Àjọ EFCC wọ́ olórí ẹgbẹ́ Miyetti Allah lọ sílé-ẹjọ́ lórí ẹ̀sun jìbìtì $2.3m

Bello Bodejo, olori ẹgbẹ Miyetti Allah

Oríṣun àwòrán, Bello Bodejo/EFCC

Àkọlé àwòrán, Bello Bodejo
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC ti wọ olori ẹgbẹ Miyetti Allah lọ siwaju ile-ẹjọ lori ẹsun jibiti owo to le diẹ ni miliọnu meji ($2.3) owo dọla.

Bodejo to je olori eka ẹgbẹ naa ti wọn pe ni Miyetti Allah Kautal Hore, to jẹ igun labẹ aburada Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria (Macban), ni EFCC fẹsun jibiti naa kan.

Ẹsun mejila ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu iwa ajẹbanu ni ajọ naa fi kan Bodejo niwaju ile-ẹjọ, eyi ti wọn sọ pe o tẹwọ gba obitibiti owo ilẹ okeere ọhun, ti wọn lo lodi si ofin.

Bo tilẹ jẹ pe Bello Bodejo to jẹ ọga wọn sọ pe oun jẹbi lori awọn ẹsun mejila naa, ṣugbọn sibẹ, EFCC sọ pe gbigba iru owo bẹẹ ni kisi ko tọna labẹ ofin.

Ki ni iwe ofin sọ

Gẹgẹ iwe ofin gbigbe owo rin nilẹ Naijiria, okoowo yoowu ti eeyan, ẹgbẹ tabi ileeṣẹ ba fẹẹ ṣe, eyi to ba ti nii ṣe pẹlu owo lati ori miliọnu marun-un naira lọ soke, gbọdọ jẹ eyi ti wọn fi n ranṣẹ lati apo aṣuwọn ile ifowopamọ kan si omiran, kii ṣe nipa gbigbe owo rin tabi titewo gba a.

Iwe ofin naa sọ pe ẹni to gbe owo lati san owo, ati ẹni to gba owo naa, ni wọn jọ lodi si ofin, ti wọn si gbọdọ foju winna ofin.

Ọkan lara awọn ẹsun naa sọ pe lọjọ kọkanla, oṣu Kinni, ọdun 2022 ni Bodejo mọ-ọn-mọ gba owo naa to jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun owo dọla lọwọ ẹnikan to n jẹ Sa'idu Abubakar, iyẹn alakoso agba feto iṣuna ipinlẹ Bauchi nigba kan ri.

Ta lo gbe owo naa fun Bodejo?

EFCC fidi rẹ mulẹ pe Sa'idu Abubakar ti wa ni ahaamọ awọn ọlọpaa ilẹ Naijiria.

Bakan naa ni ajọ naa tun fi kun ọrọ wọn pe lọjọ keje, oṣu Keji, ọdun 2024 ni Bodejo tun tẹwọ gba owo to to ẹgbẹrun lọna ọgọrinlelẹẹdẹgbẹrun ($980,000), ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ($500,000) owo dọla ninu oṣu Kẹta, ọdun 2024, lọwọ Sa'idu Abubakar kan naa.

Lẹyin ti Bodejo sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti ajọ EFCC fi kan oun, agbẹjọro rẹ, Ahmed Raji rọ ile-ẹjọ lati fun un ni anfaani beeli.

Ṣugbọn ṣa, agbẹjọro EFCC, Wahab Shittu sọ pe ọrọ gbigba beeli fun Bodejo ko le ṣeeṣe, nitori pe ohun to lewu ni lati fun ọkunrin naa ni beeli.

Shittu sọ pe ohun to dara ni lati fi ọga Miyetti Allah naa pamọ si ọgba ẹwọn Kuje, titi digba ti igbẹjọ miran yoo tun waye.

Onidajọ Inyang Ekwo to gbọ ẹjọ naa, ti wa sọ pe ki Bodejo ṣi wa lọgba ẹwọn titi di ogunjọ, oṣu Keje, ọdun yii ti igbẹjọ miran yoo waye, lati le mọ boya o tọ si beeli, tabi ko tọ.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Bi ẹ ko ba gbagbe, ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS lọjọ kẹsan, oṣu Kejila, ọdun 2024 gbe Bodejo, bo tilẹ jẹ pe wọn ko foju rẹ ba ilẹ-ẹjọ, ṣugbọn ti Onidajọ Mohammed Zubairu pada sọ pe ki wọn fi silẹ, iyẹn lọgbọn ọjọ, oṣu Kejila, ọdun naa.

Adajọ naa sọ pe bi ile-ẹjọ ṣe ni ki wọn yọnda Bodejo, ko tunmọ si pe wọn ti tu u silẹ patapata lati maa lọ layọ ati alaafia, bi ko ṣe pe lati ma jẹ ki wọn tẹ ẹtọ rẹ labẹ ofin loju mọlẹ lasan ni.

O ni ileeṣẹ eleto aabo ko ni ẹtọ lati fọwọ ṣikun ofin mu eeyan, lai jẹ pe wọn fi ẹsun kan an niwaju ile-ẹjọ lọna to tọ.

Ta ni Bello Bodejo?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọmọ bibi ipinlẹ Nasarawa ni Alaaji Bello Badejo, iyẹn ni ẹkun Aarin Gbungbun Ariwa ilẹ Naijiria. O jẹ olori ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah Kautal Hore ti ẹnu n kun kaakiri Naijiria.

Oniruuru aami ẹyẹ ati oye idalọla ni ọkunrin naa ti gba lẹkun Ariwa ilẹ Naijiria, lara rẹ si ni 'Lamido Fulbe' ati 'Majidadin Mambilla'.

Ọpọ igba ni awọn ileeṣẹ eleto aabo bii ologun ati ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti gbe Bodejo lori ẹsun wi pe igun Miyetti Allah tirẹ lo n kopa oniruuru iwa ọdaran kaakiri orileede Naijiria, ṣugbọn to jẹ pe niṣe ni wọn tun n gbe e ju silẹ, lai foju rẹ ba ile-ẹjọ.

Ninu oṣu Kinni, ọdun 2024, Bodejo ṣagbekalẹ ẹgbẹ kan to pe ni 'Nomadic Vigilante Group', leyi to sọ pe oun finufẹdọ da silẹ lati ṣagbelarugẹ fun eto aabo awọn ọmọ ẹgbẹ, paapaa lawọn agbegbe ti wọn ti n ṣe oniruuru ikọlu si wọn.

O sọ fun BBC nigba naa pe ẹgbẹ fijilante oun naa ni ọmọ ẹgbẹ ti ko din ni igba, ṣugbọn ti awọn ṣi n foju sọna lati ni ọmọ ẹgbẹ to to ẹgbẹrun mẹrin.