Ṣé òótọ́ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Edo ti fòfin de Davido láti má wọ ìpínlẹ̀ náà mọ́? Gómìnà Okpebholo ṣàlàyé

Gomina ipinlẹ Edo, Monday Okpebholo ati David Adeleke (Davido)

Oríṣun àwòrán, Gov. Monday Okpebholo/Facebook/Davido/ Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lasiko ti wọn yoo fi dibo gomina ipinlẹ Osun lọjọ Abamẹta to kọja, iroyin kan gbode pe aarin Gomina ipinlẹ Edo, Monday Okpebholo ati gbajumọ olorin sufee-taka, David Adeleke tawọn eeyan mọ si Davido, ko gún.

Ko tun pẹ ni fidio kan jade sori ayelujara, nibi ti Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Gomina Okpebholo lori iroyin ori ayelujara; Apostle Kassy Chukwu, ti kede pe wọn ti fofin de Davido, ọmọ ẹgbọn Gomina Ademola Adeleke, lati ma ṣe wa si ipinlẹ Osun mọ.

Ohun ti fidio naa ṣafihan

Gẹgẹ bi Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Gomina Okpebholo lori iroyin ori ayelujara, Apostle Kassy Chukwu ṣe wi ninu fidio naa, o ni wọn ti fofin de Davido lati ma ṣe waa kọrin nipinlẹ Edo mọ.

Kassy Chukwu ni: "A ti fofin de ọ lati ma ṣe waa kọrin nipinlẹ Edo. A ko fẹẹ ri ọ l'Edo mọ."

"Inu n bi awọn ọdọ Edo. Wọn ni tawọn ba tun mu ẹ, kẹnikẹni ma ṣe mu Davido wa lati kọrin nibikibi nipinlẹ Edo mọ."

Bẹẹ ni Apostle Kassy Chukwu sọ ninu fidio naa.

Ki ni ijọba Edo sọ?

Nigba to n dahun si fidio to gba ori ayelujara kan naa, Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Edo, Ọmọọba Kassim Afegbua, sọ pe ijọba ko fofin de Davido lati ma wọ Edo.

Afegbua sọ pe to ba wu Davido lati waa kọrin l'Edo lọjọ iwajuu, ijọba ibẹ ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade ti Afegbua fi sita lorukọ ijọba ipinlẹ Edo sọ pe:

"Awọn ọta wa tun ti gbe ìṣe wọn de; a ko fofin de Davido lati ma wọ Edo.

"Ẹni to kede ifofinde naa jẹ ọta ipinlẹ Edo, ki i ṣe ara wa, jibiti si ni pẹlu.

"Ijọba ipinlẹ Edo fi asiko yii ya ara rẹ kuro lara iru iwa idojuti bẹẹ, a si fẹ sọ pe gbogbo eeyan ni a faaye gba lai fi ti igbagbọ, oṣelu tabi ẹgbẹ yowu ki wọn jẹ ṣe.

"Bi Davido ba fẹ wa kọrin nibi lọjọ iwaju, ipinlẹ Edo yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu rẹ."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ijọba Edo naa ka.

Wọn fi kun un pe ọkan lara awọn ọmọ awọn ni David, ipinlẹ Edo ni iya rẹ ti wa, Davido funra rẹ si jẹ awokọṣe ti inu ijọba Edo dun si.

Atẹjade naa sọ pe Gomina Okpebholo ko awọn eeyan mọra lai fi ti ibi ti wọn ti wa ṣe.

O ni gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ ninu ibo Osun to waye lọsẹ to kọja ko ju oṣelu lọ.

"Ọdọkunrin to n ṣojuu Naijiria lagbaaye ni Davido,amuyangan lo jẹ fun wa, inu wa dun si iṣe rẹ, a si n foju sọna fun igba ti yoo gba ami ẹyẹ Grammy."

Bẹẹ ni ijọba Gomina Monday Okpebholo ṣalaye.