Àdéhùn jógunómí tí Trump ṣe fún Lebanon bá Israel lójijì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi iroyin jogunomi ṣe gba gbogbo apa Ariwa ilẹ Israel kan, bẹẹ ni wọn tun fọn fere tantan lẹẹẹmẹta nirọlẹ ijẹta lati kilọ ado oloro to ṣee ṣe ko ti Lebanon wa.

Bakan naa ni ikọ oju ofururu ilẹ Israel tete gbera sọ lati dena ikọlu to n rọ dẹdẹ lori ilu Nahariya, bẹẹ ni ado oloro n bu gbamu.

Gẹgẹ bi ikọ alaabo to n wa ọkọ agbokuu-gbe alaye (Ambulance) ṣe wi, o to eeyan mẹta to farapa ko too di pe ofin jogunomi naa bẹrẹ.

Kaakiri Israel ni wọn ti n ṣiyemeji lori idi ti olori ilu naa fi tọwọ bọwe adedun onigbedeke naa.

"Niṣe lo da bii pe ijọba purọ fun wa."

Akẹkọọ ti orukọ rẹ n jẹ Gal, ni Nahariya lo sọ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe;

"Ileri ti wọn ṣe fun wa ni pe nnkan maa yatọ lọtẹ yii, ṣugbọn o tun jọ pe a tun n pada sibi adehun jogunomi ti ko tan iṣoro kankan ni."

"A fun ijọba Lebanon ni anfaani, wọn si kọ lati tẹle adehun; wọn ko gba agbara lọwọ awọn Hezbollah."

Ẹlomi-in ti orukọ tiẹ n jẹ Maor, ẹni ọdun mejilelogoji to maa n wa tirela, amọ ti ado oloro ba ile rẹ lọdun to kọja lo ṣalaye bẹẹ.

"Bi a ko ba ṣe e, ko sẹni ti yoo ṣe e. Itiju ni pe won tiẹ dawọ ẹ duro, òye foju han tẹlẹ pe iyatọ fẹẹ wa, pẹlu awọn ohun ti a ti ri ṣe."

Ibudo ologun marun-un ni Israel ni, ni Guusu Lebanon, agbẹnusọ wọn si ni awon yoo maa tẹsiwaju.

Adehun òjijì

Adehun jogunomi yii ba ọpọ ọmọ Israel lojiji gan-an, ẹka iroyin Israel kan to gbajumọ pupọ, kede pe laaarin iṣẹju marun-un pere ni Olootu ijọba, Benjamin Netanyahu, fi pe ipade apapọ lori aabo, ko si pẹ lẹyin rẹ ni wọn kede adehun jogun-o-sinmi.

Awọn kan to tu aṣiri ipade naa tilẹ sọ pe awọn minisita to wa nibi ipade naa ko wi nnkan kan, wọn ko fun won laye lati yan ohun ti wọn fẹ.

Loju ọpọ ọmọ ilẹ Israel, Netanyahu lo n foribalẹ fun Trump pe ki ogun duro na, koda nigba ti ohun gbogbo to yẹ ki wọn ṣe ko ti i jẹ ṣiṣe.

" Bi eeyan ba fẹ ṣe adehun jogunomi, o yẹ ko waye nipa agbara ni, ko si wa fun anfaani awon ọmọ Isreali."

Olori ikọ ologun IDF tẹlẹ, Gadi Eisenkot, lo sọ bẹẹ.

"Ilana ti won n lo fun wa bayii ni fifi ipa mu wa lati jẹ kogun-o-mi, ni in Gaza, Iran ati Lebanon bayii. Netanyahu ko mọ bi wọn ṣe n sọ aṣeyọri ologun di èrè fun araalu."

Alaye Netanyahu

Nigba to n ṣalaye adehun jogunomi naa, Netanyahu sọ pe "anfaani kan ni lati jẹ ki alaafia ti yoo wa ninu itan waye pẹlu Lebanon"

O si tun sọ pe oun naa n ṣe awọn eto lori adehun yii.

Netanyahu ni Hezbollah taku pe ọna meji ni ọrọ yii ja si: Akọkọ ni kiko ọmọ ogun Israeli kuro ni Lebanon, ikeji si ni "ilana ka jọ dakẹ".

"Ko seyi ti mo gba wọle ninu mejeeji." A ko ti I ṣe eyikeyi ninu mejeeji. A ṣi maa wa ni Lebanon, nibi ti aabo ibẹ ti le. A wa nibẹ a o si ni I kuro."

Bẹẹ ni Netanyahu wi.

Iran ni tiẹ n fẹ opin si ija Israeli pẹlu Hezbollah to jẹ eeyan rẹ ni Lebanon, latigba ti won ti fẹnuko si adehun jogunomi ọlọsẹ meji pẹlu America nibẹrẹ oṣu yii.

Netanyahu ati awọn olori ogun Israel n ri adehun jogunomi ti Trump ṣe pẹlu Tehran bii pe ko tumọ si bẹẹ ni Lebanon.

Ṣugbọn ọpọ ọmọ Israeli lo n ri olori wọn bii ẹni ti wọn ti ko ni papamọra lati gba ohun ti America ba n fẹ.

Ati pe ohun ti America n fẹ yatọ si tawọn.