Agbébọn pa ọkùnrin kan lọ́nà oko, jí ìyá ìyàwó tuntun àtàwọn mí-ìn gbé lọ ní Kwara

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ojọ ibanujẹ ni ana, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii jẹ fawọn ilu kan nipinlẹ Kwara, pẹlu bi awọn agbebọn ṣe yawọ ibẹ, ti wọn si ṣọṣẹ nla.

O ya ni lẹnu pe awọn ilu wọnyi wa ni ijọba ibilẹ mẹta otọọtọ, sibẹ awọn agbebọn yii ṣọṣẹ laaarin oru ọjọ naa mọju bii pe wọn pin ara wọn ṣe e ni.

Pabanbari rẹ ni ti ọdọkunrin kan ti wọn yinbọn pa ni ilu Lata-nna, nijọba ibilẹ Patigi. Ọtọ nibi ti wọn ti ji iya iyawo gbe, gbe awọn eeyan mi-in naa wọgbo lọ.

Aago méje àárọ̀ ni wọ́n wọlé

BBC Yoruba ba ọkan lara awọn olugbe agbegbe Lata-nna sọrọ, ọkunrin ti a forukọ rẹ pamọ naa sọ pe aago meje aarọ ni wọn ya wọlu.

"Bi wọn ṣe wọlu ni wọn pade ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Ndabani Yaguru, loju ọna oko rẹ.

"O se ni laanu pe bi wọn ṣe ri i ni wọn yinbọn fun-un, o si ku.

"A o mọ ohun to sẹlẹ laarin wọn ti wọn fi yinbọn pa a, amọ o see ṣe ko jẹ pe o gbe igbesẹ lati di wọn lọwọ isẹ ọwọ wọn ni.

"Igba ti wọn pa ọkunrin naa tan ni wọn ya wọ inu ilu, wọn si lọ taara si ile ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Sanni, amọ ti ọpọ mọ si Master, wọn si ji i gbe lọ.

"Latigba naa ni ilu ti wa ni inu fuu aya fuu, ti kaluku si n rin tifura-tifura."

Ọkunrin naa salaye pe titi di akoko ti oun ba BBC Yoruba sọrọ lori aago, awọn agbebọn naa o ti i pe lati mọ ohun ti wọn fẹ fun itusilẹ Sanni Master.

Èèyàn márùn-ún ní wọ́n jí gbé ni Odo-Ore

Bakan naa, ni ilu Odo-Ọrẹ, nijọba ibilẹ Isin, awọn marun-un ọtọọtọ ni a gbọ pe wọn ji gbe lọ.

Arakunrin ti a ba sọrọ lori aago, Lekan Adewoye, sọ pe aago meji oru ni wọn de ti wọn ṣina ibọn bolẹ.

"Aago meji oru ni wọn de, wọn si n yìnbọn lati da Ibẹrubojo silẹ.

"Awọn eeyan marun-un ni wọn lọ ka mọle wọn ti wọn si ji wọn ko lọ.

"Ọkan lara wọn ni Alhaji Yusuf Yinusa to jẹ oloselu ati oludasilẹ ile-ẹkọ."

Adewoye fi kun-un pe ẹni kankan ninu ilu ko ti I gba ipe kankan lati mọ ohun tawọn ajinigbe naa fẹ lati tu awọn ti wọn ji gbe silẹ lai farapa.

BBC Yoruba pe Alaga ijọba ibilẹ Isin, iyẹn Benjamen Jolayemi, lori ẹrọ ibanisọrọ lati mọ eto to n se lati doola awọn ti wọn gbe ati lati dena irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ.

Alaga naa sọ pe ọrọ eto aabo ni, ohun o si le mẹnu ba a lori aago.

"Mi o le sọrọ eto aabo lori aago."

Bẹẹ ni Jolayemi wi.

Wọ́n gbé Ìyá ìyàwó àti alábàáse kan lọ

Ni Gaa-Idera, nijọba ibilẹ Ifelodun, eeyan meji ni iroyin sọ pe wọn ji gbe lọ.

Iwadii BBC fi han pe ọkan lara eeyan naa ni iya kan to yẹ ko jokoo gẹgẹ bii iya iyawo nibi igbeyawo ọmọ rẹ lonii ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun osu Kẹrin yii.

Iwadii sọ ọ di mimọ, pe yatọ si iya iyawo naa, wọn tun gbe eeyan kan toun naa wa ba wọn sajọyọ iyawo lọ.

"A ti lé àwọn ajínigbé kúrò ní Kwara, àmọ́ àwọn agbódegbà ni wọ́n ń kó wọn wọ̀lú padà"

Lonii ọjọ Ẹti ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fidi awọn iṣẹlẹ wọnyi mulẹ.

Oga agba ajọ naa, CP Adekimi Ojo lo sọ ọ nibi afihan ti wọn se, pe ọlọpaa ti gbiyanju agbara wọn lati dẹkun ijinigbe ni Kwara.

O sọ pe awọn ti le awọn ajinigbe kuro nipinlẹ Kwara, ti wọn si ti lọ fi ibuba wọn si awọn ipinlẹ mi-in.

Adekimi sọ pe isoro tawọn n koju bayii ni tawọn ti wọn n se agbodegba fawọn ajinigbe yii.

O salaye pe awọn agbodegba yii ni wọn maa n lọ fun awọn ajinigbe ni iroyin nipa awọn ilu ni Kwara, ti wọn si n ko wọn wọle lati wa ji awọn eeyan gbe.

O wa seleri pe gbogbo awọn agbodegba naa ni ọwọ yoo tẹ laipẹ, nitori awọn o sinmi lori ọrọ wọn.