Wọn jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, ja àìmọye ilé ìtajà lólè lásìkò tí ìwọ́de ìwà ipá sáwọn àjèjì bẹ̀rẹ̀ padà nílẹ̀ South Africa

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
O kere tán, ọkọ mẹrinlelogun lọ tí jóná, tí wọn sì tún ja àìmọye ibùdó ìtajà to jẹ táwọn àjèjì lólè nílẹ̀ South Africa ní báyìí tí ìwọ́de sáwọn àjèjì di ìwà ipá làwọn ìlú ńlá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni orílẹ̀èdè náà.
Gẹ́gẹ́ bí ileeṣẹ ọlọpaa ni orílẹ̀èdè náà ṣe wí, làásìgbò bẹ silẹ nilu Soweto lọ́jọ́bọ ana.
Ilu náà sì sún mọ́ ìlú Johannesburg tíì ṣe olú ìlú ilẹ̀ South Africa èyí tó tóbi julọ pẹlu ìlú Durban tíì ṣe ìlú ńlá to jẹ ibudokọ ojú omi.
Ìwà ipá àti ìwọ́de náà lo bẹ silẹ bí inú ṣe ń bí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè náà lórí idajọ iléẹjọ́ kan tó fi ààyè gba àwọn àjèjì to wọ orílẹ̀èdè náà lọ́nà tó bá òfin mú láti béèrè fún àṣẹ láti ṣe àtìpó.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí ṣe okùnfà báwọn ìlà gbọọrọ táwọn èèyàn tó si làwọn iléeṣẹ́ to n ri si eto wọlé wọde èèyàn àti ẹrú lórí lédè náà.
Ijoba sì ti kede lọ́jọ́ Ẹtì pé òun yóò mú ayipada bá ona ti wọn yoo gba ṣe amusẹ àṣẹ iléẹjọ́ náà àmọ́ kò ṣàlàyé ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé nípa rẹ.
Ẹ̀ka iléeṣẹ́ to wa fọrọ abẹ́lé lorilede South Africa tí wá kéde pé ìlànà tuntun náà tí mú kí isẹ ọhun wọ àwọn ọṣìṣẹ́ rẹ lọrun, tí "ìdúnkookò àti ewu ńlá feto ààbò aráàlú àti Ibọwọ fún òfin si ti f'oju hàn"
Iléeṣẹ́ fọrọ abẹ́lé náà ni ìlànà tuntun náà yóò sì tẹ́lẹe àṣẹ tile ẹjọ pa.
Orílẹ̀ede South Africa lọ tí ń sá fihan ìwà ipá sáwọn àjèjì léraléra, tí wọn sì ń dójú ìjà kọ àwọn atọhunrinwa làwọn orílẹ̀èdè to mule tí wọn.
Àwọn ọlọ́pàá ń yín ìbọn onirọba láti tú àwọn oluwọde náà ká báwọn ibùdó ìtajà to wa laarin ìlú ṣe ń gbé ilẹkun wọn ti
Ṣé ni wahala bẹ silẹ lásìkò ìwọ́de to wáyé lanaa ọjọ́bọ nítorí àwọn ẹ̀sùn pé àjèjì kan tàbùkù ọkàn lára àwọn èèyàn tó ń ṣe ìwọ́de nilu Durban.
Gẹ́gẹ́ báwọn ọlọ́pàá tí wí, ọwọ́ tẹ àwọn àjèjì mẹta nibamu pẹlu ẹ̀sùn ọyaju nàá.
Nilu Durban, to wa lekun ìlà oòrùn agbegbe KwaZulu-Natal, làwọn oluwọde tí péjọ níwájú ibùdó igbalejo àwọn àtìpó tijọba gbé kalẹ, tí wọn sì ń béèrè pé kí ibùdó náà jawọ nínú gbigba ìwé ìbéèrè láti ṣe àtìpó ní orílẹ̀èdè náà lọ́wọ́ àwọn àjèjì.
Ṣe ni àwọn ọlọ́pàá ń yín ìbọn onirọba láti tú àwọn oluwọde náà ká báwọn ibùdó ìtajà to wa laarin ìlú ṣe ń gbé ilẹkun wọn ti.
"Àwọn àjèjì àti ọmọ onílùú dojú ìjà kọ ara wọn lágbègbè náà" Oga ọlọ́pàá kan ni agbegbe yìí, Xolani Fihla lo sọ bẹẹ fún iléeṣẹ́ agbohunsafefe ilé South Africa.
"Mọ lè sọ fún yín pé títí di àkókò yìí, wọn kò tíì fi to wa leti pé ẹnikẹ́ni fi ara pa"
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọkọ mẹ́rìnlá ni wọn sún nina nilu Durban àti mẹ́wàá nilu Soweto níbi tí ìró ìbọn tí ń dùn lakolako lasiko iporogan laarin awọn àjèjì to kí ibùdó ìtajà àti ọmọ onílùú.





























