ko si si eeyan kankan ninu rẹ, sọnu lasiko to n wọde nipinlẹ Niger, ẹnikẹni ko ku ninu rẹ.

  • Oṣu Kẹwaa 2026:

Iṣẹlẹ ọjọ Aje ọsẹ yii to waye lọjọ karun-un oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ti I ṣe NAF 931 ni tuntun to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ lagbo awọn ologun.

Eeyan mẹẹẹdọgbọn pata ti wọn lo wa ninu rẹ ni wọn si di oloogbe niluu Igbokoda, ipinlẹ Ondo.

Ohun pato to fa ijamba naa ko ti i foju han, kaluku wulẹ n sọ ohun ti won ro pe o fa a ni.

Ẹka to n ri si iwadii ati aabo (Nigerian Safety Investigation Bureau) ti ni ojuṣe awọn alaṣẹ ologun ni lati wadii iṣẹlẹ yii.

Wọn ni amọ bi wọn ba pe awọn, ẹka naa le ṣe iranlọwọ pẹlu.