Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí mẹ́fà tó fẹ́ ju àdó olóró sí dúkìá ìjọba l'Ondo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn afurasi mẹfa kan to n gbero lati ṣe ikọlu ado oloro niluu Akure.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Adebowale Lawal, lo sọrọ yii di mimọ lasiko to n ba awọn akoroyin sọrọ lonii Ọjọbọ, ọjọ kerindinlogun osu Kẹrin ọdun 2026.

Orukọ awọn mẹfa naa gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe fi lede ni:

Adekunle Prosper, Ojo Olumide, Tope Kolawole, Ahmed Salihu,Bolaji Adebowale ati obinrin aarin wọn; Gbadebo Abidemi.

Kọmisanna sọ pe awọn gba awọn ohun eelo ti wọn fi n se ado oloro naa lọwọ wọn, ati ọpọlọpọ nnkan miran.

Báwo lọ́wọ́ ṣe tẹ àwọn afunrasí náà?

Kọmiṣanna ọlọpaa Ondo, Adebowale Lawal, ṣalaye pe iwadii ati isẹ ọtẹlẹmuye ti ikọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ yii ṣe lo tu asiri awọn ti wọn n pinnu ikọlu naa.

O ṣalaye pe kete ti olobo ta ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ti ran awọn ọlọpaa lọ sibudo iṣẹlẹ naa, nibi tawọn afurasi ọhun farapamọ si ki ọwọ too tẹ wọn.

Adebowale ni awọn ọlọpaa yi wọn ka, wọn mu wọn, wọn si tu agbegbe naa yẹbẹyẹbẹ.

Lasiko ayẹwo ibẹ ni wọn ri awọn ohun eelo ti wọn fi n ṣe ado oloro tí wọn fẹ lo lati sọsẹ.

Yatọ si eyi, ọga ọlọpaa naa ṣo pe awọn tun gba igo 217, apo sugar, oogun, ẹrọ ilewọ 17, owo to to ₦187,000, ẹrọ komputa meji, ọbẹ, kaadi idanimọ, ẹrọ alupupu meji pẹlu awọn nnkan eelo mi-in lọwọ wọn.

O sọ siwaju pe iwadi fidi rẹ mulẹ, pe awọn kan n ṣe ado oloro lojuna ati kọlu awọn ibi to jẹ ti ijọba.

O ni o si ṣee ṣe ki wọn kọlu awọn ilu kaakiri ipinlẹ Ondo, ati awọn ipinlẹ miran jakejado orileede yi.

Adebowale sọ pe awọn afurasi naa gba ile si agbegbe Oke Odu, niluu Akure, eyi to jẹ ibi ti wọn ti n ṣe ado oloro naa.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ondo naa sọ pe awọn ọlọpaa ri awọn akọsilę kan gba lọwọ awọn afurasi naa, eyi to safihan awọn aaye ati agbegbe ti wọn fẹ ṣe ikọlu si.

O ni iṣẹ takuntakun ti awọn ọlọpaa ṣe ni ko jẹ ki ero ibi àwọn afurasi naa wa si imuṣẹ.

O wa rọ awọn onile jakejado ipinlẹ Ondo lati se iwadii daradara nípa awọn ti wọn n fun nile, ki wọn maa ba ma lo awọn ile naa fun iṣẹ ibi.