Akpabio, Aiyedatiwa, Uzodimma àtàwọn míìn balẹ̀ sílùú Osogbo fun àṣekágbá ìpolongo ìdìbo gómìnà Osun

Gboyega Oyetola, Akpabio, Aiyedatiwa ati agba oloṣelu kan ree lasiko ti wọn de si ipinlẹ Osun fun ṣaaju eto idibo gomina

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Gboyega Oyetola, Akpabio, Aiyedatiwa ati agba oloṣelu kan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba nilẹ Naijiria, Godswill Akpabio ti balẹ sipinlẹ Osun, ṣaaju eto idibo gomina to n bọ lopin ọsẹ yii.

Sẹnetọ Akpabio ati ikọ akọwọrin rẹ, pẹlu awọn bii alaga igbimọ ẹgbẹ gomina onitẹsiwaju, Hope Uzodimma; Monday Okpebholo tipinlẹ Edo ati Gomina Usman Ododpo tipinlẹ Kogi.

Oni Ọjọru, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni aṣekagba eto ipolongo idibo gomina nipinlẹ Osun, eyi tẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti ya sọtọ.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo gomina yoo waye nipinlẹ Osun, nibi ti gbogbo araalu, adije, awọn alatilẹyin oludije, to fi mọ awọn alẹnulọrọ yoo ti dibo yan gomina tuntun.

Bakan naa ni Gomina Lucky Aiyedatiwa tipinlẹ Ondo, aṣoju-ṣofin lẹkun Ikeja nipinlẹ Eko, James Faleke ni wọn ti wa l'Osun pẹlu, lati ṣagbatẹru oludije sipo gomina lẹgbẹ osẹlu APC, Bola Oyebamiji.