Bí arábìnrin tó kó Ebola wọ Nàìjíríà ṣe rìnrìnàjò afẹ́ lọ sí Uganda, àtàwọn ohun míràn tí a mọ̀ nípa àrùn Ebola àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà láti ọdún 2014

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹniyan akọkọ ti Naijiria tii fidi rẹ mulẹ p e o laarun Ebola lorilẹede Naijiria lati igba ti aarun ọhun ti bẹrẹ loṣu karun un ọdun yii lẹkun ila oorun Africa ni wọn sọ wi pe o jẹ iyawo oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju ijọba ilẹ okeere kan to rin irinajo lọ gba afẹ ni olu ilu Uganda.
Dokita agba ajọ to n mojuto ajakalẹ arun ni Africa, Africa CDC lo sọ eyi fun BBC.
Dokita Jean Kaseya to jẹ adari ajọ Africa CDC ṣalaye pe Ọmọ orilẹede Uganda ni arabinrin naa, ṣugbọn ilu Abuja lo fi ṣe ibugbe, nibẹ lo si ti dubulẹ aisan fun ọjọ mẹta lẹyin to de si olu ilu Naijiria ni ọjọ kẹta oṣu kẹwaa.
Minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria, Muhammad Ali Pate pẹlu fi idi rẹ mulẹ pe ọsẹ meji abọ ni arabinrin ẹni ọdun mejilelogoji naa lo ni ilu Kampala, o si duro fun wakati meji ni olu ilu Ethiopia lasiko to fi n pada bọ ni Naijiria.
O ni "ara rẹ ti n balẹ"
O fi kun un pe kii ṣe gbogbo awọn mẹrẹrinlelogoji to farakinra pẹlu arabinrin naa ni wọn fi ara kan an pẹkipẹki, bẹẹni ko tii si eyikeyi ninu wọn to tii ni ami pe aisan naa ti wọ ara wọn.
Bawo ni irinajo obinrin naa ṣe jẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Kaseya sọ wi pe ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa ni arabinrin naa kọkọ fi ami han pe aarun naa wa lara rẹ.
"O lọ si ileewosan aladani akọkọ ni ireti pe aisan iba lo n ba oun finra, o tun lọ si ikeji ki wọn to daa duro si ileewosan keji yii ni ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa."
Minisita feto ilera, Pate sọ pe, nigba ti ara rẹ ko yipada ni wọn ke gbajare si awọn alaṣẹ ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹwaa ti esi ayẹwo rẹ lọjọ keji si fidi rẹ mulẹ pe o ni aarun Ebola.
Ọrọ irinajo alaisan naa di arinyanjiyan pẹlu Uganda

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaye ti minisita feto ilera ni Naijiria ati dokita agba fun ajọ to n mojuto ajakalẹ arun ni Africa, Africa CDC ṣe lori bi arabinrin naa ṣe rinrinajo rẹ ko ba awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Uganda lara mu rara ni. Wọn ni arabinrin naa ko wa si Uganda rara.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita wọn ni ọmọ orilẹede Naijiria ni arabinrin naa ati pe o rinrinajo lọ si orilẹede DR Congo fun ọrọ aje ni, o kan gba orilẹede Uganda kọja ni.
Uganda n faake kọri pe ko si ẹnikẹni to laarun Ebola lorilẹede naa lọwọ yii nitorinaa ko si bi arabinrin naa ṣe le ko arun ọhun nibẹ.
Minisita fun eto ilera ni Naijiria ni awọn oṣiṣẹ ilera ni Naijiria ti n sọrọ pọ pẹlu Uganda, Ethiopia ati ajọ Africa CDC lati fi idi okodoro ọrọ naa mulẹ.
Bakan naa ni Dokita Paseya to jẹ adari agba fun ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun nilẹ Africa, Africa CDC rọ awọn orilẹede Africa lati fi awọn iroyin to ba wa larọwọto wọn to awọn oluwadii leti lati lee yannana bi irinajo arin naa ṣe lọ si ati ibi ti o ṣeeṣe ko ti ko arun naa.

























