You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀rọ̀ ìyọnípò Makinde àti Olubadan gba ọ̀nà míì yọ, àwọn aṣòfin kan fẹ́ yọ olórí ilé nípò àmọ́...
Láti ìgbà tí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose ti fẹ̀sùn kàn ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá pé gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ń gbèrò láti yọ Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja nípò ni onírúurú awuyewuye ti ń wáyé ní Ibadan.
Lẹ́yìn náà ni olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo, Debo Ogundoyin gbé ìròyìn jáde pé Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan àti àwọn kan fi owó lọ òun láti gbé ìgbésẹ̀ ìyọnípò gómìnà Seyi Makinde.
Àwọn ẹ̀sùn yìí fa awuyewuye bí àwọn èèyàn ṣe ń bèèrè pé kí Ogudoyin dárúkọ àwọn tó fi rìbá náà lọ láti yọ gómìnà nípò.
Ẹ̀sùn yìí náà ti wá mú kí ìyapa ẹnu máa wáyé ní ilé aṣòfin Oyo bí wọ́n ṣe ní àwọn aṣòfin kan ṣe ń gbèrò láti yọ olórí ilé náà nípò nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ náà kò bá ipò tó wà mú.
Ìròyìn ní tí kò bá sí ìdásí Gómìnà Seyi Makinde, àwọn aṣòfin kò bá ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún Ogundoyin bí gómìnà ṣe pè wọ́n síbi ìpàdé kan lọ́jọ́bọ̀ ní ọ́fíìsì rẹ̀ tó wà ní Agodi ní ìlú Ibadan.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, wọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ ni àwọn aṣòfin náà ti kọ́kọ́ ṣe ìpàdé tí wọ́n ti fẹnukò lórí ìlànà tí wọ́n fi máa yọ olórí ilé náà.
Àmọ́ nígbà tí wọ́n pàdé ní ọ́fíìsì gómìnà ni aríyànjiyàn tó lágbára wáyé láàárín wọn, tí àwọn kan sì gbàgbọ́ pé ìwà tí Ogundoyin hù kó ẹrẹ̀ bá ilé aṣòfin.
Wọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan ni wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀ níbi ìpàdé náà, tí gómìnà sì jẹ́ kó yé wọn pé yíyọ olórí ilé aṣòfin máa nípa gidi lórí ìpínlẹ̀ náà lápapọ̀.
Ìṣèjọba mi ku ọdún kan àti oṣù kan lórí ipò - Makinde
Ẹ̀wẹ̀, ní ọjọ́bọ̀ kan náà ni gómìnà Seyi Makinde sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé kan tí ó ṣe tí àwọn kan sì ń sọ pé ó jẹ́ èsì sí ẹ̀sùn pé wọ́n fẹ́ yọ ọ́ nípò.
Makinde nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfilọlẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀ kan ní Ibadan sọ pé òun ṣì ní ọdún kan àti oṣù tí òun ṣì máa lò lórí ipò gómìnà.
"Nǹkan bíi ọdún kan àti oṣù kan sí àsìkò yìí ni ìṣèjọba wa yìí máa parí. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, ìyẹn tí wọn kò bá ì tíì yó mí nípò."
Ohun tí àwọn èèyàn ń sọ ni pé Makinde sọ èyí láti fi sọ̀rọ̀ lórí bí olórí ilé aṣòfin ṣe ní àwọn kan pé òun láti gbé ìgbésẹ̀ bí wọ́n ṣe máa yọ Seyi Makinde nípò.
Tí ìṣèjọba àwọn gómìnà ní ìpínlẹ̀ Oyo bá fẹ́ parí ni wọ́n máa ń ṣi ẹsẹ̀ gbé - Fayose
Nínú ìròyìn míì ni gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose tó dá gbogbo ẹ̀sùn náà sílẹ̀ tún ṣe àbẹ̀wò sí Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Oba Rashidi Ladoja lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Níbi àbẹ̀wò náà ni Fayose ti ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Seyi Makinde àti Ààfin Olubadan ti jiyàn ẹ̀sùn tí òun fi kàn pé gómìnà ń gbèrò láti yọ Olubadan.
Ó ní lẹ́yìn tí wọ́n jiyàn ẹ̀sùn náà ni olórí ilé aṣòfin jáde láti sọ̀rọ̀ pé Olubadan ló ń gbèrò láti gómìnà, ohun tí Fayose sọ pé ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún òun.
"Àwọn ilé aṣòfin kan sọ pé ọba ló fẹ́ yọ Kàbíyèsí, ṣe é gbọ́ ibi tí Ọba ti yọ Kàbíyèsí rí?"
"Bí èèyàn bá ti pẹ́ tó ti ń gé gbogbo èèyàn, yóò gé ara rẹ̀ lọ́jọ́ kan."
Fayose wòye pé ọ̀rọ̀ Seyi Makinde kò fẹ́ yàtọ̀ sí àwọn gómìnà tó ti jẹ tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo tó jẹ́ pé tí wọ́n bá ti fẹ́ parí sáà wọn máa ń ní onírúurú ìpèníjà tàbí òmíràn.
"Tí àwọn gómìnà bá fẹ́ parí sáà wọn ní ìpínlẹ̀ Oyo, wọ́n máa ń ṣi ẹsẹ̀ gbé, ó ṣẹlẹ̀ sí Akala, Ajimobi náà gbogbo rẹ̀ náà dàrú nígbà tó fẹ́ máa lọ, Makinde náà tún fẹ́ máa kó sí ságo.
"Tí ó bá bá ọ̀rọ̀ dé ọdọ̀ Olubadan, lílọ ni yóò lọ."