Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ wa ní Ido-Ani, tí ìjọba Ondo fi pa wá tì láìsí ilé ìwòsàn àti ojú ọ̀nà tó dára? – Aráàlú fárígá

Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ wa ní Ido-Ani, tí ìjọba Ondo fi pa wá tì láìsí ilé ìwòsàn àti ojú ọ̀nà tó dára? – Aráàlú fárígá

Ilu Ido-Ani jẹ ara ilu to gbaju-gbaja nipinlẹ̀ Ondo, ti okiki rẹ si kan kari aye.

Amọ iyalẹnu lo jẹ pe ojoojumọ ni awọn eeyan inu ilu naa n ku nitori aisi awọn ohun eelo amayedẹrun ninu ilu naa.

Lara awọn ohun tawn eeyan ilu Ido Ani n pohungbẹ rẹ ni omi ẹrọ to se mu, ile iwosan igbalode, oju ọna to dara ati eto aabo to peye.

Idi ree ti BBC News Yoruba fi morile ilu naa lati mọ awọn isoro to n ba wọn finra, ọrọ pọ ninu iwe kọbọ.

"Obinrin ti a gbe lọ sile iwosan papa ku tori wọn ni ko si oogun nile iwosan ijọba to wa ni Ido-Ani"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori ipo ti ilu Ido Ani wa, Odofin ti ilu Ido-Ani, Bankole Odunf,a salaye pe ijọba ipinlẹ Ondo ti gbagbe ilu naa patapata.

"Wọn ti gbagbe wa, ọjọ ti pẹ, koda, ijọba ko ri ọrọ awọn eeyan ilu Ido Ani ro nidi ipese awọn eelo fun igbe aye ọmọniyan.

Gbogbo awọn ohun to yẹ kawọn araalu maa janfaani rẹ latọdọ ijọba ni a ko ri."

Mo gbe obinrin kan lọ sile iwosan to wa nilu yii, wọn ti sọ agadagodo sẹnu ọna wọn.

Nigba to ya, wọn ni ko si oogun ti wọn yoo lo fun, wọn sọ fun wa pe ka maa gbe obinrin naa lọ sile iwosan ijọba apapọ to wa nilu Owo.

Lẹyin o rẹyin, obinrin naa ku tori ko si itọju fun bo se yẹ."

"Ilu Owo ati Ikare ni wọn n gbe awọn alaisan lọ, wọn yoo rin irin wakati mẹta ki wọn to de ibẹ, eyi to maa n tete pa wọn"

Bakan naa, Alamusi ti Ido-Ani, Olatunji Ogungbe fapa janu lori ipo ti ile iwosan ilu naa wa.

"Ipo ti ile iwosan wa wa, ko bojumu rara, ko si dokita nibẹ

Ilu Owo ati Ikare ni wọn n gbe awọn alaisan lọ, ti wọn yoo si rin irin wakati mẹta, ki wọn to de ibẹ, eyi to maa n tete jẹ ki wọn dagbere faye."

Awọn araalu miran to tun ba BBC News Yoruba sọrọ ni ko si eto aabo rara nilu naa.

Bakan naa ni wọn n fapa janu tori oju ọna ti ko dara to wa nilu Ido-Ani.

"Ti ijamba ba sẹlẹ tabi pe awọn eeyan fara pa, ko sibi ti wọn ti maa tọju wọn ayafi ta ba de Owo.

Ko si ina, ko si omi, a ko tiẹ mọ ẹsẹ wa lọdọ ijọba ipinlẹ Ondo amọ to ba jẹ pe ẹsẹ wa lo pọ to bẹẹ, ori idọbalẹ la wa yii, ki wọn jọọ dari jin wa."

Awọn eeyan ilu Ido wa rawọ ẹbẹ sijọ ipinlẹ Ondo pe ko gba ọrọ wọn yẹwo, tori ko si eto irọrun kankan nilu Ido-Ani ati agbegbe rẹ.