Ìgbà èwé Toluwanisings le, ọkadà bàbá rẹ̀ ló fi ń gbérò láti rí owó jẹun, ó tún ṣe lébìrà kó tó lu àlùyọ - Ọ̀rẹ́ tímọ́ olóògbé

Aworan Toluwanisings atawọn to n ṣedaro rẹ.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi a ba ku la n di ere, eeyan ko sunwọn laaye.

Se ni awọn ọrẹ igba ewe, alabagbele atawọn aladugbo ni agbegbe Olanbe nipinlẹ Ogun to ti ja pọ mọ ipinlẹ Eko, pejọ lati se ẹyẹ ikẹyin pẹlu abẹla titan fun gbajumọ akọrin ẹmi Olayemi Bayonle Bolaji, ti ọpọ eeyan mọ si Toluwanisings.

Akọrin ẹmi naa lo mi kanlẹ ni ni ọjọru, ọjọ kẹrinla osu Kẹwa ọdun 2026 lasiko to subu nile rẹ nilu Ibadan.

Nibi eto abẹla titan tawọn eeyan naa se fun oloogbe yii, ni wọn ti kọ oniruuru orin onigbagbọ, ti wọn si wọ asọ dudu lati se ọfọ akọrin ẹmi naa.

Bakan naa ni awọn eeyan to peju sibi ẹyẹ abẹla titan naa sọrọ aro nipa oloogbe yii, ẹni ti wọn ni awọn dijọ se kekere ni.

" Toluwanisings ko fẹran bọọlu gbigba daadaa, Table Tennis lo fẹran, ibẹ si la ti fun ni orukọ Ajọ̀"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Peter Omotolani tii se ọkan lara ọrẹ igba ewe Toluwanisings, salayepe ọrẹ timọtimọ oun ni oloogbe naa lati kekere, ti awọn si dijọ dagba si adugbo naa ti wọn n pe ni Kowe isalẹ ni adugbo Lambe nipinlẹ Ogun.

O wa salaye awọn iriri igba ewe oun ati oloogbe Toluwanisings fun BBC News Yoruba.

" Toluwanisings ko fẹran bọọlu gbigba daadaa amọ ni ẹkọọkan, o maa n dara pọ mọ wa lati gba bọọlu.

Ere idaraya bọọlu ẹlẹyin ti a mọ si Table Tennis ni oloogbe naa fẹran, ibẹ si la ti fun ni orukọ Ajọ̀ tori o maa n gbariwo ajọ, o si pegede ninu ere idaraya naa.

"Asiko ti Wolii Arole gbe Toluwanisings soju opo ayelujara rẹ ni awọn eeyan bẹrẹ si ni maa mọ ọ, ti isẹ rẹ si n lọ soke siwaju si"

Awọn ọrẹ, aladugbo ati ẹgbẹ olorin ẹmi GOMAN wọ asọ dudu, gbe ilu lọwọ pẹlu aworan Olayemi Bayonle Bolaji ti ọpọ mọ si Toluwanisings
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn ko bi Toluwanisings ni idile olowo, igba ewe rẹ si le gidi tori lojoojumọ lo maa n fi ẹsẹ rin lọ sile ẹkọ lati Kowe isalẹ lọ si Oke Aro fun odidi ọdun mẹfa.

Ti Toluwanisings ba ti ileẹkọ de, yoo gbe ọkada baba rẹ lati fi sisẹ lọ, yoo gbe ero lati Kowe Isalẹ lọ si agbegbe Lambe ko le ri owo na.

Igba miran wa to jẹ pe yoo ba awọn eeyan ko pako tabi sisẹ lebira, ko le ri ọwọ mu lọ si ẹnu.

Amọ Ọlọrun bẹrẹ si gbọ adura rẹ nigba ti ileesẹ Redio Lagos fun ni owo lati maa bawọn se ipolowo , isẹ to kọkọ se lati ri owo gidi niyẹn."

Bakan naa ni Omotolani tun mẹnuba pe Ọlọrun tun gbọ adura Toluwanisings lati ọdọ wolii Arole.

O ni asiko ti Wolii Arole gbe Toluwanisings soju opo ayelujara rẹ ni awọn eeyan bẹrẹ si ni maa mọ ọ, ti isẹ rẹ si n lọ soke siwaju si.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe Toluwanisings kuro ni adugbo Kowe Isalẹ naa lọ silu Ibadan ko le raye maa se akọsilẹ awọn orin rẹ, ko si maa le gbe wọn jade.

"Ibadan ni Ọlọrun ti wa gbọ adura rẹ, to si n se daadaa.

"Toluwanisings ko tii pe ẹni ọdun mọkanlelogoji bawọn se n sọ, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn pere ni"

Peter Omotolani tun wa mẹnuba pe oniruuru ahesọ ọrọ lo n lọ lori ayelujara paapaa lori iye ọdun ti akọrin ẹmi, Toluwanisings jẹ, ko to jade laye ati ibi to ti subu.

Omotolani sọ pe awọn eeyan kan n sọ kiri pe ẹni ọdun mọkanlelogoji ni Toluwanisings amọ eyi ko ri bẹẹ rara, bẹẹ si lo ni akọrin ẹmi naa ko subu lori akaba ile rẹ.

"Toluwanisings ko tii pe ẹni ọdun mọkanlelogoji, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn pere ni.

Bakan naa, inu yara igbalejo Toluwanisings lo ti subu, kii se ori akasọ ile rẹ rara gẹgẹ bawọn eeyan kan se n gbe kiri.

Wọn si du ẹmi rẹ, wọn gbe lọ sawọn ile iwosan aladani, amọ wọn ni o ti ku nigba ti wọn yoo fi gbe de ibẹ, o se ni laanu pe oloogbe naa lọ ni ọjọ kekere amọ o ye Ọlọrun."

"Mo sisẹ abẹ, Toluwanisings fi N500,000 ransẹ si mi, o lawọ, ko lahun rara, igba miran, yoo fi N100,000 tabi N50,000 ransẹ si mi"

Omotolani ni lara nnkan ti oun yoo maa se aaro nipa ọrẹ timọtimọ oun ni ẹbun orin rẹ tori o yatọ si tawọn akọrin yoku.

"Ninu gbogbo awọn olorin to n kọ̀rin lọwọlọwọ bayii, awọn mẹta ni wọn ni ohun to yatọ si tawọn yoku.

Awọn akọrin ẹmi mẹtẹẹta naa ni Tope Alabi, BBO ati Toluwanisings, wọn yatọ patapata

Bakan naa, nigba kan, mo sisẹ abẹ, ti Toluwanisings si fi ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, (N500,000) ransẹ si mi, ki n fi se isẹ abẹ naa.

Toluwanisings lawọ, to si maa n fun ni ni nnkan, ko lahun rara, igba miran, yoo kan sadede pe mi, ti yoo si fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira, (N100,000) ransẹ si mi.

Igba miran, ẹgbẹrun lọna aadọta Naira lo maa fi ransẹ, aimọye igba lo ti fun mi lowo."

"A n seto concert fọdun 2027 lati ki Toluwanisings pada si agbegbe Lambe, o pa mi lẹkun pe eto abẹla titan fun iku rẹ lo rọpo Concert"

Omotolani ni ibẹrẹ ọdun yii ni oun pe oloogbe naa pe nibayii to ti di ilumọọka akọrin ẹmi, yoo dara ko jẹ kawọn seto ipejọpọ orin ta mọ si Concert ni adugbo Lambe tawọn ti dagba.

"O sọ fun mi pe oun fẹ gbadura si na, lẹyin naa lo pe mi pe ka se Concert naa lọdun 2027 to n bọ, ti awọn agba olorin naa yoo si wa.

Amọ o ya wa lẹnu, to si pa mi lẹkun pe emi to yẹ ki n maa ki kaabọ si Lambe lasiko Concert lọdun 2027, ni mo wa n seto orin abẹla titan fun."

Omotolani wa kede pe awọn ẹbi ni yoo sọ akoko ti Toluwanisings yoo wọ kaa ilẹ sun amọ awọn ẹrẹ ati aladugbo kan seto alẹ abẹla lati se ẹyẹ fun ni.