You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ làwọn ọmọ ogun máa ń ra aṣọ ogun àti ohun ààbò fúnra wọn?- iléeṣẹ́ ológun sọ̀rọ̀
Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti jiyàn ẹ̀sùn tí ọmọ ogun tẹ́lẹ̀ rí kan, Rotimi Olamilekan fi kàn pé àwọn ọmọ ogun ló máa ń ra aṣọ ogun àti ohun ìdáàbò lójú ogun fúnra wọn.
Àtẹ̀jáde kan tí adelé adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ aráàlú ní iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà, Appolonia Anele fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun sọ pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ẹ̀sùn náà àti pé ó le ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn.
Àtẹ̀jáde náà ní gbogbo àwọn ọmọ ogun ni iléeṣẹ́ ológun máa ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún.
Ṣáájú ni Rotimi Olamilekan, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Soja Boi, ti fẹ̀sùn kàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun ló máa ń ra aṣọ ogun, bàtà, àti aṣọ arọ́tadànù fúnra wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó oṣù tí wọ́n ń gbà kéré jọjọ.
Olamilekan, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe fẹ̀sùn kàn pé owó oṣù àwọn ọmọ ogun kò ju N51,000 sí N111,000 àti pé àwọn ni wọ́n máa ń ra àwọn ohun èlò tí wọ́n nílò fúnra wọn.
Lórí owó oṣù, iléeṣẹ́ ológun ní àwọn ní ìlànà tí wọ́n fi ń san owó fáwọn òṣìṣẹ́ èyí tó hàn sí gbogbo èèyàn, tó sì jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ ló ní àfikún àjẹmọ́nú tí wọ́n máa ń gbà.
"Ní àfikún sí owó oṣù, àwọn ọmọ ogun ní àǹfààní sí àjẹmọ́nú owó aṣọ ogun àtàwọn àjẹmọ́nú míì èyí tí wọ́n máa ń gbà lóòrèkóòrè.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ ológun tún sọ pé àwọn ọmọ ogún tó bá wà lójú ogun tún máa gba àjẹmọ́nú tó yàtọ̀.
"Àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n wà ní ẹ̀ka tó ń mú iṣẹ́ ṣe ni wọ́n ń gba àjẹmọ́nú lórí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe àtàwọn àjẹmọ́nú láti ṣe àtìlẹyìn fún ìgbéayé àti iṣẹ́ wọn."
Nígbàt ó ń sọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀sùn tí Olamilekan fi kàn, iléeṣẹ́ ológun ní kò sí òṣìṣẹ́ kankan tó ń ra aṣọ ogun àtàwọn ohun ìdáàbòbò fúnra wọn.
"Ríra aṣọ ogun, bàtà, àwọn ohun ìjà ogun àtàwọn ohun èlò ìdáàbòbò ló jẹ́ ojúṣe iléeṣẹ́ ológun èyí tí ẹ̀ka tó ń rí sí ìpèsè rẹ̀ máa ń mójútó."
Anele nínú àtẹ̀jáde náà gbà pé àwọn òṣìṣẹ́ kan máa ń rà kún ohun tí iléeṣẹ́ ológun bá fún wọn ṣùgbọ́n tó ní ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tó bá wu ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn, kìí ṣe dandan.
Ó ní èyí kò túmọ̀ sí pé iléeṣẹ́ ológun kò pèsè ohun tó yẹ nígbà tí òṣìṣẹ́ bá pinnu láti rà kún ohun tí iléeṣẹ́ bá pèsè.
Ó tẹmpẹlẹmọ pé kò sí òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń ràn jáde lọ ṣiṣẹ́ láì pèsè gbogbo àwọn ohun tí wọ́n nílò fún ààbò ara wọn.
"Kò sí ọmọ ogun tí a máa ran lọ sójú ogun láì pèsè àwọn ohun èlò tí wọ́n nílò láti fi dá ààbò bo ara wọn."
Ó wà rọ àwọn aráàlú láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí àwọn ẹ̀sùn náà, kí wọ́n sì máa ṣe ìwádìí nígbà tí èèyàn bá jáde láti máa fẹ̀sùn kàn.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí iléeṣẹ́ ológun fi gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Olamilekan, ó ní kìí ṣe wí pé Olamilekan sọ èrò ọkàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ bíkòṣe pé ó tàpa sí òfin iléeṣẹ́ ológun.
"Iléeṣẹ́ ológun fẹ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọn kò lé Olamilekan lẹ́nu iṣẹ́ fún sísọ òótọ́ tàbí nítorí sísọ̀rọ̀ nípa àwọn olórí tó wà nípò òṣèlú.
"Nítorí pé ó wùwà tó lòdì sí òfin lílo ẹ̀rọ ayélujára àtàwọn ìwà tó lòdì sí iṣẹ́ ológun ni a ṣe gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀."
Ó fi kun pé àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀, tó fi mọ́ bí èèyàn ṣe le máa lo ayélujára àti àṣìlò jíjẹ́ ológun èyí tó lòdì sí òfin iléeṣẹ́ ológun ni wọ́n fi gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Ṣáájú