You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn agbébọn tún ya bo ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama ní Kwara, ṣekúpa ẹ̀ṣọ́ asọ́gbó márùn ún, dáná sun ọkọ̀ àti alùpùpù
Awọn ara ilu Nuku ni ijọba ibilẹ Kaiama, ni ipinlẹ Kwara ni wọn ti wa ninu laasigbo tuntun bayii.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn agbebọn ṣe kọlu ilu naa ni nnkan bii aago mẹta owurọ oni, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ti wọn si ṣekupa awọn ẹṣọ asọgbo marun-un.
Ilu Nuku jẹ ilu to fẹgbẹ ti ilu Woro ti awọn agbebọn ti pa eeyan bii igba ki wọn to ji ọpọ obinrin ati awọn ọmọde gbe lọ ninu osu keji ọdun yii.
Ni bi ọjọ meji ṣẹyin ni awọn agbebọn yii gbe fidio awọn ti wọn ji gbe sita, ti wọn si n sọ ninu fidio naa pe, anfaani ikẹyin ti awọn fun wọn ni eleyii.
Aráàlú ṣàlàyé bí ìkọlù náà ṣe ṣẹlẹ̀
BBC Yoruba kan si olugbe ilu Woro lori ago lati mọ kulẹ-kulẹ iṣẹlẹ naa.
Olugbe ọhun to ni ki a fi forukọ bo oun laṣiri nitori abo ara rẹ sọ pe aago mẹta owurọ kutu ni awọn agbebọn naa wa ṣekọlu si ilu awọn.
O ni "Aago mẹta oru ni wọn ya bo ilu wa, awọn ẹṣọ aṣọgbo marun-un si ni wọn pa.
"Ohun to ṣẹlẹ ni wi pe, yatọ si awọn ọlọpaa kogbọregbe ti wọn wa niluu, a ni awọn ẹṣọ asọgbo mẹwaa.
"Awọn aṣọgbo yii maa n gbasẹ funra wọn ni marun-un, marun-un.
"Awọn marun-un akọkọ ṣiṣẹ di aago meji oru, wọn si lọ sinmi sinu yara ikẹkọọ ti wọn maa n lo, lẹyin naa ni awọn marun-un ekeji gbaṣẹ."
Ẹni naa ṣalaye pe igba to di bi aago mẹta oru ni awọn oniṣẹ ibi naa de, ti wọn si n yinbọn si gbogbo ohun ti wọn rii.
"Àkóbá ní tajú-tajú àwọn ọlọ́pàá ṣe fún àwọn asọ́gbó"
"Awọn ọlọpaa ti wọn wa nibẹ yin gaasi tajutaju si gbogbo agbegbe lati le dẹkun iṣẹ awọn agbebọn wọn yii ṣugbọn akoba nla lo jẹ fun awọn aṣọgbo ti wọn wa ninu yara ikẹkọọ nitori wọn o ni imọ to nipa rẹ.
"Tajutaju yii lo ti kọkọ sọṣẹ lara wọn ki awọn agbebọn to ka wọn mọbẹ, wọn si yinbọn pa wọn sibẹ.
"Wọn dana sun awọn alupupu awọn asọgbo yii, wọn si tun ba ọkọ awọn ọlọpaa jẹ.
"Awọn asọgbo ti wọn wa lẹnu iṣẹ ati awọn ọlọpaa moribọ, awọn naa ja fitafita wọn si yinbọn fun meji ninu awọn agbesunmọmi naa.
"A o le sọ boya awọn agbebọn naa ku tabi wọn ye nitori pe awọn iyoku wọn gbe wọn dani lọ.
"A rí àwọn abẹ́rẹ́ tí àwọn agbébọn fún arawọn tí wọ́n faragbọta"
Araalu naa tẹsiwaju pe, koda awọn abẹrẹ ati ohun itọju mii ti awọn agbebọn naa fi n tọju ara wọn ti ibọn ba ninu igbo lawọn foju ri laarọ oni.
O sọ wi pe, awọn agbebọn naa o ya lati ji araalu kankan gbe, amọ taara ni wọn kọja lọ ibuba awọn ẹṣọ aṣọgbọ bi wọn ṣe wọ inu ilu, ti wọn si yinbọn fun wọn.
O sọ siwaju si pe "O ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ẹṣọ asọgbo naa ni wọn wa pa nitori awọn ni wọn mọ wọn daada tori wọn jẹ ọmọ ilu, ti wọn si n ran awọn ologun lọwọ pẹlu imọ wọn nipa agbegbe wọn.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ rẹ, Ejire Adetoun Adeyemi fi lede.
O ni, oga agba ọlọpaa ni Ipinlẹ ọhun, Adekimi Ojo sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹu lati nawọ gan awọn oniṣẹ ibi yii ati lati daabo bo araalu.
O rọ araalu lati sowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati koju awọn oniṣẹ ibi ọhun.