INEC Làá Hàn Mí: Èló ni àwọn olóṣèlú lè ná láti ṣe ìpolongo ìbò ní Naijiria? Ohun tí òfin sọ rèé

Àkọlé fídíò, INEC Làá Hàn Mí
INEC Làá Hàn Mí: Èló ni àwọn olóṣèlú lè ná láti ṣe ìpolongo ìbò ní Naijiria? Ohun tí òfin sọ rèé
Published

Ni bayii ti eto idibo gbogbogbo ọdun 2027 din diẹ ni oṣu mẹta pere ti ipolongon ibo si ti bẹrẹ, ajọ eleto dibo, INEC ti tan imọlẹ si iye ti ẹgbẹ oṣelu kọọkan le na lasiko yii.

Ọgbẹni Eniola Oladapo, to ba BBC Yoruba sọrọ lorukọ INEC sọ pe o lodi si ofin fun ẹgbẹ oṣelu lati gba owo lati oke okun fun ipolongo ibo wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, abala 92 ofin to de eto idibo ni Naijiria, iyẹn electoral act, ṣe alakalẹ iye ti ẹgbẹ oṣelu ati oldije le na lasiko ipolongo.

O ni ofin ko faye gba ki ẹni to ba fẹ du ipo Aarẹ na owo to pọ ju biliọnu mẹwaa naira lọ, nigba ti ẹni to ba fẹ du ipo gomina ko gbọdọ na owo ti iye rẹ ju biliọnu mẹta pere lọ.

Wayi o, iye wo wa ni ofin faye gba awọn to ba n du ipo mii bii ile igbimọ aṣofin agba ati ile aṣofin ipinlẹ atawọn ipo kekeke mii?

Wo fidio oke yii fun alaye kikun ohun ti Oladapo sọ lorukọ INEC.