Wáyà iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì já, iná ṣẹ́yọ, ṣekúpa èèyàn kan ní Ilọrin, ọ̀pọ̀ farapa, dúkìá olówó iyebíye jó mọ́lé

Ibẹrubojo gbilẹ lagbegbe Yakuba, niluu Ilọrin, to jẹ olu Ipinlẹ Kwara, lowurọ ọjọ Iṣẹgun, lasiko ti ina mọ̀nàmọ́ná gbẹmi gende ọkunrin kan, Ismail Ọlatunbọsun, ẹni ọgbọn ọdun, ti ọpọ miran si farapa yanna-yanna.
Ninu awọn to farapa yii lati ri aburo oloogbe naa, Yetunde Olatunbosun to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ gbogbonise Kwara ((Kwara Poly) o si n gba itọju lọwọ ni ile-iwosan lai tii mọ bayii wi pe ẹgbọn oun ti ṣe alaisi.
Yetunde ati ẹgbọn rẹ to doloogbe ni wọn jọ wa ninu ile nigba ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ.
Iroyin tun sọ pe ọpọlọpọ dukia, to fi mọ ile lo jona ninu ijamba naaIsẹlẹ laabi yii.
Ki lo ṣẹlẹ gan?

Ohun ti a gbọ ni pe wáyà ẹlẹntiriki kan lagbegbe naa ṣa dede re lu ara wọn, eleyii to fa ina nla to sọ to si da wahala naa silẹ.
Iwadii BBC News Yoruba fihan pe waya ina nla (High tension) eyi to mu ina ẹlẹntiriki wọ agbegbe naa lo re lu ara wọn ati pe aiboju to o lasiko lo mu ko di pakute iku.
Awọn eeya kan sọ pe nigba ti waya naa relu ara wọn ni o mu ina to lagbara ju wọ agbegbe naa, ati wi pe nigba tawọn eeyan n gbiyanju lati lọ pa awọ̀n nnkan elo ina mọnamọna to wa ni ile wọn ni ijamba naa bẹrẹ.
Igba ti BBC News Yoruba de agbegbe naa, jẹ asiko ti wọn n se adura fun oloogbe naa ki wọn to gbee lọ si itẹ lati sin-in.
Mo ti ní kí ọmọ mi padà sílé, ṣùgbọ́n ó kọ̀ - Ìyá olóògbé

Mama oloogbe naa ti ọpọ mọ si Iya Barakah Olatunbosun ba BBC News Yoruba sọrọ pẹlu omije loju.
Iya Barakah sọ pe ilu Eko ni oun wa ti wọn si pe oun ni ipe pajawiri ni aarọ ọjọ naa pe ki oun maa sa bọ ni Ilorin.
"Iwe lo wa ka ni Ilorin ti o si yege, o si tun sin ilẹ baba rẹ ni Kwara, lẹyin to pari, mo ti sọ fun-un ni ọpọlọpọ igba pe ko pada wale sugbọn ko gbọ simi lẹnu. Ohun ti o sọ ni pe, oun ti n ri isẹ ṣe wẹrẹwẹrẹ ni Ilorin, pe tọrọ kọbọ si n wọle. O ni agbegbe Kwara ba oun lara mu, nitori nnkan ko wọn pupọ nibẹ lai mọ pe ẹmi rẹ ni yoo pada fi dii."
Aládùúgbò olóògbé ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an

Ọrẹ oloogbe naa ti oun naa jẹ olugbe agbegbe naa salaye ohun to sẹlẹ ki Ismail to di oloogbe.
Ọrẹ naa to n jẹ Obey Oriade Emmanuel ti ọpọ mọ si India sọ pe yara oun lo kangun si yara Ismail.
O salaye sii pe, ariwo aburo rẹ loun gbọ laarọ kutuku ti oun fi bẹ sita lati le mọ ohun to n sẹlẹ ninu yara wọn.
Gẹgẹ bi o ṣe wi, "Ismail ṣẹṣẹ pari sisin ilẹ baba rẹ ni, ni nnkan bii aago marun-un idaji ni wọn mu ina abami de ti ina si n gbe (shock) gbogbo araadugbo."
"Igba ti Ismail rii pe, ina ṣẹ yọ lara ogiri ni o gbiyanju lati yọ foonu rẹ lara ogiri. Bi o se gan mọna ni yẹn o ti ko si lee sọrọ mọ. Bi aburo rẹ ṣe fọwọ kan an lati doola rẹ ni ina ba sẹyọ lara oun naa, oun naa ba subu lulẹ. "
O ni ariwo aburo rẹ ni oun gbọ ti oun fi sare jade, ti oun si pe awọn iyoku, a si ja ilẹkun wọle.
Arakunrin yii tun ṣalaye pe ina naa tun gbe iya to sare lọ yọ fiusi lara mita, ti gbogbo ọwọ rẹ si jo.
"A sare gbe awọn mejeeji lọ ile iwosan, UITH, wọn o kọkọ da si wa, wọn sọ pe awọn ti dasẹ silẹ sugbọn lẹyin atotonu, wọn ṣe ayẹwo fun Ismail, esi si jade pe, o ti ku. Ẹyin igba naa ni a gbe aburo lọ ile iwosan aladani fun itọju. "
"Awọn NEPA ti sáré wá se iná náà láti fi bo ẹ̀rí mọ́lẹ̀"

Ẹwẹ, arabirin Christiana Lawal ti oun naa jẹ aladugbo sọ pe awọn awọn NEPA ti sare wa so ina naa nigba ti wọn gbọ pe o ti mu ẹmi eeyan lọ.
O fi kun-un pe, waya (high tension) ni o re lurawọn ti o si ti yẹ ki wọn tun-un ṣe ki wọn to muna wa.
O ni wọn ti sare wa see bayii lati fi bo ẹri mọlẹ ki asise wọn ma baa han sita. Bẹẹ lo rọ ijọba ki wọn dide si ọrọ naa ki oloogbe ọun ma bàa ku gbe.
O ni aburo Yetunde to jẹ akẹkọọ gbogbonise Kwara (Kwara Poly) n gba itọju bayii lẹyin ti awọn aladugbo te owo jọ lati gbe lọ ile iwosan.
O rawọ ẹbẹ si ijọba ati awọn alẹnulọrọ lawujọ lati dide iranlọwọ.
A o ti le sọ ni pato iye eeyan to farapa ati awọn dukia to bajẹ nibi iṣẹlẹ naa nitori iwadii si n tẹ siwaju.
























