Iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote dá owó epo bẹntiró padà sí ₦1,200

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ifọpo Dangote ti din owo epo bẹntiro ku si N1,200 fun lita epo kan.

Ṣaaju lo ti kọkọ fi kun owo epo naa ko to tun ja walẹ bayii.

Ileeṣẹ ọhun sọ ninu atẹjade kan pe adinku owo epo yii lo n waye latari bii owo epo naa ṣe n lọ soke ati sodo lagbaye.

Ikede iye tuntun naa n tumọ si pe Dangote ti yọ N75 to fi kun owo epo naa tẹlẹ to fi di N1,275 fun lita kan.

Ọkan lara awọn adari ileeṣẹ ọhun sọ fun awọn akọroyin pe igbesẹ dindin owo naa ku ko ṣẹyin bi owo epo ọhun ṣe n ja walẹ lagbaye.

O ni "Ẹ mọ pe ogun n lọ lọwọ ni Middle East ati ipa ti ogun naa n ko ninu iye ti wọn n ta epo lagbaye.

"Awọn iṣẹlẹ to n waye lagbaye yii n ni ipa to n ko lara iye ti a n ta epo bẹntiro."

Gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe sọ, adinku yii lo n waye lẹyin ti Aarẹ Amẹrika, Donald Trump kede adehun Amẹrika ati Iran lati da ogun to n lọ lọwọ duro fun ọsẹ meji fun ijiroro alaafia.

Idaduro ogun yii n tumọ si pe awọn ọkọ oju omi to n gbe epo bẹntiro gba oju ọna ori omi Strait of Hormuz kọja yoo lanfani lati ṣe bẹẹ bayii lai si ifoya kankan.

Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, kaakiri agbaye ni owo epo ti n ja walẹ lẹyin ikede Aarẹ Trump ọhun.

Ileeṣẹ naa tun sọ ninu atẹjade kan pe irọ ni iroyin kan to n lọ ni igboro pe oun ti fi kun owo epo bẹntiro.

O ni "Iye ti a n ta a tẹlẹ naa lo ṣi wa, a ko tii gbe igbesẹ tuntun lori iye owo naa fun awọn onibara wa.

Atẹjade ọhun fi kun pe afojusun Dangote ni lati ri daju pe ko si ọwọngogo epo ni Naijiria.

Lati igba ti ileesẹ ifọpo naa ti bẹrẹ iṣẹ ninu oṣu Kẹsan an ọdun 2024 lo ti di akẹyindegbẹgbọn ni Naijiria.

Bo ṣe n pin epo bẹntiro kaakiri Naijiria naa lo n ṣakoso iye owo ti wọn n ta a.