''Mi ò sọ pé àṣìṣe wà nínú òfin owó orí tuntun ilẹ̀ Nàìjíríà, wọ́n ṣì mí gbọ́ ni'' -Mínísítà ìpínlẹ̀ fún ètò ìṣúná

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita ipinlẹ fun eto iṣuna lorilẹede Naijiria, Taiwo Oyedele, ti yanna-na ọrọ ti wọn lo sọ pe aṣiṣe wa ninu ofin owo ori tuntun ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu gbe kalẹ.

Oyedele ṣalaye lọjọ Aiku, ọjọ kejila oṣu Kẹrin ọdun 2026, pe oun ko sọ ohun to jọ bẹẹ.

Ninu atẹjade ti 'Presidential Fiscal Policy and Tax Reforms' fi sita lọjọ Aiku ni minisita naa ti sọ pe iroyin to le ṣi araalu lọna ni wọn n gbe kiri.

Nibi eto ẹgbẹ awọn amofin; Nigerian Bar Association (NBA) to waye niluu Eko laipẹ yii ni wọn ni Oyedele ti sọ pe oun gba pe aṣiṣe wa ninu ofin owo ori tuntun naa.

Wọn lo tun rọ awọn ọmọ Naijiria lati duro de abọ iwadii ofin lori rẹ.

"Iroyin yi ohun ti minisita sọ pada ni, iṣẹ ti pari lori ofin naa, o si ti wa ni akọsilẹ"

Gẹgẹ bi Oyedele ṣe ṣalaye ninu atẹjade naa, o ni ko si abọ iwadii kankan lori ofin owo ori tuntun yii mọ, nitori iṣẹ ti pari lori rẹ.

Atẹjade naa ṣalaye pe :

"Agbejade naa yi ohun ti minisita sọ pada ni, bi wọn ṣe sọ pe o rọ awọn ọmọ Naijiria lati duro de abọ iwadii lẹka ofin.

"Eto to ti pari tipẹ, wọn si ti ṣe akọsilẹ rẹ, ile igbimọ aṣofin agba si ti fi ontẹ lu u, wọn ti gbe e jade lati ibẹrẹ oṣu Kin-in-ni ọdun 2026."

Minisita eto iṣuna fun ipinlẹ naa kilọ pe ahesọ iroyin bi eyi le ṣi araalu lọna, o si le ṣakoba fun ohun ti ijọba tori ẹ gbe atunto kalẹ gan-an.

O ni anfaani ti atunto ofin owo ori naa yoo mu wa lati ibẹrẹ loun ṣalaye nibi eto awọn lọya.

Titi kan bi awọn okoowo ṣe le fi orukọ iṣẹ wọn silẹ, ati iforukọsilẹ nipa owo ori sisan.

O fi kun un pe ko si ofin to pé tan, aaye ṣi le wa fun atunṣe.

O ni ṣugbọn ki araalu ri i daju pe iroyin to ba jade nibi okodoro ni won n gbagbọ, ki wọn ma si ṣe tẹle awọn ẹka iroyin aturọta bi elubọ.

Tẹ o ba gbagbe, lara atunto ati ileri Ireti ọtun (Renewed Hope) ti ijọba Tinubu gunle ni ofin owo ori tuntun tijọba kede rẹ naa wa, ai ye ọpọ araalu nigba ti wọn kede rẹ si wa lara ohun to mu ofin naa di ohun ti wọn n sọ kiri.