Ìjọba Nàíjíríà ṣe àfikún lórí owó oṣù àwọn ọmọ ogun láti 49,000 sí 100,000 náírà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita fọrọ eto aabo nilẹ Naijiria ti sọ pe ijọba apapọ ti ṣe afikun lori owo oṣu awọn ọmọ ogun orileede naa, lojuna lati mu ilọsiwaju ba iṣẹ wọn.
Nibi ifọrọwerọ ti minisita naa ṣe l'Ọjọru, ọsẹ yii lo ti sọ pe ijọba ṣe afikun naa lati le jẹ da si eto igbayegbadun awọn ọmọ ogun naa.
Ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira ni ijọba gbe owo oṣu naa si bayii, lati ẹgbẹrun mọkandinlaadọta naira ti wọn n gba tẹlẹ gẹgẹ bi owo oṣu.
Musa sọ pe lara awọn ifarajin ijọba Naijiria lati mu ọrọ igbayegbadun awọn ọmọ ogun lọkunkundun ni afikun ọhun jẹ.
"Nigba ti a bẹrẹ, ẹgbẹrun mọkandinlaadọta ni ọmọ ogun kan ṣoṣo n gba gẹgẹ bi owo oṣu. A sa ipa ati akitiyan wa, ni bayii, ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira ni wọn n gba bayii," o sọ bẹẹ.
Pẹlu afikun yii, minisita naa sọ pe owo ti awọn ologun n gba ko to nnkan, ati pe eto iṣuna wọn ko to lati gbogun ti ọrọ eto aabo nilẹ Naijiria.
Nigba to n dahun ibeere nipa boya eto iṣuna owo ti wọn pin fun ileeṣẹ ologun to wọn lati lo, minisita naa sọ pe, "ko to rara."
Musa wa sọ pe oun fẹ ki ijiya nla wa fun awọn ajinigbe, to si loun ṣatilẹyin fun idajọ iku fun ajinigbe tọwọ ba tẹ, leyi ti yoo mu ki gbogbo awọn to n lọwọ si iwa naa jawọ.
"Mo lero wi pe o yẹ ka ṣe bẹẹ. O yẹ ki ijiya nla wa. Ofin wa ko lagbara to, idi ree ti awọn eeyan fi n lo anfaani rẹ. Bi wọn ba mọ lẹyin ti o ti daran, o yẹ ki ijiya wa," o sọ bẹẹ.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe iroyin ti kii ṣe otitọ ni pe wọn ko bọ awọn ọmọ ogun daadaa, ati pe gbogbo awuyewuye to n kaakiri ori ayelujara lo jẹ agbelẹrọ lasan, ti ko si otitọ kankan nibẹ.
Kií ni àwọn èèyàn sọ?
Latigba ti Minisita Musa ti sọrọ naa nipa owo oṣu awọn ọmọ ogun, ni oniruuru awuyewuye ti gba gbogbo ilu, to fi mọ ori ayelujara.
Awọn agbaagba ati awọn oṣiṣẹ nidi iṣẹ ologun naa ti wa bu ẹnu atẹ lu iye owo oṣu naa, ti wọn si ni ko bojumu to rara.
Wọn ni eyi ṣafihan wi pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti kuna lati buwọ lu afikun owo oṣu to ṣeleri rẹ l'oṣu mẹrin sẹyin.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọjọbọ ọsẹ yii ni Aarẹ Tinubu ṣe ipade pẹlu awọn olori ologun niluu Abuja.
Ajagunfẹyin kan, Abdul Isiak sọ pe owo ti awọn ologun n gba lasiko yii, ko le ṣe ohunkohun ninu igbe aye ẹda, pẹlu bi eto ọrọ aje orileede yii ṣe ri.
O sọ pe bi wọn ba n gba owo gidi, yoo jẹ ki awọn ọmọ ogun tẹra mọ iṣẹ wọn lara ọtọ.
"Ko to rara. Ki ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira fẹẹ ṣe pẹlu bi nnkan ṣe ri ni Naijiria lasiko yii. Ko le ran nnkankan. Ki wọn tubọ ṣe daadaa. Bi wọn ba san owo gidi, wọn yoo tun tẹpa mọ iṣẹ ti wọn n ṣe daadaa," o sọ bẹẹ.
Ajagunfẹyin, Zaki Williams, ninu ọrọ rẹ siwaju beere boya owo ti minisita sọ sita naa jẹ otitọ
"Mo ni iyemeji boya wọn n san to iye ti minisita mẹnuba yẹn, irọ nla to jinna si otitọ ni," o sọ bẹẹ.
"Koda, to ba tiẹ jẹ bẹẹ, o ku diẹ kaato. Ijọba to ba n san ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira ko mọ ohun to n ṣe. Bi ẹ ba mọ ohun ti awọn ọmọ ogun n dojukọ, ẹ ko nii fi iru owo bẹẹ lọ wọn rara. A ti n sunkun, ṣugbọn a ko ri iranlọwọ. Ijọba ti gbiyanju, ṣugbọn wọn ṣi nilo lati ṣe daadaa sii."
Owó yìí kù díẹ́ káàtó fún ẹni tó n fi ẹ̀mi rẹ̀ wá ewu fún orílẹ́-èdè
Alakoso agba fun ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Coalition for Concerned Veterans, Abiodun Herbert-Durowaye, nigba toun naa n sọ ninu ọrọ rẹ, jẹ ko di mimọ pe owo ti wọn n san fun awọn ọmọ ogun to n fi ẹmi wọn wewu fun orileede yii ko to rara.
"Bawo ni a ṣe maa sọ pe eyi dara. Bawo ni owo yii yoo ṣe to lati na fun ẹni to n fi ẹmi rẹ wa ewu fun ilẹ orileede?
"A mọ bi ọrọ eto aye gbigbe ṣe ri lasiko yii. Owo yii ko to fun ọkunrin to n fi gbogbo ọjọ aye rẹ wa ibaṣepọ alaafia ni orileede.
"O jinna sira wọn. Eelo ni wọn n ta apo irẹsi kan lonii, a ko tii mẹnuba ọrọ owo ile-ẹkọ awọn ọmọ, aabo ati awọn ohun miran?" Durowaye sọ bẹẹ.



























