Àlàyé lórí báwọn olùjọ́sìn tó ní ìpèníjà etí ṣé máa ń ṣiṣẹ́ Hajj ní Mecca

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Jani Hussain ranti bi o ṣe ṣiṣẹ Hajj niluu Mecca lorilẹede Saudi Arabia ni ọmọ ọdun mẹtala.

Hassain sọ pe oun ranti bi mama oun ṣe sunkun, ṣugbọn o ni oun ko mọ nnkan to n mu mama oun sunkun.

O ni iriri to buru jai ni oun ni lasiko naa.

Lọdọọdun ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu olujọsin maa n lọ si orilẹede Saudi Arabia lati lọ fun Umrah, iṣẹ ijọsin tawọn eeyan maa n ṣe yatọ si Hajj

Iṣẹ ijọsin mejeeji lawọn olujọsin ti maa yipo Kaaba ni igba meje ọtọọtọ.

Kaaba ni awọn olujọsin gbagbọ wi pe ibẹ lo jẹ ibi mimọ julọ ninu ẹsin Islam.

Amọ, fun awọn to ni ipenija eti, ijọsin ti wọn maa n lọ ni idakẹjẹ.

Wọn kii gbọ gbogbo nnkan tawọn olujọsin yooku maa n gbọ, iru awọn olujọsin yii ni ẹgbẹ awọn olujọsin to ni ipenija eti ti wọn n pe ni Al Isharah.

Lati orilẹede UK lawọn ẹgbẹ yii to n ṣeranwọ fawọn ẹlẹsin Islam to ni ipenija eti ti maa n rinrin ajo lọ si Saudi Arabia.

Wọn maa n mu aburada pipa lọwọ lati fi le da ara wọn mọ, ati pe abuarda yii kii jẹ ki wọn sọnu laarin ero ni Mecca.

Ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Zainam Bostan lo maa n ṣe ogbufọ bi nnkan ṣe n lọ fun wọn ni Hajj.

Lati igba ti wọn ti bi Jani Hussain ni o ti ni ipenija eti.

Eyii kii si jẹ ko lọ sọ mọṣalaaṣi nigba to wa ni kekere tori ko le gbọ waasi tabi adura ti wọn maa n ṣe nibẹ.

Idi niyi ti o fi ṣalaye pe niṣe lo dabi ẹni pe oun o lọ sibi kankan nigba ti ẹbi oun kọkọ mu oun lọ si Mecca.

O ni eyi ṣẹlẹ nitori gbogbo nnkan ti wọn n ṣe níbẹ ni ko ye oun.