Èyí ni àkójopọ̀ èsì ìdìbò gómìnà láti ìpínlẹ̀ Osun

Oṣiṣẹ eleto idibo to n ka ibo pẹlu agunbanirọ to duro
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Bi idibo si ipo gomina nipinlẹ Osun ṣe waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ajọ eleto Idibo ilẹ wa, INEC, ṣe ti n ko esi ibo naa jọ.

Bẹẹ naa si ni BBC News Yoruba to ti gunlẹ sipinlẹ Osun ṣaaju ọjọ idibo n mu gbogbo ẹ wa bo ṣe n lọ.

Eyi ni awọn esi idibo naa bi wọn ṣe n jade lati ijọba ibilẹ kọọkan l'Osun.

Lati maa mọ bi esi idibo naa ṣe n lọ si, maa ba wa lọ lori ikanni ati oju opo yii.

Ni bakanaa, ti o ba ṣe n tẹ ori atẹ esi ìbo to wa ni isalẹ patapata, ni abajade esi ibo fun ẹgbẹ oṣelu kọọkan, pẹlu ijọba ibilẹ ti wọn ti bori, yoo maa han si ọ.

Ajọ INEC ti fẹ bẹrẹ kika esi idibo

Ajọ INEC ti fẹ bẹrẹ si ni kede esi idibo

Gbogbo eto ti to ni Osogbo nibi ti ajọ INEC tí fẹ bẹrẹ si ni maa ka esi idibo ipinlẹ Osun tó waye loni.