Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkunrin tó kú sínú bààlúú tó ń bọ̀ sí ìlú Eko láti Kenya

Ọkọ ofurufu Kenya ati awọn ero meji ninu awọn to wa ninu rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi iroyin ọlọkan-o jọkan ṣe gbode nipa iku ọkunrin arinrinajo kan to n bọ niluu Eko lati orilẹede Kenya, ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu Kenya ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ pato.

Bakan naa ni awọn ero ti wọn jọ wọ ọkọ naa ṣalaye ohun ti wọn ni o ṣoju awọn koro.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu Kenya Airways ṣe ṣalaye ninu atẹjade ti wọn fi sita l'Ọjọru oni, ero ọkọ kan ku sinu ọkọ naa to gbera lati Nairobi to si n bọ niluu Eko, lorilẹede Naijiria.

Atẹjade ti wọn fi soju opo X wọn lọjọ keje oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ṣalaye pe, ṣadeede ni ọkunrin naa ko mọ ibi to wa mọ, ti ko si jọ pe o n mi mọ, ki ọkọ ofurufu naa too balẹ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, niluu Eko.

Ileeṣẹ naa sọ pe ọjọ kẹfa oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni iṣẹlẹ yii waye, ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju .

Nnkan bii ogun iṣẹju lo ku ti baaluu naa yoo fi balẹ bi Kenya Aiways ṣe wi, amọ lasiko naa ni arinrinajo ọhun ko mi mọ.

"Ikọ wa fun un ni itọju akọkọ gẹgẹ bii ẹkọ ti wọn kọ, wọn si tẹle gbogbo ilana pajawiri."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.

Wọn fi kun un pe nigba ti baaluu naa balẹ tan ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport, awọn eleto ilera fidi ẹ mulẹ pe arinrinajo naa ti jade laye.

Ileeṣẹ naa loun ba ẹbi ọkunrin ọhun kẹdun iku rẹ.

BBC kan si awọn alaṣẹ ọkọ ofurufu Kenya lati mọ ohun to ṣẹlẹ pato, ṣaaju ki wọn too fi atẹjade sita, amọ wọn ko fesi.

Ohun ti awọn ero ọkọ naa kan sọ

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bo tilẹ jẹ pe ileeeṣe ọlọkọ ofurufu Kenya ṣalaye tiwọn, awọn eeyan kan lori ayelujara ti wọn lawọn wa ninu ọkọ pẹlu ọkunrin naa sọ awọn nnkan mi-in.

Ẹnikan to pe ara rẹ ni Lola ninu wọn, sọ pe o ṣee ṣe ṣe ki ọkunrin arinrinajo naa ni arun ọpọlọ

O ni oun wa ninu ọkọ naa nigba ti iṣẹlẹ yii waye.

Lola fi kun un pe niṣe ni ọkunrin naa fẹ ṣilẹkun ọkọ to n lọ lọwọ, Ọlọrun lo gba awọn ero ọkọ yoku lọwọ rẹ ti ko fi ṣe bẹẹ.

Loju opo Instagram rẹ to ni akọle yii: _neene lo kọ ọ si lọjọ keje oṣu Kẹwaa ọdun 2026, pe:

"Ero ọkọ kan gbiyanju lati ṣilẹkun ọkọ nigba ti mo n pada bọ l'Ekoo lanaa."

Lola sọ pe niṣe ni ọkunrin naa n lọ to n bọ ninu ọkọ oun, ti awọn eeyan si n rọ ọ pe ko fi ara balẹ, o ni oun tilẹ ro pe ija lo n ṣẹlẹ ninu ọkọ ni.

O ni ọkunrin naa sọ pe oun fẹ ri awakọ, boun ko ba tile ri i ki wọn jẹ koun kuku ṣilẹkun ọkọ, koun ku.

Wọn pada ri i mu walẹ, oju rẹ si da wai bi Lola ṣe ṣalaye, o ni ṣugbọn ko pẹ sigba naa lo di pe ko le ṣe nnkan kan mọ, to si pada ja si ku fun un.

Bakan naa ni ero ọkọ naa miran torukọ rẹ n jẹ Adekunbi Ewaola, ṣalaye loju opo Instagram rẹ to ni akọle @theewaola_ pe awọn ero ọkọ naa lo sare de ọkunrin naa mọlẹ, ko ma baa le ṣilẹkun ọkọ.